Ọkọ mi kò kú, ó ń palẹ̀ ọjọ́ ìbí 78 rẹ̀ mọ́ lọ́wọ́ - Joke Jacobs

Olu Jacobs ati Aya rẹ Joke Silva

Oríṣun àwòrán, Instagram/olujacobs

Irọlẹ Ọjọru ni ariwo ta pe gbajugbaja osere tiata kan ni ede Yoruba ati oyinbo, Olu Jacobs, ti jáde laye.

Igba keji ree ni aarin osu kan ti ikede yoo waye pe ilumọọka osere tiata naa papoda, bẹẹ ni ọpọ eeyan to si gbọ ikede yii lo ka ọwọ sori pe ẹni re lọ.

Ṣugbọn iwadii BBC Yoruba ti fihan pe ahesọ ọrọ ati irọ nla to jinna si ootọ ni ikede naa, nitori Olu Jacobs si wa laaye, to n mi loke eepẹ.

Nigba to n fidi otitọ ọrọ mulẹ nipa ipo ti ọkọ rẹ wa, Joke Silva, to tun n jẹ Joke Jacobs, tii ṣe aya oṣere tiata naa ni ko ko ko bii okuta ni ara ọkọ oun le, ko si si iku kankan loju rẹ.

"Ko si ohun to ṣe ọkọ mi, koda, ó ń palẹ mọ lọwọ bayii lati ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun kejidinlọgọrin to de ile aye losu keje to n bọ, bẹẹ ni ẹnu ya awọn nigba ti ọpọ eeyan n beere pe ki lo ṣe ọkọ òun."

Joke Jacobs wa fi ọkan awọn ololufẹ wọn balẹ pe ko si ewu rara fun ọkọ oun.