Esabod: Esther Aboderin tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Esabod ní ẹ̀sín pọ̀ fún òun lọ́jọ́ tí wọn parọ́ pé mo mu sìgá lórí Facebook

esther aboderin esabod

Oríṣun àwòrán, others

Oloye Esther Aboderin tii ṣe ilumọọka sọrọ-sọrọ lori ayelujara ati elegbogi ibilẹ to n lo ewe ati egbo ti salaye pe ọrọ aje ati ọna atijẹ lo sọ oun di were lori ayelujara.

Aboderin, ti ọpọ eeyan mọ si Esabod abi iya ewe, lasiko to n kopa lori akanse eto loju opo BBC Yoruba dahun ọpọ ibeere awọn ololufẹ BBC Yoruba.

O salaye pe, bi oun ko ba fi were diẹ diẹ kun ọja ti oun n ta lori ayelujara, ko ni ta bo ṣe yẹ.

Esabod, ẹni to bẹrẹ lilo ori ayelujara lati ọdun 2012, táwọn eeyan si ni o maa n si pata silẹ lori Facebook tun kede pe, oun ko kabamọ awọn iwa ti oun n hu loju opo Facebook.

O ni bo tilẹ jẹ pe igba ti oun bẹrẹ ọja tita ni eebu maa n dun oun, amọ nibayii, o ti mọra, tori ara ipolowo ọja ni.

Esabod ni: "N ko lee gbagbe ọjọ ti wọn n sọ kiri pe mo mu siga lori Facebook, oju ti mi, ẹṣin pọ ju fun mi.

Idi si ree ti mo kuku fi mu siga naa han wọn lori Facebook, pe bi wọn yoo ba pa mi, ki wọn kuku pa mi."

Nigba to n sọrọ lori ija lorisirisi to n waye laarin rẹ ati awọn eeyan miran lori Facebook, eyi to mu ki wọn maa sọrọ kobakungbe ṣi ara wọn, ti ẹnu si saaba maa n kun-un, Esabod ni ọpọ awọn eeyan to n bu oun ni oun kii da lohun afi awọn ti aseju wọn ba pọ ju.

"Ogun aye lo ti mi de ori Facebook, ibẹ si ni mo ti ṣe oriire.

Mo dupẹ pe ẹnu n kun mi bayii tori nigba ti iya n jẹ mi, n ko ni ọrẹ, bi ogo ba si ṣe pọ si, naa ni ọta yoo pọ, orúkọ mi si lo gbayi ti wọn ṣe n pariwo mi mo ri oju rere Ọlọrun gba ni."

Àkọlé fídíò,

Ibadan Murder: Oyún oṣù méje ló ń bẹ nínú Azeezat, kí wọ́n tó f'òkúta fọ́ ọ lórí

Kini Esabod sọ nipa iwa ipa ninu idile?

Iya Ewe, tun mu ẹnu ba iwa ipa sáwọn obinrin ninu idile tun mẹnuba ọpọlọpọ idi ti iyawo fi maa n duro sinu idile bẹẹ yatọ si itọju ọmọ.

" Oju kokoro ati ẹtan owo, ifẹ ori ayelujara ati ifẹ afẹju si ọkùnrin wa lara idi ti awọn obinrin fi n fi ara da iya lati ọwọ ọkùnrin.

Amọ mo n rọ awọn obinrin ti ọkọ ba n na wọn lati ko kuro nibẹ, ko ma baa pa a nitori ọmọ wọn ní ọkọ wọn."

Wo ohun ti Esabod sọ nipa ọrọ alufanṣa to n sọ si awọn Ọba alaye kan:-

Esabod, ẹni ti ọpọ eeyan mọ pe o maa n fi ede abuku sọrọ nipa awọn Ọba alaye nilẹ Yoruba, awọn agba oselu, olorin, oṣere tiata atawọn eekan ilu miran lori ayelujara, wa salaye pe, oun kii woju ẹnikẹni bii sọrọ-sọrọ, ti oun ba wa lẹnu iṣẹ oun

O ni: " Ni ẹnu iṣẹ mi, n ko fẹ mọ iru ẹni to jẹ, amọ laisi lẹ́nu iṣẹ, maa kunlẹ fun Ọba; amọ, ki ni Ọba wa de ibi iroyin?

Ẹtọ ilu ni mo n ṣe, ija ilu ni mo n ja awọn araalu si lo n fun mi ni ẹri ti mo n lo, ti mo ba si sọrọ Ọba, mo ní ẹri to daju lọwọ."

Àkọlé fídíò,

Joke Silva: Olu, ó tó gẹ́ pẹ̀lú obìnrin yìí níkan tó ń ba ẹ ṣeré ìfẹ́ nínú sinimá

Imọran Esher Abọdẹrin fun awọn ọdọ Naijiria ni pe:

Iya ewe, to ti le ni ọgbọn ọdun to ti wa loke okun, wa gba awọn ọdọ to n lakaka lati wa iṣẹ aje lọ soke okun nimọran pe, ki wọn ni suuru nitori nnkan ko fi bẹẹ dara mọ lọhun.

O ni: " Ewe, tii ṣe iṣẹ idọti lo sọ mi di ọlọla, ogun lo si le mi de idi ewe tita, ki Ọlọrun tete fi ọna han ẹda.

Ki awọn ọdọ mase fi akoko wọn sofo nipa diduro de ijọba, ki wọn ma si tiju iṣẹ ti wọn ba n ṣe."

O ni ọlẹ ati ole lo n da awọn ọdọ iwoyii laamu ni wọn ko ṣe fẹ ṣíṣẹ ni Naijiria, bẹẹ si ni oke okun ko dabi ti tẹlẹ mọ, wọn kan n wa fi ara wọn jiya ni.