Coronavirus symptoms : Wo ìdí tí ìdí tí ìjọba ìpínlẹ́ Ekiti ṣe fẹ́ kéde Kónílé-ó-gbélé tuntun

Fayemi

Oríṣun àwòrán, @ng_phenomenal

Ijọba ipinlẹ Ekiti ti sọ pe oun yoo kede ofin konile-o-gbele tuntun mii laipẹ ti awọn eeyan ipinlẹ naa ba tẹsiwaju pẹlu kikọ eti ikun si ilana to gbe kalẹ lati dẹkun itankalẹ arun Coronavirus.

Kọmiṣọna ọrọ to n lọ ni ipinlẹ ọhun, Muyiwa Olumilua lọ sọ bẹẹ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC.

Olumilua sọ pe "Ti awọn eeyan to ni arun naa ba n pọ si, o di dandan ki a pada si ofin konile-o-gbele."

Kọmiṣọna ọhun tẹsiwaju pe ojuṣẹ ijọba ni lati daabo bo awọn ara ilu ati pe ki wọn lee wa ni ilera pipe ati alafia.

O ni "Ti awọn eeyan ba kọ lati tẹle ilana ti ijọba gbe kalẹ fun ilera awọn eeyan, ko si nnkan mii ti a maa ṣe ju pe ka ti gbogbo ibode wa, ki a si paṣẹ konile-o-gbele."

Oríṣun àwòrán, @ng_phenomenal

Olumilua sọ pe ijọba Ekiti ko tii mu ọjọ ti yoo kede igbele tuntun ọhun, ṣugbọn ijọba n fi akoko yii kilọ fun awọn eeyan lati tẹle inala to gbe kalẹ.

Lẹyin naa lo rọ awọn olugbe ipinlẹ Ekiti lati tẹle gbogbo ilana ti ajọ NCDC gbe kalẹ, bii fifọ ọwọ ẹni dede, itaketesiraẹni lawujo ati lilu ibomu.

Àkọlé fídíò,

Lagos lockdown update: Ayodeji Tinubu ní àìsí àǹfàní ẹ̀kọ́ ayélujára t'íjọba ń pariwo