June 12: Ìtàn bí Alhaja Kudirat Abiola ṣe dojúkọ ohun t'ọ́kùnrin ń sá fún torí ìjọba àwaarawa

Kudirat Abiola

Oríṣun àwòrán, @niwexnigeria

Kudirat Abiola jẹ opo nla gidi nidi agbekalẹ eto isejọba alagbadada, a ko sile sọrọ June 12, ka yọ ipa to ko sẹyin nitori o fi ẹmi rẹ lelẹ fun ijọba alagbada ni.

Wọn bi Kudirat Olayinka Adeyemi ni ilu Zaria lọdun 1951, lati igba ọdọ rẹ lo ti n fi apẹrẹ akinkanju han.

Ijẹri ohun to ṣe ni ileewe girama. Muslim Girls High School lo soo di odidi alagbara obinrin pẹlu iṣẹ takuntakun to fi jẹ adari gbogbo ọmọ ile iwe ni kilaasi aṣekagba rẹ.

Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gbajugbaja ni Kudirat, orukọ rẹ kari aye, o si jẹ apẹrẹ ara ọtọ aronilagbara ẹda to n ja fun idọgba ati ijọba awa ara wa jakejado Afirika

Irinajo igbeyawo ati ifẹ pẹlu MKO

Ọmọ ọdun mọkanlelogun lo fẹ Oloye Moshood Abiola.

Alhaja Kudirat ni iyawo keji ti Abiola fẹ ṣugbọn oun ni iyale ninu awọn iyawo rẹ lasiko ti wọn pa a.

Ọmọ meje ni Kudirat bi fun ọkọ MKO Abiola - Yisau Olalekan, Hafsat Olaronke, Abdul Mumuni Khafila, Hadi, Moriam, Jamiu Abiodun ati Olalekan Yisau Abiola.

Oríṣun àwòrán, @OgbeniOlaide

Gẹgẹ bi o ṣe wa ni akọsilẹ, odindi gende ọkunrin mẹfa ni wọn gbe iṣẹ iku rẹ fun.

Ninu ọkọ rẹ ni wọn pa a si pẹlu iru ibọn ti awọn sọja n lo.

Koda, dẹrẹba rẹ gan an ku, Oluranlọwọ rẹ ti wọn fẹsun kan pe o mọ nipa iku rẹ naa wa ninu ọkọ ṣugbọn oun o farapa rara.

Ọkọ rẹ, oloogbe MKO Abiola sọ lọjọ kan nigba aye rẹ pe : "mo n lọ sile lọjọ kan lati lọ bẹ iyawo mi ati ọmọ wa ọkunrin wo, nigba ti mo ri ọkọ ayọkẹlẹ iyawo mi loju ọna, o ni oun ti n gbadura ki n pade oun lọna ile tori pe awọn ọkunrin kan ti wa ta oun lolobo pe ọlọpaa n bọ wa mu mi lati fẹsun kan mi.

Àkọlé fídíò,

Àwọn ará ìlú Abiola ní Abẹokuta bá BBC sọ̀rọ̀

Kia ni mo sa pada si ibi ti mo n fara pamọ si lati lọ ṣe ọna bi n o ṣe sa kuro ni Naijiria".

Lẹyin ti Abiola ri ibi salọ si ilu London, iyawo ati ọmọ rẹ naa pada ri ọna salọ ba a lọhun nibi ti wọn ti jọ n yi i mọra wọn ninu ile kolobo kan pẹlu idile awọn Olunloyo.

Ninu eyi ni Kudirat n ba Abiola jiya. Ati ri owo na nira fun wọn ṣugbọn wọn n ri iranwọ lẹẹkọọkan latọdọ awọn mọlẹbi ati ọrẹ Abiola.

Alaṣeyọri oniṣowo ni Alhaja Kudirat.

Oríṣun àwòrán, @deji_of_lagos

Ki ni a le s nipa June 12 ni soki?

Ohun ti awọn eniyan maa n saaba ranti ti wọn ban sọ itan jija fun ijọba tiwa n tiwa ni ọna aburu ati ailaanu ti wọn gba pa arẹwa akinkanju obinrin to jẹ iyawo Abiola.

Alhaja Kudirat Abiola di ajafẹtọmọniyan nigba ti ijọba Naijiria bẹrẹ sii doju le e.

Lati igba ti wọn ti gbe Moshood Abiola ti mọle, pẹlu igboya ni Kudirat fi lọ pe fun itusilẹ ọkọ rẹ pẹlu bi ijọba ṣe n dunkooko mọ ẹbi ati awọn alatilẹyin rẹ to.

Alhaja Kudirat Abiola ba ọpọlọpọ ileeṣẹ iroyin sọrọ kaakiri to si n pe fun itusilẹ ọkọ rẹ ati pe o n fi ẹsun kan ijọba pe wọn n run isuna idile oun.

Lọjọ kẹjọ, oṣu karun un, odun 1996, ile ẹjọ giga ipinlẹ Eko da a lẹjọ ẹsun igbimo idite ti ijọba ati ọpọlọpọ irọ.

Bakan naa, lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu ati ọdun kan naa, ile ẹjọ tun fi ẹsun yii kan naa kan an.

Ile ẹjọ da a silẹ pẹlu beeli wọn si tun sun ẹjọ rẹ siwaju di ọjọ kẹtadinlogun, oṣu keje.

Pẹlu gbogbo idunkooko mọ ọ yii, Kudirat Abiola tẹsiwaju pẹlu ipolongo lorukọ ọkọ rẹ.

Pẹlu bi o ṣe han gbangba gbangba pe ewu n bẹ lori orule, Kudirat ṣi huwa adari lasiko yii ti gbogbo ẹ doju ru.

O bọ siwaju lati fi igboya rẹ han pe igbesẹ awọn ologun tẹ oju ofin ẹtọ awọn ọmọ Naijiria mọlẹ lati dibo yan ijọba ti wọn fẹ.

Oríṣun àwòrán, @abdulakeemibra8

Kudirat Abiola tun ṣaaju igbesẹ kan lọdun 1994 eyi to bi iyanṣẹlodi ọlọsẹ mejila ti awọn oṣiṣẹ ileepo.

Ṣe ni iyanṣẹlodi yii ka ijọba niṣan ko tori o jẹ ọkan lara awọn iyanṣẹlodi awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ epo bẹntiroo to gun ju ninu itan Afirika.

Ki lo fa sababi iku Kudirat gan an?

Wọn pa Kudirat lasiko ti ijọba orilẹ-ede Naijiria labẹ iṣejọba ologun to fi ọkọ rẹ sẹwọn.

Kashimaawo Abiola lo n jawe olubori ninu idibo to waye ni Naijiria nigba naa lọhun lọdun 1993.

Ko pẹ ni wọn fi ọlọpaa mu Abiola lẹyin ti ijọba to wa lori oye da ibo naa ru lasiko Ibrahim Babangida.

Lẹyin iku Kudirat, wọn ko ṣi tu ọkọ rẹ silẹ kuro lẹwọn.

Bo ṣe ku ki wọn tu u silẹ lọjọ keje, oṣu keje, ọdun 1998 ni Moshood Kashimawo Abiola jade laye.

Lẹyin iku rẹ lọdun 1996, nigba to di oṣu kẹwaa, ọdun 1998, Hamza Al-Mustapha ati ọmọ aarẹ ana, Abacha Mohammed farahan nile ẹjọ pẹlu ẹsun pe awọn ni wọn pa Kudirat Abiola.

Nibi igbẹjọ, ẹni to pa a gangan to fẹnu ara rẹ jẹwọ, Barnabas Jabila ni oun tẹle aṣẹ latọdọ ọga oun Al-Mustapha ni.

Oríṣun àwòrán, @HistoryVille

Ni ọgbọnjọ oṣu kẹfa, ọdun 2012 ni wọn to dajọ iku nipa yiyẹgi fun Hamza Al- Mustapha ati Alhaji Lateef Shofolahan fun iku Kudirat Abiola.

Al-Mustapha yii ti jẹ adari awọn oṣiṣẹ alaabo fun ijoba to wa lori aleefa nigba ti Shofolahan ti jẹ oluranlọwọ pataki fun oloogbe.

Nigba to ya ni wọn gbọ ẹjọ ẹbẹ ti wọn pada tu awọn mejeeji silẹ nile ẹjọ kan ni Eko.

Kudirat Abiola jẹ apẹrẹ ajijangbara fun ijọba awarawa Naijiria to bẹẹ to jẹ pe ọdun mọkandinlogun, wọn ṣi n ṣe iranti igbesẹ yii eti iboji rẹ.

Àkọlé fídíò,

Ibadan Murder: Oyún oṣù méje ló ń bẹ nínú Azeezat, kí wọ́n tó f'òkúta fọ́ ọ lórí

Iṣẹ Alhaja Kudirat ko parẹ

Ninu gbogbo iwadii, a o rẹni to sọrọ lodi si Alhaja Kudirat Abiola ri dipo bẹẹ kiki awọn to n kan sara si igbesẹ rẹ ati iṣẹ takuntakun to ṣe gẹgẹ bi akọni obinrin fun orilẹ-ede Naijiria ni.

Won ni o duro gbọingbọin lẹyin ọkọ rẹ.

Lapapọ awọn eeyan ni "lootọ, Kudirat Abiola ni akinkanju ọjọ kejila, oṣu kẹfa (June 12).

Lọjọ kẹrin, oṣu kẹfa to ku ọjọ perete ti awọn ọmọ Naijiria yan lati dibo yọ ijọba ologun kuro lori oye ni ẹmi Kudirat kuro loke eepẹ pẹlu ọpọlọpọ ọta ibọn. awọn aṣekupani.

Gbàrà, ṣe ni iku Alhaja Kudirat Abiola ṣe agbende akinkanju obinrin mii ni idile Abiola, iyẹn Hafsat Costello ọmọbinrin ti wọn bi lọdun 1974 ẹni to pinnu lati tẹsiwaju lati maa gbe opo ijangbara ti iya rẹ ja ro

Alhaja Kudirat Abiola ku ṣugbọn iṣẹ akinkanju rẹ ṣi n gbe aye lọkan awọn ọmọ Naijiria.