Barrakat Bello: Sábàbí ire ní ikú Barakat padà já sí fún wa- Ẹ̀bí fẹ̀mí ìmoore hàn sí àwọn ọmọ Nàíjíríà

Àkọlé fídíò,

Barrakat Bello: Iya rẹ̀ ní báwọn èèyàn ṣe ń fún òun lówó, làwọn míì ń tún ilé ṣe

Arabinrin Kafayat Bello, Iya Barakat Bello, ti dupẹ lọwọ awọn ẹlẹyinju aanu ti o dide iranlọwọ lẹyin iku ọmọ rẹ.

Baraakat Bello ni ọmọbinrin ẹni ọdun mejidinlogun, ti awọn olubi ẹda kan ṣekupa, lẹyin ti wọn fi ipa baa lopọ tan l'oṣu kẹfa ọdun yii, ni agbegbe Akinyẹle,

Ninu ọrọ ti o ba ikọ BBC Yoruba sọ l'Ọjọ Aje, iya Baraka ni, "A dupẹ lọwọ ọmọ Naijiria nilẹ yii ati ni oke okun. Iṣẹ ẹni kankan ko ni di iṣẹ o.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Mi o ni fi iru eleyii san an fun onikaluku o. Ẹ ṣee, ẹ ku idide, ẹ ku iranlọwọ. Irinajo onikaluku yin naa ko ni dojuru o".

Iya Barakat ati awọn to n sisẹ ile lọwọ

Arabinrin Kafayat fi to wa leti wi pe, iku Barakat mu ayipada nla de ba ile ti wọn n gbe, nipasẹ awọn alaanu to dide si wọn.

Awọn osisẹ to n tun ile obi Barakat Bello se

O ni iranlọwọ dide loriṣiriṣi nitori bi awọn kan ṣee n gbe owo silẹ, ni awọn ẹlomii tun un pese awọn ohun elo ti yoo mu ayipada ba ile naa.

O tun fi kun ọrẹ rẹ wi pe, gbogbo ferese ile naa ati ilẹkun lo ti di piparọ, bẹẹ si ni iṣẹ n lọ lọwọ lati kọ ile naa pari.

Arabinrin Bello fikun pe, ko si ohun mii ti wọn n fi owo ti wọn ri gba ṣe yatọ si amojuto ile ti wọn ko tii kọ tan.

O ni bakan naa ni wọn fi katakata ro gbogbo igbo to kun di ile naa tẹlẹri, bẹẹ si ni imọlẹ ti yii ile naa ka.

Baluwẹ atijọ ti wọn pa oloogbe Barakat si naa ti di wiwo, bẹẹ si ni iṣẹ ti n lọ lọwọ lorii ile iwẹ ati ile igbọnsẹ igbalode ti wọn kọ mọ ile naa.

ile obi Barakat Bello ti wọn tun se

Egbọn iya Baraka ti o ba wa sọrọ, Arakunrin Ọlalẹyẹ Daud ni, sababi ire ni iku Baraka pada jasi.

O ni, "Mo ri iyatọ gidi gan ni ayika yii nitori nigba ti iṣẹlẹ yẹn ṣẹlẹ, gbogbo ibi kun fun igbo ni.

Laarin bii ọjọ kẹta, wọn ti wa fi katakata hu gbogbo igbo yẹn.

Lẹyin igba yẹn, a ti ri iyatọ lara gbogbo ile, awọn ọmọ Naijiria dide iranlọwọ inu mi ti ẹ dun.

Amọ gbogbo nnkan pẹluu sababi ni, bi Ọlọrun ṣe sọ wi pe yoo ṣe ri niyii, a si ti gba fun Ọlọrun."

Ile obi Barakat Bello ti wọn tun se

Arakunrin Daud wa dupẹ lọwọ gbogbo ọmọ orilẹede Naijiria pẹluu adura wi pe "a o ni fi iruẹ gbaa".

L'ọjọ kẹta oṣu kẹfa ọdun 2020 ni awọn olubi ẹda kan ṣekupa Arabinrin Barakat Bello, lẹyin ti wọn fi ipa baa lopọ tan ni agbegbe Akinyẹle niluu Ibadan.

Awọn olubi ẹda naa si tun da ẹmi awọn obinrin marun un mii legbodo ni ijọba ibilẹ kan naa niluu Ibadan, laarin oṣu kan ti Barakat di oloogbe.

Ile obi Barakat Bello ti wọn tun se

Bo tilẹ jẹ wi pe ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ ṣe afihan awọn ọdaran ti wọn mu lorii iku Barakat ninu oṣu keje ọdun yii, awọn olugbe agbegbe Akinyẹle ti o ba wa sọrọ labẹ aṣọ, fi idi ọrọ mulẹ wi pe, awọn to n ṣiṣẹ ibi ni agbegbe naa kọ ni ọlọpaa ri mu.

Arakunrin Ọlalẹyẹ Daud, Ẹgbọn iya Barakat

Idi ni pe wọn tun dede ri oku ọmọbinrin ẹni ọdun mẹrindinlogun mii ninu igbo kan ni agbegbe Akinyẹle, lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ kede pe awọn ti mu awọn afurasi ọdaran naa to n paayan ni Akinyele.

Ikú Barakat Bello ní Akinyele gbé aláàánú pàdé ẹ́bí rẹ̀

Barakat Bello ati aworan atunse ile obi rẹ

Yoruba ni a tori ọkan se ọkan ni Ọlọrun Ọba, ti ọpọ eeyan si maa n gbadura pe, ko ma fi ọkan gba ọkan lọwọ wa.

Ẹ ranti iroyin kan nibi ti awọn onisẹ ibi ti da ẹmi ọmọbinrin kan, Barakat Bello legbodo lọjọ aipe, ladugbo Akinyele nilu Ibadan, to si fi tipa ba lopọ, ko to gba ẹmi rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bẹẹ ba gbagbe, lasiko ti iya Barrakat, Kafayat Bello n ba BBC Yoruba sọrọ lori bi isẹlẹ naa se waye, o ni ko ba nira fun awọn onisẹ ibi naa lati raye wọnu ile wọn, to ba jẹ pe wọn ni ferese ati ilẹkun gidi ninu ile naa ni.

Awọn osisẹ to n tun ile obi Barakat Bello se

Oríṣun àwòrán, BBC Sport

Abẹwo BBC si ile naa si fihan pe, wọn ko tii pari ile ọhun, asọ ati ọra ni wọn ta si awọn oju ferese ati ẹnu ọna ile, ti wọn ko si rẹ ara ile ọhun rara.

Àkọlé fídíò,

JusticeforBarakat: O lé lọ́mọ ọdún mọ́kànla kí n tó rí abúrò rẹ̀ bí lée

Wayi o, orire oloogbe Barakat naa ti gbe alawore pade awọn ẹbi rẹ.

Idi ni pe alaga ajọ alaanu kan, HANHF, Asofin Abayomi Fagbenro to se abẹwo si ọdọ iya Barakat lati baa kẹdun, ti pasẹ pe ki wọn bẹrẹ si se atunse ilegbe mọlẹbi naa.

Awọn osisẹ to n tun ile obi Barakat Bello se

Oríṣun àwòrán, Others

Asofin Fagbenro ni awọn mọlẹbi Barakat nilo atilẹyin to yẹ ati eto idẹrun ti yoo din ironu wọn ku lasiko yii ti wọn n sọfọ iku ọmọ wọn.

Bakan naa lo tun kesi ijọba atawọn araalu lati tete wa ojutu si ọrọ ifipanilopọ to n fi ojoojumọ peleke si, ti ijiya iku si tọ si awọn onisẹ ibi naa.

Ọwọ́ ọlọ́pàá tún tẹ afurasí tó fipá bá odi àti adití lòpọ̀ nílùú Ibadan

barakat bello

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo ti kede pe oun ko sinmi nidi ṣíṣe awari awọn to pa Barakat Bello ati Azeezat Somuyiwa.

Oṣiṣẹ alarena fun Ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo, Olugbenga Fadeyi, lo sísọ loju ọrọ yii lasiko itakurọsọ pẹlu ikọ iroyin BBC Yoruba lori iwa ifipabanilopọ ati ipaniyan nipinlẹ Oyo.

Fadeyi ni ọwọ awọn ti tẹ afurasi kan to ni ohun ṣe pẹlu bi wọn ṣe fi tipa ba obinrin kan to ni ipenija ọrọ sisọ ati gbigbọ lopọ ni agbegbe Ibarapa.

Bakan naa lo ni ọwọ ti tẹ afurasi miran lori iku to pa Azeezat Somuyiwa, ẹni to ni oyun osu meje ti wọn fọ okuta mọ lori ninu yara rẹ.

Amọ oṣiṣẹ alarina ọlọpaa nipinlẹ Oyo naa ni ọwọ ọlọpaa ko tii tẹ afurasi kankan lori iku Barakat Bello ti wọn fi tipa ba lopọ, ki wọn to pa ninu baluwẹ lagbegbe Akinyele.

Fadeyi wa fi ọwọ gbaya pe Ileesẹ Ọlọpa ko ni rẹwẹsi titi ti yoo fi ṣe awari awọn onisẹ ibi yika ipinlẹ Oyo.