George Floyd: Ẹ̀rọ ayàwòrán ara ọlọ́pàá ṣàfihàn bí George Floyd ṣe ni òun kò le mí mọ́

George Floyd

Oríṣun àwòrán, Twitter/Ruty Richardson

Iwadii tuntun ti fihan pe, ọlọpaa ti wọn fẹsun kan pe o pa George Floyd sọ fun un pe, ko gbẹnu dakẹ ni gbogbo igba to fi n pariwo pe oun ko le mi mọ.

Fidio kan to jade sita ṣe afihan George Floyd, to n pariwo fitafita fun iya rẹ to ṣẹṣẹ doloogbe, ati awọn ọmọ rẹ pe awọn ọlọpaa naa yoo pa oun.

Iwadii naa si lo tan imọlẹ si bi Floyd ṣe ja fitafita fun ẹmi rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọpọlọpọ ifẹhọnu han lo waye ni Oṣu Karun, ọdun 2020 lẹyin iku George Floyd.

Awọn ọlọpaa mẹrin ti wọn fi panpẹ ọba mu, nipa iku George Floyd ni wọn ti gba iṣẹ ni ọwọ wọn, ti wọn si ti fi wọn si panpẹ ọlọpaa.

Derek Chauvin to gbe orunkun le ọrun rẹ lo n jẹjọ iwa ipaniyan pẹlu awọn to ku.

Orukọ ọlọpaa mẹta yoku ni - Thomas Lane, J Alexander Kueng ati Tou Thao - wọn fẹsun kan wọn pe, wọn ṣe iranwọ fun ẹni ti wọn fẹsun ipaniyan kan.

Àkọlé fídíò,

George Floyd: Àwọn ọlọ́pàá darapọ̀ mọ́ àwọn olùwọ́de lórílẹ̀èdè Amẹ́ríkà

Ọkan lara awọn agbẹjọrọ to fi fidio iwadii tuntun naa lede, lo n pe fun ki ijọba da ẹjọ ti wọn pe mọ Thomas Lane nu, nitori ko kopa ninu iṣekupani naa.

Ọkan lara awọn agbẹjọro fawọn ọlọpaa mẹrin naa lo fi lede pe, ẹrọ ayaworan to wa lara awọn ọlọpaa fihan pe, ọkan lara awọn ọlọpaa naa lo ni ki Floyd gbẹnu dakẹ.

Àkọlé fídíò,

Black lives Matter: Ọmọ Naijiria sọ ìrírí rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọlọ́pàá nílẹ̀ Amerika.

Ẹrọ ayaworan naa fihan pe, o le ni igba ogun ti George Floyd fi pariwo pe, oun ko le e mi mọ, lẹyin ti wọn fi orunkun fun lọrun, amọ ti ọlọpaa Chauvin jagbe mọ wi pe, ko gbe ẹnu rẹ soun, ko dakẹ ariwo to n pa.

Amọ, awọn agbẹjoro Chauvin ko i tii fesi si iwadii tuntun naa, lati igba ti o ti wa ni ikawọ awọn eniyan lawujọ.

Àwọn olùfẹ̀hònúhàn kọ etí ikún s'íkìlọ̀ ọlọ́pàá ṣe ìwóde ní London

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ẹgbẹẹgbẹrun un awọn olufẹhonuhan lo tu jade laarin gbungbun ilu London lọjọ Satide, bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa ti kilọ fun wọn lori iwọde naa.

Ọpọ ninu wọn lo n ju igo sawọn ọlọpaa nigba ti wọn kọlu ara wọn.

Ohun ti wọn sọ ni pe awọn fẹ daabo bo awọn ere tawọn eeyan kan n wo lulẹ notori wọn nii ṣe pẹlu ẹlẹyamẹya.

Ileeṣẹ ọlọpaa Met ti fote le iwọde ṣiṣe nitori ohun to ṣẹlẹ nigba tawọn eeyan kan n fẹhonuhan lopin ọsẹ to lọ.

Bakan naa lawọn ẹgbẹ ''Black Lives Matter'' naa ti ṣewọde kaakiri UK to fi mọ ilu London.

Oríṣun àwòrán, AFP

Awọn to ṣagbatẹru iwọde ti ọjọ Satide ti rọ awọn eeyan lati maa darapọ mawọn ti wọn fẹ ṣe ifẹhonuhan lati tako iwa ẹlẹyamẹya.

Ṣugbọn awọn olufẹhonuhan kan to ko ara wọn jọ nibi ere ti wọn fi n ṣe iranti ogun ni Whitehall ti wọn si gun ere Winston Churchill ni Parliament Square.

Niṣe ni wọn raga bo ere Churchill lati rii wi pe awọn olufẹhonuhan mii ko woo lulẹ.