June 12: Àwọn tó ṣojú wọn kòró sọ irírí ọjọ́ náà

Dele Fawehinmi
Àkọlé àwòrán,

Ọlọ́run ló ní kí Abacha kú, àwọn àgbà Yorùbá púpò kò bá ṣòfò- Dele Momodu

Awọn ti iṣẹlẹ June 12 ṣoju wọn ti bu ẹnu atẹ lu bi ijọba ologun to wa nigba naa lọhun ṣe fi ẹtọ ọpọ ọmọ Naijiria dun wọn.

BBC Yoruba lo gbe wọn wa sori akanṣe eto fun ayajọ June 12 eyi ti ijọba apapọ labẹ akoso aarẹ Muhammadu Buhari ti kede ti wọn si sọ ọ di ayajọ eto iṣejọba tiwa n tiwa lorilẹ-ede Naijiria.

Wọn bẹrẹ si ni ṣe eyi ni iranti awọn to ja fitafita fun ijọba awaarawa ni Naijiria.

Awọn alejo mẹtẹẹta to wa lori eto jẹ awọn ti iṣẹlẹ June 12 ṣoju wọn koro.

Oloye Dele Momodu ati akọbi ọmọ oloogbe ajafẹtọ ọmọniyan, Oloye Gani Fawehinmi, Mohammed kẹnu bọ ọrọ o si da bii ki eto naa ma tan mọ.

Dele Momodu ni ọrọ pọ ninu iwe kọbọ pẹlu ọrọ June 12.

O sọ idi ti Oloye MKO Abiola fi fẹ jẹ aarẹ Naijiria nigba naa lọhun.

Abiola ni bi oun ṣe maa n tọju awọn araalu, owo ti oun ni ko lee gbe e tan. lo se pinnu lati lo owo ilu fun ara ilu nipasẹ ijọba, eyi gan an ni gbigbe apoti ibo fun ipo aarẹ ṣe wu Abiola.

Lasiko idibo ọdun 1993, "Alhaji Bashir Tofa ati Oloye MKO Abiola lo jọ figagbaga lọjọ naa.

Ko sija, ko si ikunsinu, gbogbo ẹ lọ ni irọwọrọsẹ ṣugbọn a o wa mọ bi ọrọ ṣe dẹnu akayin ti akara fi wa di egungun".

O ṣafiwe ohun tawọn ologun ṣe nigba yẹn pe bii igba ti obinrin bi ọmọ tan ti wọn si bẹ ori ọmọ to ṣẹṣẹ yọri sita ni.

Ọgagun Ibrahim Babangida lo wa lori alefa lasiko ti wọn n sọ ọ yii.

Abiola ran Dele lọ ilu Oyinbo, Austria fun ayẹyẹ ami ẹyẹ kan ti Oloye Fawehinmi n gba nibẹ.

Àkọlé fídíò,

BBC gbalejo ọmọ Ibadan

Dele pe awọn oniwe iroyin atawọn mii ni Naijiria wọn si fi da a loju pe pẹlu ohun ti awọn n ri, Abiola ni yoo wọle gẹgẹ bi aarẹ afigba to pe eeyan kan to ni nkan ti ologun fẹ ṣe ree o

"O ni oun ti n wa mi, o ji ọrẹ rẹ Abiola lo mọ da bii pe yo wọle ṣugbọn awọn ologun ko ni gbe ijọba fun un.

Ọọ kẹrindinlogun oṣu kẹfa ni Dele Momodu ati Oloye Gani Fawehinmi tẹkọ ofurufu leti wa si Naijiria.

Ni papakọ ofurufu ni wọn ti gba ipe pe awọn ologun ti da ibo ru o. Eyi gaan ni ibẹrẹ bi ohun gbogbo ṣe doju ru.

Nigba ti Amofin Mohammed Fawehinmi yoo kan lu agbami ọrọ, abuubu tan ni ọrọ ti ọmọ Oloye da walẹ.

Gẹgẹ bi ẹni tọrọ tun ṣoju oun naa, o ni ere lawọn pe e nigba tawọn naa gbọ iroyin nkan tawọn ologun n sọ nigba naa toun wa nileewe loke okun afi ti wọn ni Abiola ko ni wọle.

Ṣaaju si ni Abiola ti sọ fun wọn awọn to fẹ yan sipo minisita atawọn ipo mii lo ba di pe awọn kan lọ si Abuja lọ ki Abacha ku oriire.

Ṣe lo ni igbakuugba ti awọn ologun ba tun ti wa gbe baba Gani Fawehinmi nile inu awọn kii dun ṣugbọn kia iya oun yoo ti gba ọdọ awọn agbẹjọro lọ ti yoo ran oun naa lọ gbe igbesẹ mii.

Koda wọn ti ṣe gbogbo eto bi Abiola yoo ṣe ko lọ si Aso Rock ni Abuja ti eeyan kan dedee wa sọ fun Oloye Abiola pe ko ma lọ sibẹ lọjọ to gbero lati lọ o.

Àkọlé fídíò,

June 12:Àwọn tó wà ní ìjọba Baba mi ní kò lu owó ìlú ní póńpó- Ọmọ Abacha

Bi wọn ṣe wa gbe oloye Abiola lọ si atimọle niyẹn ti Abacha bẹrẹ si ni ṣejọba lọ.

Dele Momodu mu ni ranti pe nigba ologun wọn ko ki n fẹ ki ẹnikẹni maa gbo wọ lẹnu ẹni ba dan an wo gbigbe tabi pipa ni.

Nigba naa ni wọn ṣe agbekalẹ NADECO ti awọn ologun fi n ṣọ ibi gbogbo lorilẹ-ede Naijiria ṣugbọn Dele Momodu pa owe pe "mo n ree mugi wa, mo n ree mugi wa, ọgbọọgbọn lagba fi n sa fun ejo" ni awọn fi yọlẹ sa kuroni Naijiria

O ni eyi sele nitori ijọba ologun to mu ohun gbogbo le koko lo mu oun atawọn ọdọ mii sa kuro nile gba ọna ẹnu ibode Sẹmẹ.

O ni bi awọn eeyan nbere ki lode ti awọn fi bẹru. Wọn pa eeyan wọn tun pa obinrinbinrin, Kudirat Abiola ni ita gbangba, o tọ ki awọn fi ibẹru sa lọ.

Bakan naa, ọkan lara awọn ọdọ to ti dagba bayii ṣugbọn to jẹ ọmọde nileewe girama nigba June 12 ṣugbọn to nifẹ si ọrọ oṣelu ati kika iwe iroyin,

Kini Kehinde Oyetunji só?

Ọgbẹni Kehinde Oyetunji sọ iriri tirẹ nigba naa lori eto BBC Yoruba pe koda lọjọ naa gbogbo oju popo ni wọn dana si. "Lọjọ ti wọn fagile ibo, a wọ ọkọ lọ si ilu Oṣogbo ṣugbọn ẹsẹ ni a rin pada lọ si ilu Ire" tori rogbodiyan ti bẹrẹ nigba naa.

Mohammed Fawehinmi ni iyi ni to fi mu ki Aarẹ Buhari sọrọ pe oun mọ riri June 12, o tun yẹ Abiola si pẹlu oye GCFR lẹyin to ti doloogbe.

Ni ìdáhùn si ibeere pé awọn igbesẹ wo lo ti waye to ba nkan ti awọn eeyan ja fun nigba naa:

Ogbeni Kehinde Oyè Tunji ni lati ọdun 1979 si 1993, ijọba ologun lo wa ṣugbọn nigba ti Abiola fẹ dije, awọn agbekalẹ rẹ fara pẹ jẹ fun imayerọrun gbogbo eeyan bíi eto ẹkọ ọfẹ, ìlera ọ̀fẹ́ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Amọ ó ni ṣe tori pe o kan jẹ Abiola ni wọn ṣe pada yẹ ẹ sì.

Kehinde ni o yẹ ki ijọba ṣe awọn nkan ti Abiola ku fun si ilu.

Bakan ni Amofin Mohammed Fawehinmi naa yi i mọ.

O ni "Yoruba ni lati ronu, a o ni olori mọ afi awọn akowojẹ". O fun pe si awọn to wa ni ijọba pe "ẹ bẹrẹ ẹkọ ọfẹ, ilera ọfẹ, owo ẹ wa bayii".

Mohammed ni ko yẹ ki ọmọ Yoruba tun maa san owo ileewe titi di fasiti mọ.

Awọn alejo fẹnu ko pe niwọn igba ti Naijiria ba le mọ riri ayajọ June 12, ki wọn ṣe oun ti yoo maye araalu dẹrun.