Akure fire: Àwọn tó fara káásá ìjàmbá iná nílùú Akure d'ẹ̀bi ru panápaná

Awọn eeyan niwaju ọkan lara awọn ṣọọbu to jona

Awọn aladugbo ni agbegbe Ọbanla ni ilu Akurẹ ti di ẹbi bi ọṣẹ ti ijamba ina to waye lagbegbe naa ṣe se pọ ru bi awọn oṣiṣẹ panapana ṣe pẹ de ibi ti ijamba ina naa ti waye lalẹ ọjọ Aiku.

Ina nla kan tun sọ lagbegbe Ọba nla ni ilu Akurẹ eleyii to run ọpọlọpọ dukia olowo iyebiye, ọọbu ati ileegbe.

Awọn eeyan kan ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe ijamba ina naa ko ba ti jo ajopadukia run bẹẹ kani awọn oṣiṣẹ panapana naa tete de.

Lowurọ ọjọ Aje ni ọpọlọpọ awọn oniṣowo to ni ṣọọbu si agbegbe naa ṣẹṣẹ n mọ ina to jo dukia wọn ti wọn si n gbiyanju ati ṣaa nnkan ti wọn lee ri ko jọ.

Akure fire: Ọ̀pọ̀ oníṣòwò ni ṣọ́ọ̀bù wọ́n jóná lọ́jọ́ Àìkú nílùú Akure ṣùgbọ́n tí ìséde kò jẹ́ kí wọ́n mọ̀

Dukia ẹgbẹlẹgbẹ owo lo tun parun lasiko ti ina nla kan tun sọ lagbegbe Ọba nla ni ilu Akurẹ, olu ilu ipinlẹ Ondo.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ BBC News Yoruba lọwọ ṣe sọ, ileeṣẹ to n ta afẹfẹ idana gaasi kan to wa lagbegbe naa ni ina ọhun ti sọ ni aṣalẹ ọjọ Aiku.

Titi di afẹmọjumọ ọjọ Aje, ọpọ awọn ọlọja to ni ṣọọbu lagbegbe naa ni ko tii mọ bi ina aje ṣe jo wọn to ninu ijamba ina naa nitori ofin konile o gbele eyi ti ijọba ipinlẹ naa gbe kalẹ.

Ọkan lara awọn eeyan ti ile itaja rẹ faragba ninu ijamba ina naa, Ọgbẹni Oluwadare Ọlawale to ba BBC News Yoruba sọrs lori ẹrọ ibanisọrọ ṣalaye pe gbogbo ẹru ati ile oun lo jona raurau. O ṣalaye pe iṣẹlẹ naa ko nii ṣe pẹlu idakureku ina ọba tabi kudiẹkudiẹ ajọ naa nitori ko wulẹ si ina lagbegbe naa tẹlẹtẹlẹ ṣaaju, lasiko ati lẹyin ijamba ina naa.

Bakan naa lọgbẹni Ọlawale jẹ ko di mimọ pe ile ti oun fi ọwọ, owo ati oogun oun kọ wa lara awọn ile to jona ninu ijamba ina naa.

Ile marun un pẹlu ṣọọbu ti ko din ni marundinlọgbọn lo jona lasiko ijamba ina naa.