Kwara: Fọ́fọ́fọ́ ni mọ́ṣáláṣí kún tí ìlànà ìjìnàsíraẹni sí forí ṣánpọ́n lẹ́yìn tí ìrun Jímọ̀ bẹ̀rẹ̀ padà ni Ilorin

Àkọlé fídíò,

Kwara: Fọ́fọ́fọ́ ni mọ́ṣáláṣí kún tí ìlànà ìjìnàsíraẹni 'social distancing' sí forí

Witiwiti lawọn olujosin ẹlẹsin Musulumi ṣi bo awọn Mosalasi nilu Ilorin pẹlu bi ijọba ti ṣe faaye gba ijọsin lawọn Mọsalasi ati ile ijọsin Kristẹni pada.

Akọroyin wa to jabọ lati awọn Mosalasi to wa ladugbo Pakata ni aarin gbungbun Ilorin so pe ọpọ àwọn olujosin ni wọn ni inú awọn dun lati ki Irun pada ni mosalasi Jimọ.

Ni Mosalasi Jimọ Government Girls Day Sec school ni Pakata, mosalasi naa kun fọfọ ni ti ko si si apẹrẹ pe awon eeyan n tẹle ilana ijinasiraẹn lasiko ti arun Covid-19 n ja kalẹ.

Diẹ ninu awọn olujọsin lo lo ibomu ti o sí je pe ati omode ati agbalagba lo wa se ijọsin.

Alfa Ibrahim Igboho to jẹ ọkan ninu awọn alaṣẹ mosalasi naa sọ pe awọn salaye fawọn olujosin gẹgẹ bí ilana ijoba pe ki wọn lo ibomu wá sí mosalasi ṣugbọn kìí ṣe gbogbo eeyan lo tẹle ilana yi.

Laipẹ yi ni ijọba ipinlẹ Kwara dẹwọ ofin to de akojọpọ fun ijọsin.

Bẹrẹ lati ọjọ kokandinlogun awọn sọọsi ati mosalasi láánfàní lati maa ṣe ijosin lalai yọ ẹnikẹni silẹ.

Ṣugbọn to wa nibe ni pe awọn oludari ile ijọsin yi gbọdọ ri pe awọn eeyan tẹle ilana ijinasiraẹni ati ìmọtótó lasiko ijọsin ti won ko si gbọdọ jẹ kí ọrọ iwaasu wọn pẹ pupọ.

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán,

Àwọn ti ọrọ naa ṣe oju wọn ni ojo arọrọda lo fa bi afara naa ṣe ja ni Ọjọ Abamẹta.

Kwara Bridge: Afárá tó já ní Ilorin pa ènìyàn kan, ènìyàn méjì míràn di àwátì

Eniyan kan ti ku, ti won si n wa eniyan meji lẹyin ti afara kan ja ni Oko-Erin, Ilorin ni ipinlẹ Kwara.

Àwọn ti ọrọ naa ṣe oju wọn ni ojo arọọrọda lo fa bi afara naa ṣe ja ni alẹ́ Ọjọ Abamẹta.

Wọn fikun un pe ọkọ ayọkẹlẹ kan n gbe eniyan mẹta lori afara naa nigba ti o ja, ti wọn si ni awakọ ati awọn eniyan naa ja si koto, ti wọn ko si le doola ẹmi wọn.

Oríṣun àwòrán, Others

Loju opo ikansiraẹni ipinlẹ naa ni ijọba ti ni awọn ti bẹrẹ igbesẹ lati wa awọn eniyan meji ti wọn n wa naa lawari.

Wọn fikun wi pe igbese ti bẹrẹ lati ri wi pe wọn dẹkun bi awọn eniyan ṣe n da idọti si oju omi, eleyii to ti fa ki oju odo o kun ni akunfaya.

Oríṣun àwòrán, Others

Bakan naa ni wọn rọ awọn eniyan lati sọra nipa kikọ ile si oju omi nipinlẹ naa, eleyii ti wọn ni o sokunfa bi afara naa ṣe ja.

Oríṣun àwòrán, Others

Nibayii, awọn oṣiṣẹ pajawari n ṣiṣẹ lati ri wi pe wọn tete ri awọn to sọnu naa.