Rape: Ó kéré tán wọ́n ń fipá bá obìnrin kan lòpò láàrín wákàtí márùn ún ní Naijiria

Ọga ọlọpaa abubakar

Oríṣun àwòrán, Twitter/nigeria police

Iye eniyan to to 717 ni wọn ti fipa ba lọpọ lorilẹede Naijiria laaarin Osu Kini si Osu karun un ọdun yii, ti osi fihan pe laarin wakati marun, won fi ipabaobinrin lọpọ.

Ọga Agba Ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Mohammed Adamu lo fi eleyii lede lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lasiko to lọ ṣẹ ipade pẹlu aarẹ Buhari lori ọr ifipabanilọpọ to n ṣẹlẹ kaakiri ni Naijiria.

Adamu ni ohun to buru jai ni nkan to ṣẹlẹ, to si koju ọrọ si awọn aṣebi wọn yii.

Bakan naa o fikun pe eniyan 799 ni o wa ni panpẹ ọlọpaa lori ẹsun ifipabamilopo, ti 631 ninu wọn si ti fi oju ba ile ẹjọ.

Oríṣun àwòrán, AEPA

Ọpọlọpọ awọn eniyan ti wọn fipa balopọ naa ni wọn tun n pa lasiko naa ti iwadii.

Bakan naa ni Ọga Ọlọpaa naa fikun pe awọn sisẹpẹlu awon eto aabo kaakiri Naijira lati ri pe ifipabaniopo

Wo ojú ọmọbìnrin 4 tí afipa báni lòpọ̀ pa ní Nàìjíríà

Ojoojumọ ni akọtun iṣẹlẹ iwa ifipa bani lopọ ati isekupani n waye yika Naijiria, eyi to n mu omi loju ọpọ eeyan.

Awọn ọmọbinrin ti wọn n ku iku aitọjọ yii si lo jẹ akẹkọọ, ti ọjọ ọla rere wa fun, to si ṣee ṣe ki wọn gbe ogo Naijiria ga lọjọ ọla.

Kẹ ba le mọ bi igbe aye awọn ọmọbinrin ti wọn da ẹmi wọn legbodo lọjọ aipe yii ṣe ri, ni BBC Yoruba fi ṣe akojọpọ itan ranpẹ nipa aye wọn.

Barakat Bello:

 • Ọjọ Aiku, ọjọ kọkanlelọgbọn osu kẹfa ọdun 2020, ni wọn pa Barakat Bello lẹyin ti wọn fipa ba a lopọ tan
 • Ẹni ọdun mọkandinlogun ni Barakat Bello nigba ti wọn pa
 • Akẹkọọ ile ẹkọ imọ nipa iwadii eto ọgbin IAR&T nilu Ibadan ni
 • Inu baluwẹ ni ẹyinkule ile rẹ ni Akinyele nilu Ibadan ni wọn ti fipa ba a lopọ, ti wọn si pa
 • Ọwọ ọlọpaa ko tii tẹ afurasi kankan ninu iwadii wọn lati mọ ẹni to pa a
 • Afojusun Barakat ni lati di onimọ giga nipa eto ọgbin, ko to ku ni aipe ọjọ.

Uwaila Omozuwa:

Oríṣun àwòrán, others

 • Ọjọru, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Karun-un ọdun 2020 ni wọn pa Uwa Omozowa nilu Benin, lẹyin ti wọn fipa ba lopọ tan
 • Inu ìjọ Redeem kan ni Benin ni wọn pa si lasiko to n kawe lọwọ
 • Ẹni ọdun mejilelogun ni akẹkọọ ọlọdun kinni, lẹka imọ nipa microbiology ni fasiti ilu Benin naa, nigba to ku
 • Afojusun Uwaila ni lati jẹ ilumọọka ojisẹ Ọlọrun ati oniwaasu agbaye, ti yoo yi ọkan awọn eniyan pada sọdọ Ọlọrun
 • Ọwọ ti tẹ afurasi kan lori iku Uwa, ti iwadii ọlọpaa si fihan pe wọn la ẹrọ iyẹfun panapana mọ lori ni

Azeezat Somuyiwa:

Oríṣun àwòrán, Tribuneonline

 • Ọjọ Eti, ọjọ karun-un oṣu kẹfa ọdun 2020 ni wọn pa Azeezat Somuyiwa, lẹyin ọjọ kẹrin ti wọn pa Barakat
 • Oyun oṣu meje lo wa ninu Azeezat nigba ti wọn pa a lagbegbe Akinyele níbi ti wọn ti pa Barakat naa
 • Ẹni ọdun mọkandinlọgbọn ni Azeezat, ti iwadii si ni wọn gbẹmi rẹ lati fi ṣe oogun owo ni
 • Ọwọ ọlọpaa ti tẹ afurasi kan lori iku obinrin naa, ti kọmisana ọlọpaa si ti gbe ijoko rẹ si agbegbe Akinyele lati sewadii iku awọn obinrin naa
 • Azeezat, ti a ko mọ ile iwe to lọ ni wọn fi okuta ni fọ lori lati gbẹmi rẹ

Grace Oshiagwu:

Oríṣun àwòrán, others

 • Ọjọ Satide, ọjọ kẹtala oṣu kẹfa ọdun 2020 ni ẹnikan tun sekupa Grace Oshiagwu lẹyin tí wọn fipa ba a lopọ
 • Ọmọ pasitọ ijọ CAC kan to wa ni ori Sasa nii ṣe, inu ile wọn to wa lẹyin ile ijọsin naa si ni iṣẹlẹ yii ti waye.
 • Ẹni ọdun mọkanlelogun ni Grace Oshiagwu nigba ti wọn pa lẹyin ti wọn fi tipa ba a lopọ ninu ile baba rẹ
 • Agbegbe Akinyele nilu Ibadan ni wọn tun ti gba ẹmi Grace, níbi ti wọn ti pa Barakat ati Azeezat bakan naa
 • Akẹkọọ ọlọdun kinni ni ẹka imọ nipa akoso oko-owo, Business Administration, nile ẹkọ gbogbonse Poly Oke Ogun si nii ṣe, to si jẹ ọmọ bibi ilu Oguta nipinlẹ Delta
 • Awọn ọlọpaa ko tii ri afurasi kankan mu nipa ẹni to pa Grace