Adams Oshiomole: Idí tí mo fi faramọ́ ìpinu NEC- Oshiomole

Oríṣun àwòrán, Other
Alága ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress tẹ́lẹ̀rí, Adams Oshiomhole sàlàyé lọ́sàn òní pé òun ti faramọ́ ìpinnu ìgbìmọ ẹgbẹ́ (NEC).
Èyí ni ìgbà àkọ́kọ tí Oshiomhole yóò sọ̀rọ̀ láti ìgbà ti gbogbo ǹkan ti n rú gùdùgùdù nínú ẹgbẹ òṣèlú APC, eyi ti wọ́n sì fi yọ Oshiomhole kúrò nípò gẹ́gẹ́ bi alága.
- Iṣẹ́ márùn ún tí àwọn adarí ẹgbẹ́ APC gbọ́dọ̀ ṣe kíákíá kí omi má tẹ̀yìn wọ ìgbín lẹ́nu
- Iré dé! MTN àti BBC World Service bẹ̀rẹ̀ àjọṣepọ̀ lórí ìròyìn ìṣẹ́jú kan BBC
- Ẹbí Abiola Ajimobi kéde bí ètò ìsìnkú rẹ̀ yóò ṣe rí pé...
- A wà nínú igbó tí a ti ń wá àwọn arinrìnàjò mẹ́jọ láti Abuja sí Eko tí wọ́n jígbé lọ- Ọlọ́pàá Ondo
- Wo odò tí wọ́n ti rí Aishat tí àgbárá òjò gbé lọ ní Eko
Oshiomhole ní, òun kò kábàmọ́ gbogbo ìgbésẹ̀ ti òun ti gbé sẹyin.
O ni gbogbo nkan ti oun ṣe lásìkò ti òun jẹ alága ẹgbẹ́ APC lo tẹ oun lọrun ati pe, òun sì wà lẹ́yìn ìjọba ààrẹ Muhammadu Buhari lọ́jọ́kọ́jọ́.
Ibadan Death: Àwọn ará àdúgbò Akinyele ké sita lórí iṣékúpani tó ń wáyé ní ìlú Ibadan.
Adams Oshiomole ní ààrẹ Buhari pe òun sínú ẹgbẹ́ APC gẹ́gẹ́ bi alága láti ṣe àtúntò ẹgbẹ́ ní, àti pé ààrẹ Buhari kan náà ló lo oyé rẹ̀ láti gbárúkù ti bi wọn ṣe tú ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe náà ká.
O mẹnuba pataki titẹ̀lé àṣẹ́ ẹgbẹ́ boya o tẹ eeyan lọrun tabi bẹẹkọ nitori pe ifẹ ẹgbẹ lo ṣe pataki julọ.
- Wo bí o ṣe lè di aṣojú tó ṣe pàtàkì nínú àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé 'UN Goodwill Ambassador'
- Àwọn èèyàn ìpínlẹ́ Ondo kò gbàgbọ́ pé Coronavirus wà lọ jẹ́ kó máa pọ̀ síi - ìjọba
- Wo bí ọwọ́ orílẹ̀-èdè Dubai ṣe tẹ Ramoni Igbalode tí gbogbo ayé ń pè ní Hushpuppi
- Wo àwọn èèyaǹ jàǹkàn mérin tí àrùn Coronavirus ti sọ dèrò ọ̀run ní Naijiria
Oríṣun àwòrán, Others
Ilé ẹjọ́ kòtẹ́mílọ́rùn yọ alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC Adams Oshiomhole nípò
Adams Oshiomhole: Ilé ẹjọ́ kòtẹ́mílọ́rùn yọ alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC Adams Oshiomhole nípò
Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ti ilú Abuja ti yẹ àga mọ alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Adams Oshiomhole nídìí
Ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mẹ́tà ti adájọ́ Eunice Onyemanam sójú fún ni wọ́n fẹnu kò láti jan idájọ́ tí ilé ẹjọ́ ti kọ́kọ́ dá tẹ́lẹ̀ lóntẹ̀.
Sáájú ni Oshiomhole ti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ìdájọ́ tí àdájọ Abubakar Yahaya sì dájọ pé kí ìdájọ́ náà dúró náà kí ó ṣì maa ṣe alága lọ́ títí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn yóò ṣe fìdímúlẹ̀.
Port harcourt Bole: Mi kò mọ́ pé bọ̀ọ̀lì títà lè gbé mi dé ipò yìí láyé mi!
Adajọ Onyemanam to dárí ẹjọ́ to wáyé lónìí ọjọ́ iṣẹgún lo dá ẹjọ́ náà ló fídí rẹ̀ múlẹ pé ìdájọ́ ilé ẹjọ́ kekere to yọ Adams Oshiohmole gẹ́gẹ́ bi alágá ni inú ọṣù kẹta ọdún yìí ṣe ǹkan to yẹ ati pé, ẹjọ́ kòtẹ́mílọ́rùn ti Oshiomhole pè kò fìdì múlẹ̀.
- Iré dé! MTN àti BBC World Service bẹ̀rẹ̀ àjọṣepọ̀ lórí ìròyìn ìṣẹ́jú kan BBC
- Wo bí o ṣe lè fí orúkọ rẹ sílẹ̀ fún iṣẹ́ N Power tuntun ti ọdún 2020
- Yàtọ̀ sí coronavirus, wo ìgbà mẹ́wàá míì táwọn mùsùlùmí kò lè ṣiṣẹ́ Hajj
- A wà nínú igbó tí a ti ń wá àwọn arinrìnàjò mẹ́jọ láti Abuja sí Eko tí wọ́n jígbé lọ- Ọlọ́pàá Ondo
Oríṣun àwòrán, Twitter/Godwin Obaseki
Godwin Obaseki: Ṣé Godwin Obaseki yóò darapọ̀ mọ́ PDP ni tàbí yóò gba kádàrá?
Gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki ti fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ lẹyin ọpọlọpọ awuyewuye lori yiyọ ti wọn yọ ọwọ rẹ kuro lawo idije fun ipo gomina labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Edo.
Godwin Obaseki ti kọwe fipo silẹ gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC lẹyin ipade rẹ pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari ni ilu Abuja ni ọjọ Iṣẹgun.
O ti to ọjọ mẹta bayii ti wahala ti bẹ silẹ laarin gomina Obaseki ati alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu APC lorilẹede Naijiria, Adams Oshiomhole.
Atunbọtan itaporogan laarin awọn mejeeji yii gẹgẹ bi igbagbọ ọpọ onwoye ọrs oṣelu ni bi igbimọ ayẹwo fun awọn oludije idibo abẹle lati yan oludije fun ipo gomina labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC fi paṣẹ pe ko ni lee kopa nitori ohun ti wọn pe ni aidọgba lori awọn iwe ẹri rẹ.
Bi o tilẹ jẹ wi pe ileewe giga fasiti ibadan ti bọ sita lati kede pe akẹkọjade ileewe naa ni, sibẹ igbimọ kotẹmilọrun ti ẹgbẹ oṣelu AOC gbe kalẹ lori eto ayẹwo naa pẹlu fọwọ si igbesẹ igbimọ ayẹwo naa.
Ibadan Death: Àwọn ará àdúgbò Akinyele ké sita lórí iṣékúpani tó ń wáyé ní ìlú Ibadan.
Nibayii, ibeere to wa lẹnu ọpọlọpọlọ awọn eeyan ni pe nibo lo kan fun gomina obaseki abi ṣe o ti gba fun Ọlọrun naa niyẹn.
Amọṣa gẹgẹ bi ọpọlọpọ ṣe mọ nipa awọn oloṣelu Naijiria, ko ṣeeṣe ko gba f'Ọlọrun bẹẹ.
Ohun ti ọpọ n woye rẹ lọwọ bayii ni pe boya yoo ko ẹru oṣelu rẹ lọ ba ẹgbẹ oṣelu PDP pẹlu bi o ti ṣe n rin irinajo kaakiri ọdọ awọn gomina ipinlẹ to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP bii Wike ti Rivers ati Udom ti ipinlẹ Akwa Ibom.
Mobile Wash: iṣẹ́ fífọ́ mọ́tò tà ni mó yàn láààyò- Slay Mama