Oluwatoyin Salau: Òkú Toyin làwọn ọlọ́pàáTallahassee ni àwọn rí lẹ́yìn ìpè rẹ̀ lórí twitter

Toyin

Oríṣun àwòrán, Virgintoyin/twitter

Àkọlé àwòrán,

Toyin poora lẹyin to figbe ta nipa ifipabanilopo loju opo Twitter - ka ohun ta mọ nipa iku rẹ

Ileesẹ ọlọpaa gẹgẹ bi ohun ti BBC ri fidi rẹ mulẹ ti sọ pe awọn ti ri oku arabinrin Oluwatoyin Salau lẹyin ọjọ meloo kan ti wọn fi se awati.

Toyin,Ọmọ ọdun mọkandinlogun ajafẹtọmọniyan ọmọ Naijiria ọhun to fi ilẹ Amẹrika se ibugbe bawọn se iwọde Black Lives Matter to waye ni Florida ni Amẹrika.

BBC pidgin lẹyin iwaadi ri wi pe ileesẹ ọlọpaa Tallahassee kede pe o di awati ni ọjọ Kẹsan osu Kẹfa 2020, sugbọn lẹyin ọjọ diẹ ni wọn kede pe awọn ri oku rẹ ni irọlẹ ọjọ Kẹẹdogun osu Kẹfa.

Àkọlé fídíò,

Ìtàn Olaniyi Balogun, ọ̀jọ̀gbọ́n tó fi Nàìjíríà sílẹ̀ lọ gba iṣẹ̀ àgbẹ̀ l'Ámẹ́ríkà

Ohun ta gbọ ni pe ajafẹtọmọniyan naa poora lẹyin to gbe ọrọ sita loju opo Twitter pe eeyan kan gbiyanju lati fipa ba ohun lopọ ni adugbo Park Avenue and Richview Road ni Tallahassee, Florida.

Ninu ọrọ to fi sita, o ni ọkunrin naa sọ pe ohun yoo fi ọkọ gbe oun pada lọ si sọọsi kan tohun fori pamọ si.

Ọrọ ti Oluwatoyin fi sita kẹhin re ki o to di pe awọn ọlọpaa ri oku rẹ

Gẹgẹ bi ohun ti awọn ọlọpaa sọ ni nkan bi ago mẹsan alẹ kọja isẹju mẹẹdogun lọjọ kẹtala osu Kẹfa ni awọn oluwadi de si ile ibugbe 2100 block to wa ni Monday Road lati se iwaadi to ni se pẹlu eeyan kan ti wọn ni o di awati, iyẹn Oluwatoyin Salau.

Lasiko iwaadi wọn ri oku meji ni agbegbe naa.

Wọn ni awọn ri oku rẹ pẹlu ti iya agbalagba kan ẹni ọdun marundinlọgọrin lẹgbẹ Wahnish Way and Orange Avenue, Tallahassee..

Oríṣun àwòrán, Screenshot/twitter

Àkọlé àwòrán,

Toyin poora lẹyin to figbe ta nipa ifipabanilopo loju opo Twitter - ka ohun ta mọ nipa iku rẹ

Oluwatoyin Salau jẹ ọkan gbogi ninu awọn to n fẹhonu han lori iwa ifiyajẹni si ara ilu lati ọwọ awọn ọlọpaa.

Bi iwaadi naa se n tẹsiwaju awọn ọlọpaa ni awọn ti ri afurasi kan to wa ni ahamọ bayi ti awọn ko si ni iroyin kankan lati fi to ara ilu leti lọwọ yi nipa isẹlẹ naa.

Awọn ọlọpaa ni oju ẹsun isekupani lawọn fi n wo iku Oluwatoyin ati ti Iya arugbo ẹni ọdun marundinlọgọrin ti wọn jijọri oku wọn.

Wọn ni awọn ti gbe ọrọ naa le ẹka ileesẹ ọlọpaa to n sewadi awọn iwa ọdaran to le lọwọ.

Awọn oluwaadi ti kesei ẹnikẹni to ba ni iroyin to le mu ki awọn ri awọn to hu iwa yi lati kan si awọn lori ago 850-891-4200 tabi Crime Stoppers lori ago 850-574-TIPS.

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán,

Toyin poora lẹyin to figbe ta nipa ifipabanilopo loju opo Twitter - ka ohun ta mọ nipa iku rẹ

Oríṣun àwòrán, @virgingrltoyin/twitter

Àkọlé àwòrán,

Toyin poora lẹyin to figbe ta nipa ifipabanilopo loju opo Twitter - ka ohun ta mọ nipa iku rẹ

Ijọba Naijiria ti pe fun iwaadi ẹkunrẹrẹ lori iku Toyin

Awọn alasẹ Naijiria ko foju kere isẹlẹ iku Toyin yi.

Ọga ileesẹ Naijiria to n boju to awọn ọmọ ilẹ yi nilẹ okere(NIDCOM)

iyẹn Abike Dabiri-Erewa sọ pe iku ọmọ ọdun mọkandinlogun Oluwatoyin yi jẹ iwa ika to buru to si tun bani lọkan jẹ.

Abike Dabiri-Erewa,alaga ajọ NIDCOM ti wa kesi ijọba Amẹrika lati se iwaadi to peye lati le tu isu de isalẹ koko nipa ohun to sokunfa iku arabinrin Slau.

Bẹẹ naa lo fi ọrọ ibanikẹdun ransẹ si awọn mọlẹbi arabinrin Salau to padanu ẹmi rẹ lasiko to n ja fẹtọmọniyan lọwọ ifiyajẹni ati aisedeede.