Deaf parents and siblings: Láàrín ìdílé ẹlẹ́ni márùn ún yìí, ọmọ kan ṣoṣo ló léè sọ̀rọ̀

Deaf parents and siblings: Láàrín ìdílé ẹlẹ́ni márùn ún yìí, ọmọ kan ṣoṣo ló léè sọ̀rọ̀

Tani Ifeoluwa ti o jade lati inu ẹ̀bi awọ́n odi yii?

Ọdọmọkunrin kan to jẹ ẹnikan ṣoṣo to lee sọrọ laarin idile ẹlẹni marun un ba BBC Yoruba sọrọ lori idojukọ rẹ.

Ọmọ ọdun mẹrindinlogun naa, Ajekigbe Ifeoluwa Martins sọ pe o jẹ iyalẹnu fun oun pe awọn obi oun ko le sọrọ, ati pe o ṣoro lati ba awọn obi oun sọrọ nigba ti oun wa ni kekere.

Ṣugbọn aile sọrọ awọn obi rẹ lo mu ko lọ kọ bi wọn ṣe n ba awọn odi ati aditi sọrọ.

Kini awon ipenija ti Ifeoluwa menuba ati ọ̀nà abayo?

O ni ẹdun ọkan nla lo jẹ fun oun pe awọn obi atawọn aburo oun ko le sọrọ, ṣugbọn itọju ti wọn fun oun jẹ ohun iwuri.

Bo tilẹ jẹ pe awọn obi ati aburo rẹ ko le sọrọ, o ni oun nifẹ ẹbi naa, ati pe oun yoo ṣetọju awọn obi naa ti ọna ba ti la fun oun lọjọ iwaju.

Awọn mọlẹbi obi ọmọdekunrin naa tun ba BBC sọrọ lori ipinlẹ bi wọn ko ṣe le sọrọ.

Ẹ wo fidio yii fun ẹkunrẹrẹ.