Jimoh Aliu: Wo àwọn nkan tí o kò mọ̀ nípa Jimoh Aliu tó d'ólóògbé

Oríṣun àwòrán, NTA ado-ekiti/city people magazine
Ọjọbọ, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2020 ni ilumọọka osere tiata, Jimoh Aliu ti dagbere faye.Nigba aye rẹ, Jimoh Aliu ṣe gudugudu meje ati yaya mẹfa lati mu iyatọ ba iṣẹ tiata lori mohunworan.
Ṣaaju iku rẹ, Aliu n ṣiṣẹ lori fiimu maarun, ti ireti wa pe awọn agbaagba oṣere Nollywood yoo kopa ninu rẹ. Ṣugbọn, iku mu u lọ lasiko to n ya ọkan ninu rẹ to pe akọle rẹ ni "Olowo Ite".Ṣugbọn bi onirese Aliu ko ba fingba mọ, eyi to ti fin silẹ lagbo iṣẹ tiata ko le parun.
Oríṣun àwòrán, Nta ado-ekiti/twitter
Idi ree ti BBC Yoruba fi ṣe akojọpọ awọn ohun ti ko fi bẹ ẹ han si awujọ nipa igbeaye oloogbe naa.
Ibẹrẹ pẹpẹ Jimoh Aliu
Ni nkan bii ọdun 1939 ni wọn bi oloogbe Jimoh Aliu, nilu Okemesi, nipinlẹ Ekiti.
Oríṣun àwòrán, Youtube/Oganla Tv
Bo tilẹ jẹ pe ọmọ ilu Oke-Imesi nipinlẹ Ekiti ni, ilu Ikare-Akoko, to wa ni ipinlẹ Ondo bayii, lo ti da ẹgbẹ tiata tiẹ, Jimoh Aliu Concert Party, silẹ lọdun 1966.
Oun ati gbajugbaja oṣerebinrin, Folake Aremu 'Oriṣabunmi', ti fi igba kan jẹ tọkọ-taya, kii wọn o to tuka lẹyin ogun ọdun.
Yatọ si Oriṣabunmi, O ni iyawo meji miran - Queen Bola ati Folashade.
Fadeyi Oloro: Ọfọ̀, àyájọ́ kò ràn án lọ́jọ́ tí 'ṣó o láyà' bá a lálejò
Oloogbe Jimọh Aliu ni iroyin sọ pe o da ẹgbẹ awọn oṣere tiata silẹ ni Naijiria, ANTP. Oun naa si ni aarẹ akọkọ fun ẹgbẹ naa.
O ṣiṣẹ gẹgẹ bi ọmọ ologun
Oríṣun àwòrán, NTA Ado-Ekiti/twitter
O ṣiṣẹ ologun nileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria fun ọdun mẹjọ, laarin ọdun 1967 si 1975.
To si jẹ pe o ma n fi ere ori itage da awọn ọmọ ogun to wa loju ija lasiko ogun abẹle 'Biafra' lara ya.
O ṣiṣẹ ni awọn ilu bi Uyo, Eket, Enugu, Onitsha, Aba, Port Harcourt, Benin, ati awọn ilu kan ni Ariwa Naijiria.
Lara awọn ere ori itage to ṣe fun awọn ọmọ ogun ni Arugbo soge, Fesojaye, ati Ojuẹnimala.
Bakan naa lo ṣere fun gomina ipinlẹ mejila, ni gbọngan to wa ni ile ẹkọ awọn ọlọpaa, Kaduna lasiko ọsẹ ere idaraya fun awọn ọmọ ogun lọdun 1975.
Ijọba Naijiria fi ami ẹyẹ MFR da a lọla
Lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti o ti ṣe gudu-gudu meje ati yaaya mẹfa ninu iṣẹ tiata, ijọba orilẹ-ede Naijiria fi ami ẹyẹ 'National Member of the Federal Republic (MFR) da a lọla, fun ipa ribiribi to ko ninu idagbasoke orilẹ-ede Naijiria.
Wo ìdílé tí ìyá àti gbogbo ọmọ kara bọ iṣẹ́ ṣíṣe epo tà
Yatọ si pe o jẹ gbajumọ oṣere, ati oniṣegun ibilẹ, oloogbe Jimoh Aliu kọṣẹ gẹgẹ bi birikila, aranṣọ ati awakọ.
Oríṣun àwòrán, Instagram/jimohaliuaworo
Oríṣun àwòrán, Instagram/jimohaliuaworo
Ohun meje ti Jimoh Aliu fi yatọ laarin oṣere tiata yoku
Ohun akọkọ to mu Jimoh Aliu, ti ọpọ eeyan mọ si Aworo, fi yatọ ni pe ojuse marun lo n ṣe nidi iṣẹ tiata.Yatọ si pe o mọ ere ṣe, Jimoh Aliu tun jẹ Agbẹ́gilére, onkọtan, oludari ere ati elere onise.Baba rẹ, Aliu Fakoya jẹ babalawo nilu Oke Imesi, ti oun naa si mọ nipa isẹ awo, to si maa n ko ipa Aworo ninu ere.
Oríṣun àwòrán, Instagram/jimohaliuaworo
Ọdun meje ni Jimoh Aliu fi kọ iṣẹ tiata lọdọ Akin Ogungbe, ko to gba iyọnda lati da ẹgbẹ osere tiata tiẹ silẹ nilu Ikare.Jimoh Aliu tun dara pọ mọ iṣẹ ologun lọdun 1967, ó si wa ni ẹka oṣere tiata ologun, amọ o fi ẹyin ti ninu isẹ ologun lọdun 1975, to si wọ kaki ologun fun ọdun mẹjọ gbako.Jimoh Aliu ni oṣere tiata to kọkọ bẹrẹ ere itage ọlọsẹ mẹtala lori mohunworan pẹlu ere Arelu, Yánpọnyánrin, Fopomoyo ati Ajalu.
'Ọ̀nà àtijẹ kan ṣoṣo táa ní ni Màálù àwọn Fúlàní ti bàjẹ́'
Oríṣun àwòrán, Instagram/jimohaliuaworo
Nipari, Jimoh Aliu fa ori ọpọ oṣere tiata soke nigba aye rẹ, to si sọ wọn di ilumọọka ati olokiki.
Lara wọn ni aya rẹ, Folake Aliu, ti ọpọ mọ si Orisabunmi, pẹlu Fadeyi Oloro, Owootori ati Toromagbe.
Bàbá ní Jimoh Aliu jẹ fún mí lọ́jọ̀ kọ́jọ̀-Orisabunmi
Ninu awọn to ba ileeṣẹ BBC Yoruba sọrọ ni Iya Ooṣa Folake Aremu ti a mọ si Orisabunmi ati Adebayo Salami, Ọga Bello.
Oríṣun àwòrán, Youtube/Oganla Tv
Orisabunmi banujẹ lori iku Jimoh Aliu to si ni ''Baba ni Jimoh Aliu jẹ fun wa, Baba ni wọn jẹ fun mi, Baba alalubarika ni wọn jẹ lọjọkọjọ''
Tibanujẹ tibanujẹ lọkan ni o wa fi ṣadura pe ki Eledua maa ṣe fi ọwọ ibajẹ kan gbogbo nkan ti Jimoh Aliu fi saye lọ.
Bakan naa ninu ọrọ ti ọga Bello,Adebayo Salami sọ, o ni Jimoh Aliyu jẹ ẹnikan to gbe aṣa larugẹ.
''O ṣe wa laanu pe iku rẹ wa lasiko yi. Ẹnikankan ko le gbagbe ipa to ko lati jẹ ki ere ori itage dagba soke.''
Oríṣun àwòrán, Instagram/jimohaliuaworo
Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni wipe ọkan lara awọn agba ọjẹ ninu fiimu Yoruba ti jẹ Ọlọrun nipe.
Loju opo ayelujara awọn agba oṣere atawọn akẹgbẹ rẹ mii ni idaro ti n tu sita bayii.
Baba Jimoh Aliyu ti ọpọ mọ si Aworo jade laye lẹni ọgọrin ọdun.
Pa Kasumu tó ni ohùn ló lọ.Ohùn tó fi sílẹ̀ kò ní parẹ́.
Fadeyi Oloro: Ọfọ̀, àyájọ́ kò ràn án lọ́jọ́ tí 'ṣó o láyà' bá a lálejò
Arelu ni ere ti o gbe agba ọjẹ Jimoh Aliu saye ti ọpọ si ni ipa ribiribi to ko ninu rẹ jẹ manigbagbe.
Yatọ si Arelu, o tun kopa ninu ere mii bi:
- Iku Jare Eda,
- Igba Oro
- Agbaarin
- Yanpon-Yanrin
- Ẹwa
- Igbo Ẹlẹjẹ
- Irinkerindo
- Rukerudo
- Ajalu
Ọdun 1959 ni Jimoh Aliu bẹrẹ si ni kopa ninu ere ori itage nigba ti Akin Ogungbe ṣabẹwo si ilu rẹ.
Lọdun 1966 to ti pe ọdun meje ti o ti lo lọdọ Ogungbe, Jimoh Aliu da ẹgbẹ ere ori itage tirẹ silẹ nilu Ikare, Jimoh Aliu Concert Party.
Oríṣun àwòrán, Instagram/jimohaliuaworo