Mama Arsenal: Ẹgbẹ́ kan ti fún màmá ní ẹ̀bùn owó

Mama Arsenal: Ẹgbẹ́ kan ti fún màmá ní ẹ̀bùn owó

Bi a ba ku, iṣe o tan ni Yoruba maa n wi. Bẹẹ gẹlẹ ni ọrọ ri pẹlu mama agba ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, Nosimatu Hassan.

Mama to jẹ ẹni ọdun mẹtadinlọgọrin di ẹni ti ọgọọrọ eeyan n sọ nipa rẹ lori ayelujara lẹyin ti sọ ọpọ ọrọ nipa ẹgbẹ agbabọọlu to yan laayo.

Lati igba naa ọpọ ẹlẹyinju aanu ọmọ Naijiria ti n ṣeleri lati fun mama ni ẹbun kan tabi omiiran.

Ṣugbọn ni bayii, ẹgbẹ ololufẹ awọn ikọ agbabọọlu Naijiria, Authentic Nigeria Supporters' Club ti fun mama ni ẹbun owo rọgun rọgun.

Oríṣun àwòrán, Facebook/ANFASC

Owo ti ẹgbẹ ololufẹ agbabọọlu Naijiria naa fun mama Arsenal ni ṣe ẹgbẹrun un lọna ọta le lugba o din mẹwaa.

Ọlọ́run ló yàn mí ti Arsenal, mi ò lè fi wọ́n sílẹ̀ láéláé- Mama Arsenal yarí

Ara meriri , mo ri ori ologbo lori atẹ ni ọrọ mama agba kan, Nosimatu Hazzan, ti ọpọ eeyan mọ si mama Arsenal.

Mama agba yii, to nifẹ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal bii oju, ti ọjọ ori rẹ yoo si to aadọrin ọdun, lo nifẹ ere bọọlu ju ọmọde tabi awọn ọkunrin miran lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lasiko ti BBC se abẹwo si ọdọ mama naa, ti ọpọ eeyan mọ si Mama Arsenal nitori bo se nifẹ si ẹgbẹ agbabọslu Arsenal, ẹnu ko gba iroyin.

Ko fẹẹ si agbabọọlu Arsenal tẹlẹ abi lọwọlọwọ bayii ti mama naa ko lee darukọ, to si ni oun maa n wo bọọlu ninu ile oun tabi lọ sawọn ibudo ti wọn ti n wo bọọlu.

Bakan naa lo ni oun maa n lọ sawọn papa isere idaraya nilu Eko lati wo ere bọọlu, ti oun si nifẹ ere sisa, awọn ere idaraya miran lorisirisi, paapaa ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal.