BBC Africa Eye: ìwádìí ìkọ̀kọ̀ BBC fihàn pé àwọn kan ń jí ohun eèlò ìdáàbòbò ìjọba tà nígboro

BBC Africa Eye: ìwádìí ìkọ̀kọ̀ BBC fihàn pé àwọn kan ń jí ohun eèlò ìdáàbòbò ìjọba tà nígboro

Se o yẹ ki a maa tun fiya jẹ ara wa nilẹ Adulawọ lori ọrọ Coronavirus?

Ọpọlọpọ ẹmi lo ti sọnu nipasẹ coronavirus ni eyi ti awọn eeyan si ti gba kadara si.

Opọ n fẹsun kan ijọba orilẹ-ede wọn pe wọn ko pese awọn ohun eelo to peye lati koju ajakalẹ arun coronavirus to n gbẹbọ lọwọ gbogbo agbaye yii.

Ṣugbọn iwadii ikọkọ ti BBC Africa Eye ṣe ni orilẹ-ede Ghana fihan pe awọn oṣiṣẹ eleto ilera gan an n ṣe ara wọn ti wọn si n ji ohun eelo ko ta nigboro.

Anas Aremeyaw lo ṣaaju awọn to ṣe iwadii naa nibiti ọwọ si ti tẹ apoogun oyinbo to jé ọga agba nile iwosan nla ni Ghana, Thomas Osei ati Divine Kumordzi to jẹ oṣiṣẹ eleto ilera.

Ṣaaju ni fọnran yii ṣafihan eto isinku dokita akọkọ ti coronavirus pa ni Ghana.

Koda, awọn ẹni ibi tun n ta awọn ohun eelo itọju alaisan Covid 19 nibẹ.

Dokita Hadi Abdallar banujẹ lori iwadii yii lataari ọpọ ẹmi to ti sọnu nipasẹ iwa ika awọn alatẹnujẹ kan nilẹ Adulawọ.

Lẹyin iwadii BBC Africa Eye yii, awọn alaṣẹ ile iwosan ti ọrọ kan ti ni ki awon ti BBC gba mu lọ rọọkun nile na titi wọn o fi pari iwadii ti wọn.

Ileeṣẹ BBC ti ko gbogbo ohun eelo ilera ti a ra lati fi gba awọn oniṣẹ ibi yii mu pada si ile iwosan nlanla gẹgẹ bii ẹbun.