Bauchi woman: Balaraba Ibrahim tó jẹ́ Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin tí a kọ̀ sílẹ̀ jẹ́ kàyééfì ní Nàìjíríà

Oluranlọwọ

Oríṣun àwòrán, others

Ṣaaju ni oriṣiriṣi ẹjọ ti jade lori bi gomina ipinlẹ Bauchi to wa ni ariwa Naijiria ṣe yan arabinrin Balarabe Ibrahim sipo oluranlọwọ pataki.

Bo tilẹ jẹ pe awuyewuye waye lori iyansipo naa, ti ọpọ eeyan si n sọ pe oluranlọwọ pataki lori ọrọ awọn ti ko ni ọkọ tabi iyawo ni gomina yan obinrin naa si.

Ṣugbọn bayii, ijọba ipinlẹ Bauchi ti salaye oun ti ipo naa wa fun.

Àkọlé fídíò,

BBC Africa Eye: ìwádìí ìkọ̀ks BBC fihàn pé àwọn kan ń jí ohun èèlò ìdáàbòbò ìjọba tà nígbo

Gomina Bala, sọ lati ẹnu agbenusọ rẹ pe iyansipo naa kii ṣe babara, nitori pe Balaraba wulẹ̀ ti n ṣe Alaga ẹgbẹ awọn obinrin to ti kọ ọkọ wọn silẹ ni ipinlẹ Bauchi tẹlẹ.

Ati pe, O maa n ṣeto ipade laarin awọn obinrin naa, o si máa n ṣe iṣẹ alarina fún awọn to ba fẹ ẹ pada ni ọkọ.

Tani Balaraba Ibrahim?

Iya n da gbe ni Balaraba fúnra rẹ jẹ, pẹlu awọn ọmọ rẹ.

Iru iyansipo yii kii ṣe nkan ti oju ko riri ni Ariwa orilẹ-ede Naijiria, nitori pe wọn ni i ni ipinlẹ Kano.

Ẹni ti gomina ba yan si ipo naa ni yoo ma a mojuto bi awọn to ti kọ ọkọ tabi iyawo wọn silẹ yoo se pada ni ololufẹ miran, paapaa nitori pe ijọba maa n ṣe ayẹyẹ igbeyawo alasepọ fun wọn.

Ijọba Bauchi ti ẹ sọ pe awokọse ipinlẹ Kano ni oun ṣe.

Ni ipinlẹ Kano bakan naa, wọn ni oye oluranlọwọ pataki lori ibojì òkú.

Oríṣun àwòrán, @Bauchi

Bẹẹni, oju yin ko kuku tan yin jẹ.

Oye yii ni gomina maa n fun eeyan, lati ma a mojuto ọrọ to ba ni i ṣe pẹlu awọn ibi tí wọn n sin oku si nipinlẹ naa.

Oye miran to tun jẹ iyalẹnu ni agbo oṣelu Naijiria ni oye oluranlọwọ pataki lori ọrọ awọn ina ti ijọba n tàn si adugbo, 'street lights'.

Ipinlẹ Kano ni gomina ti fi eeyan kan si ipo yii ni ọdun to kọja.

Oríṣun àwòrán, Others

Gomina Ganduje Abdullahi yan Yakubu Nagoda sipo olubadamọran lori ọrọ iboji oku.

Nagoda kọwe fipo rẹ silẹ lọdun 2018.

Nipinlẹ Imo, awuyewuye waye ni ọdun 2017, nigba ti gomina wọn tẹlẹ, Rochas Okorocha ṣe idasilẹ ileesẹ idunnu, Ministry of Happiness.

Àkọlé fídíò,

Working religious women: Ẹ̀lẹ́hàá kìí ṣe ọ̀lẹ- Aminat Adegoke

Koda, Gomina Rochas yan kọmiṣọnna ti yoo ma a dari rẹ.

O ni ileesẹ naa yoo ma a ran awọn ileesẹ ìjọba yooku lọwọ lati ma a mu inu ara ìlú dùn.

Àkọlé fídíò,

Ìdílé tí ọkọ da ọmọ síta tóríi ojú Búlùú tí wọ́n ní bá BBC sọ̀rọ̀