Diezani gan an ní Hushmummy tó ń bú àwọn Yahoo boys- Àwọn Ọmọ Naijiria lórí Twitter

Diezani

Oríṣun àwòrán, SAMUEL KUBANI

Awọn ọmọ Naijria ti bu ẹnu atẹ lu ọrọ ti minisita fun ọrọ epo bẹntirolu ni Naijiria tẹlẹri. Diezani Alison-Madueke sọ nipa ihuwasi awọn gbajuẹ ati Yahoo-yahoo ni awujọ.

Diezani Alison-Madueke ni oṣe ni laanu pe awọn oniwa jibiti ni awọn eniyan n gbe larugẹ, ti wọn si n wo gẹgẹ bi awọkọṣe ni Naijiria.

Arabinrin naa sọ eyi ninu fidio kan to n ja ranyinranyin lori ayelujara, nibi ti o ti n sọrọ ni ipade ti wọn ṣe fun awọn ọmọbibi ilu Ijaw lori ayelujara.

Amọ awọn ọmọ Naijiria to fesi si fidio naa lori Twitter ni iru ọrọ bẹẹ ko tọ si ẹnu Madueke nitori oun jẹjọ iwa ibajẹ lọwọ lorilẹ-ede Naijiria.

Àkọlé fídíò,

BBC Africa Eye: ìwádìí ìkọ̀ks BBC fihàn pé àwọn kan ń jí ohun èèlò ìdáàbòbò ìjọba tà nígbo

Wọn ti lẹ pe e ni iya awọn gbajuẹ ati yahoo-yahoo ni Naijiria.

Àkọlé fídíò,

Working religious women: Ẹ̀lẹ́hàá kìí ṣe ọ̀lẹ- Aminat Adegoke

Amọ, awọn eniyan kan gboriyin fun Diezani Alison-Madueke fun ọrọ to sọ tako iwa jibiti lawujọ.

Oluranlọwọ fun Aarẹ Buhari lori ọrọ Iroyin, Bashir Ahmad naa wa lara awọn to ni ọrọ to dara ni Diezani sọ, ati wi pe ki awọn eniyan fi i silẹ.

Àkọlé fídíò,

Peters Ijagbemi dá àrá lórí ètò 'Ṣé o láyà' ti BBC Yorùbá lọ̀sẹ̀ yìí

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lorilẹ-ede Naijiria EFCC n ṣewadii Minisita tẹlẹri naa, Dieziani Alison-Madueke fun ẹsun iwa ibajẹ ati jẹgudujẹra lasiko to wa ni ipo.

Amọ, iroyin ni Olootu ijọba Dominica, Roosevelt Skerrit ti yan Dieziani Alison-Madueke gẹgẹ bi kọmisọnna fun eto oro ajẹ lorilẹ-ede naa, ti wọn si fun un ni iwe igbelu.

Iroyin ni eleyii ti fun Dieziani Alison-Madueke ni anfaani lati le bọ lọwọ ajọ EFCC to n ṣewadii rẹ lati igba to ti wa ni ilu London fun ọdun mẹrin bayii.

Àkọlé fídíò,

Itan Ilu gangan