The Polytechnic Ibadan: Ẹ̀rọ abẹ́lé tó ń fọ ọwọ́ àti ‘Ventilator’ ló ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé jáde

The Polytechnic Ibadan: Ẹ̀rọ abẹ́lé tó ń fọ ọwọ́ àti ‘Ventilator’ ló ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé jáde

Oriire ti de fun orilẹede Naijiria lati ipasẹ agbekalẹ erọ tuntun meji ti ile ẹkọ gbogbonse Poly Ibadan gbe jade.

Ẹrọ akọkọ ni ẹrọ ifọwọ mẹtadọkan, eyi to n tẹ omi ati ọṣẹ sọwọ eeyan fun ra rẹ, ti yoo si tun tẹ afẹfẹ si ọwọ eeyan lẹyin taa ba fọ ọwọ wa tan.

Ẹrọ keji ni ẹrọ Ventilator, to n seranwọ lati jẹ ki alaisan lee mi jalẹ daadaa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n sọrọ lori idi ti ile ẹkọ Poly Ibadan fi se agbekalẹ awọn ẹrọ mejeeji naa, Alhaji Soladoye Adewole, tii se osisẹ alukoro agba fun ile ẹkọ naa ni ọna lati se ohun ti yoo seranwọ nidi itọju arun Coronavirus lo sokunfa rẹ.

Bakan naa lo ni wọn se tun se awọn ẹrọ ọhun lati seranwọ fun araalu ni lasiko ajakalẹ arun Coronavirus yii.

Ile ẹkọ Poly Ibadan ni oun ti gbe ẹrọ Ventilator fun ayẹwo nile ẹkọ Poly Ibadan, ti wsn si ni o n sisẹ bo se yẹ.