Nigeria international flight resumption: Àwọn ìlànà tuntun ti o gbọdọ tẹlèé rèé ki ó to le wọkọ̀ òfurufú lọ sókè òkun

Ọkọ̀ ofurufu àkọ́kọ́ láti ilẹ̀ òkèrè ball si pápákọ òfurufu ilú Eko lọ́san òní

Oríṣun àwòrán, Others

Bàálù àkọ́kọ́ balẹ̀ si pápákọ̀ òfurufú ìlú Eko lẹ́yìn oṣù márùn gbáko tí ijọba orilẹ̀-èdè Nàìjíríà ti fòfinde ìgbòkègbodo ọkọ̀ òfurufuú ilẹ̀ òkèrè.

Fífòfinde àwọn ọkọ̀ yìí kò ṣẹ̀yìn àjàkálẹ̀ ààrun coronavirus to wọ orílẹ̀ èdè Naijiria nínú oṣù kẹta ọdún 2020.

Ọkọ̀ òfurufu ọhun to gbéra lati Beirut, lebanon balẹ̀ si pápákọ̀ òfurufú Muritala Muhammed International nílùú Eko ni dede aago méjì kọjá ìṣẹ́jú mẹ́tàdínlógún lónìí ọjọ́ sátide.

Bákan náà ni ọkọ̀ òfurufú méjì míràn, Delta àti British Airways náà ṣe e ṣe kó bẹ̀rẹ̀ si ni fò láti pápákọ̀ òfurufú náà lónìí.

Ní ọjọ́ Eti ni àwọn ìkọ ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti sàbẹ̀wò sí pápákọ̀ òfururfú NMIA láti mọ̀ bi wọ́n ṣe múra silẹ̀ fún iṣẹ́ ìgbokègbodò to bẹ̀rl lónìí.

Awọn tó sàbẹ̀wò sibẹ̀ ni ìgbákeji gómìnà ìpińlẹ̀ Eko, Obafemi Hamzat Kọmísọnà ètò ìrìnà ìpińlẹ̀ Eko, Frederic Oladeinde àti kọmísọ́nà ètò ìlera, Akin Abayomi àti àwọn èèkan míràn nípìnlẹ̀ Eko.

Àsìkò tí wan sàbẹ̀wò ní ọ̀ga àgbà FAAN ní pápákọ̀ òfurufú náà sàlàyé pé, ọkọ̀furufú kan láti Middle Belt yoo maa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ fún ìgbà àkakọ́ lónìí..

Sáájú àsikò yìí ni ìjọba àpapọ tí ṣí pápákọ̀ òfurufú fún awọn to n rin ìrìnàjò abẹ́lé ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kèje ọdun yii, to si ti sàlàyé pé, ní òní ọja kàrun, ọsù kẹjọ ni àwọn ilẹ̀ òkèrè yóò bẹ́rẹ̀.

Ẹ̀wẹ̀ àwọn aláṣẹ ti fi ìlàna bi àwọn ọkọ òfúrufú náà yóò ṣe ma rìn láti òní ọjmọ́ Sátidé, ọja karún, oṣù kẹjọ ọdún 2020.

Nínú àtẹjáde kan ti àwọn aláṣẹ ìrìnà ọkọ̀ òfurufú (NCAA) fi sójú òpó twitter rẹ̀, ló ti sàfihan ìlànà ìrìnà tuntun ti wọ́n fẹ́ gùnlé.

Nínú àtẹ̀jáde náà, wọ́n ni ọkọ̀ òfurufú kankan ko le kó ju igba ènìyàn lọ, wọ́n fi ku pé àwọn fọ́wọ́si iye yìí nitori pe ó le ni ènìyàn ẹgbẹ̀run kan to maa n wa si papakọ òfurufú lọ́ọ̀jọ́.

 • Gbogbo arinrinajò to ba n bọ gbọdọ ti ṣe àyẹwò ààrùn Covid-19, ki o si ti mọ pé oun ko ni ààrun náà ko to wá
 • Arìnrinàjo ti gbọdọ ṣe àyẹwò yiì'ó kéré tan ọjọ mẹ́rin ki o to rìnrìn àjò, sùgbọ́n èyí to dára jù ni wákàtí mejìléláàdọ́rin si ìgbà to fẹ́ rìnrìn àjò.
 • Láti àwọn orílède kan, ó ni erejú ilé àyẹwo tí o ni ìtẹ́wọ́ gbà lati mu esi ayẹwo wọn wa.
 • Gbogbo àrìnrìn àjò tó n bọ̀ ni Naijiria gbọdọ̀ forúkọ̀ silẹ̀ nibi https://nitp.ncdc.gov.ng/
 • Arinrin ajò gbọdọ fi esi ayẹwo pé wọ́n ko ni ààrun náà soju opo NCDC
 • Lẹ́yìn ọjọ́ méje ti arìnrinajò náà bá de, yóò lọ tun àyẹwò ọhun ṣe
 • Àyẹwò ara gbigbona náà yoo ma wáye ni àwọn pápákọ̀ òfurufú gbogbo.

Wo àwọn òfin tuntun tíjọba fí síta lórí lílọ ìrìnàjò sílẹ̀ òkèèrè

Oríṣun àwòrán, Ethiopian Airline

Ọ̀la òde yìí ni ìrìnàjò sí ilẹ̀ òkèèrè yóò padà bẹrẹ ní Nàìjíríà

Ijọba apapọ ti kéde ọjọ karun un, oṣu Kẹsan an, ọdún 2020, gẹgẹ bí ọjọ ti irinajo ọkọ ofurufu si ilẹ okeere yoo bẹrẹ pada ni Naijiria.

Ijọba tun kede orukọ Ileeṣẹ ọkọ ofurufu mẹsan an gẹgẹ bi awọn iléeṣẹ́ tó fi ountẹ lu lati maa ko awọn arinrin ajo lọ si oke okun.

Wo àwọn ofin aatẹle ki o to le fo tabi wọle si Naijiria

 • Arinrinajo gbọdọ ni iwe ẹri mo yege n ko ni coronavirus lọwọ
 • Arinrinajo gbọdọ ṣe ayẹwo naa ni ọjọ mẹrin ṣaaju irinajo naa, o kere tan
 • O ni iru awọn ile iṣẹ ayẹwo Covid 19 ti ijọba Naijiria a gba lọwọ awọn arinrinajo lati orilẹ-ede kọọkan.
 • Awọn arinrinajo to m bọ ni Naijiria gbọdọ lọ soju opo lati forukọ silẹ: https://nitp.ncdc.gov.ng/
 • Loju opo yii ni wọn yoo ti fi abajade esi ayẹwo Covid 19 si
 • Lẹyin ọjọ meje lẹyin ti wọn ba wọ Naijiria ni wọn yoo tun ṣe ayẹwo covid 19 miran ni Naijiria nile ayẹwo ti ijọba fi ọwọ si.
 • Loju opo yii naa ni awọn arinrinajo ni oore ọfẹ lati sọrọ lori eto ilera wọn ati ayẹwo ti wọn ṣe
 • Bakan naa ni wọn le sọ ibi ti wọn ti fẹ ṣe ayẹwo ati ibi ti wọn ti fẹ gab esi ayẹwo wọn
 • Nigba gbogbo ni wọn a maa yẹ bi ara wọn ṣe gbona to wo ni papakọ ofurufu

Oríṣun àwòrán, Twitter/British_Airways

Kini ikede ti minista kọkọ ṣe tẹlẹ?

Minisita to n ri si eto irinna ọkọ ofurufu, Hadi Sirika lo kéde bẹẹ nigba ti igbimọ ti ìjọba àpapọ gbe kalẹ lori ọrọ Covid-19 n jabọ ni ilu Abuja.

O ni ko sí aye fun awọn iléeṣẹ́ kan lati bẹrẹ sí ni ko ero ni saa yii.

Lara awọn iléeṣẹ́ tó fòfin de ni saa yii ni Air France, KLM, Etihad, RwandAir, Air Namibia, Royal Air Maroc, Lufthansa ati TAAG Angola Airlines.

Minisita naa ni papakọ ofurufu Muritala Muhammed ti ilu Eko ati Nnamdi Azikiwe ti ilu Abuja yoo di ṣiṣi.

Sirika fi kun un pe ìjọba tun fòfin de Ileeṣẹ ọkọ ofurufu Cabo Verde ati South Africa nitori irinajo ofurufu ko tii bẹrẹ lorilẹ-ede wọn.

Àkọlé fídíò,

Àṣìṣe ọlọ́pàá àti Adájọ́ sọ mí di ẹni tí wọ́n dájọ́ ikú fún, ọpẹ́lọpẹ́ Fayoṣe tí ko buwọlu

Bakan naa ni ijọba tun fi ountẹ lu Middle East Airline, British Airways, Delta, Qatar, Ethiopian Airlines, Emirates Airlines, Air Peace, Virgin Atlantic, Asky Airlines, Africa World Airways, Air Cote-d' Ivoire, Kenya Airways, EgyptAir, Turkish Airlines lati bẹrẹ iṣẹ pada ni Naijiria.

Ṣaaju ni ijọba apapọ fòfin de irinajo si ilẹ okeere nitori arun Covid-19 to n mi gbogbo agbaye titi.

Ìjọba Nàìjíríà ti sún ọjọ́ tí ìrìnàjò bàálù sílẹ̀ òkèèrè yóò bẹ̀rẹ̀ padà síwájú

Ìjọba kéde ọjọ́ míràn fún ìbẹ̀rẹ̀ padà ìrìnàjò bàálù sílẹ̀ òkèèrè

Ijọba orilẹ-ede Naijiria ti sun ọjọ ti irinajo ofufuru silẹ okeere yoo bẹrẹ pada kuro ni ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2020.

Oludari ajọ to n mojuto irinajo ọkọ ofufuru, Nigeria Civil Aviation Authority (NCAA), Captain Musa Nuhu, lo kede eyi lasiko to n jabọ niwaju igbimọ amuṣẹya to n mojuto ọrọ Covid-19 nilu Abuja lọjọbọ.

Nibayii, ọjọ karun-un, oṣu Kẹsan an, ni irinajo baalu silẹ okeere yoo bẹrẹ pada.

Àkọlé fídíò,

Baby abandoned on dunmpsite: Mo ti bímọ mẹ́rin tẹ́lẹ̀ fún bàbá méjì nínú òṣí- Dupe Ogbomos

Musa ṣalaye pe lootọ ni awọn papakọ baalu , ati awọn ileeṣẹ ọkọ ofurufu ti ṣetan fun iṣẹ, ṣugbọn awọn ẹ̀ka miran ti ko nii ṣe pẹlu ọkọ ofurufu lo fa afikun ọsẹ kan.

O fikun ọrọ rẹ pe dandan ni ọjọ karun-un, oṣu Kẹsan ti wọm kede. Ati pe awọn yoo kede ilana tuntun fun irinajo silẹ okeere.

Oṣu Kẹta ni ijọba Naijiria ti fofin de irinajo oju ofurufu, nitori itankalẹ coronavirus.

Ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ìjọba Nàìjíríà ti gbẹsan lára orilẹ-ède mí tó dẹ́yẹsí i

Minisita feto ọkọ ofurufu Naijiria Hadi Sirika lo fi ọrọ yi lelẹ lasiko ti igbimọ to n koju arun Covid-19 n jabọ fawọn akọroyin ni Abuja.

O ni ipinnu Naijiria yi ko ṣẹyin bi awọn orile-ede kan ti ṣe kọdi ọkọ ofurufu lati Naijiria si ilẹ wọn paapa julọ awọn ilẹ to wa ni ajọ Yuroopu (EU)

Ipinnu ṣe fun mi ki n ṣe fun ọ yi ko ṣẹṣẹ maa waye laarin Naijiria ati awọn ilẹ miran.

Lọpọ igba Naijiria a maa fi jẹ ki o ye awọn ilẹ wọnyi pe awọn ko gba gberẹ.

Igba mẹta ọtọọtọ ree ti Naijiria ti fi ilana gbigbẹsan yi ba awọn orile-ede miran ṣe papọ latẹyin wa.

Àkọlé fídíò,

Akomolede ati asa Yoruba: Ẹ wá kọ́ nípa àpòtí ìṣura èdè wa lórí BBC Yorùbá

1) Lasiko Ijọba Ologun Buhari / Idiagbon

Eyi to gbajumọ julọ ninu iṣẹlẹ igbẹsan ti ijọba Naijiria ṣe lo waye ni asiko ologun ni ti Umaru Dikko.

Umaru Dikko wa lara awọn ti ijọba Buhari / Idiagbon ni o lu owo ilu ni ponpo.

Oríṣun àwòrán, Twitter/MMMDProvost2

Umaru Dikko gẹgẹ bi ọrọ naa ti ṣe lọ ṣa lọ si ilẹ Gẹẹsi ṣugbọn ijọba ran awọn ọtẹlẹmuyẹ lati lọ ji gbe pada wa sile.

O ku diẹ ki wọn ri i da pada wa sile ṣugbọn ijọba ilẹ Gẹẹsi ni ki baalu ti wọn fẹ fi ji i gbe ma gbera lẹyin ti wọn ri i nibi ti wọn di i sinu paali papọ mọ ẹru.

Àkọlé fídíò,

Blind DJ: Etu Omotayo kò ríran àmọ́ ó le to irinṣẹ́ eléré pọ̀ láti kọrin láì sí ìrànwọ́

Ọrọ yi bi ọgagun Idiagbon ninu ti o si paṣẹ ki baalu ilẹ Gẹẹsi kan to ti gbera kuro ni Naijiria pada si papakọ ofurufu Murtala Muhammed nilu Eko.

Awọn onwoye ni igbesẹ yi ko ṣẹyin bi awọn ọlọpaa ilẹ Gẹẹsi ti ṣe doola ẹmi Umaru Dikko ti ijọba Naijiria fẹ fipa gbe lati pada wale wa jẹjọ ajẹbanu.

2) Abacha ṣe iyipada opopona lati fi gbẹsan ohun ti Amẹrika ṣe

Lasiko ijọba ologun bakan naa a ri i ka ninu itan pe olori orile-ede nigba naa Ọgagun Sani Abacha ni ki wọn yi orukọ opopona kan niwaju ileeṣẹ orile-ede Amẹrika ni Naijiria pada.

Orukọ tuntun ti wọn yi opopona naa pada si ni ti olori ẹgbẹ Nation of Islam, Louis Farrakhan.

Igbesẹ ko ṣẹyin bi Amẹrika naa ti ṣe fi orukọ Kudirat Abiola iyawo MKO Abiola pori opopona kan ni New York.

Lọdun 1998 ni ijọba Naijiri a gbe igbesẹ yi lati fi han Amẹrika pe awọn naa ko gba gbẹrẹ.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Aisan ọkan ni wọn sọ pe, o pa Ọ̀gágun àgbà Sani Abacha

3) Iṣẹlẹ ifofinde baalu lati ilẹ Yuroopu

Eyi ni iṣẹlẹ to sunmọ ju to ṣẹṣẹ waye lẹyin ti awọn orile-ede Ajọ Yuroopu ka Naijiria kun awọn orile-ede aadọta ti wọn ko faaye gba ki baalu wa lati ilẹ wọn si Yuroopu.

Naijiria wa lara awọn ilẹ ti ọrọ yi kan ti eyi si mu ki ijọba Naijiria tutọ soke foju gba a pe awọn naa ko ni gba ki baalu lati awọn ilẹ Yuroopu yi wọ oju ofurufu Naijiria.

Lọjọbọ ni ijọba orile-ede Naijiria fi ikede sita pe awọn orile-ede to ba gbegi dina irinajo baalu lati Naijiria sọdọ wọn, Naijiria naa ko ni gba ki baalu wọ ilẹ rẹ lati ọdọ wọn.

Oríṣun àwòrán, thecableng

Kini o ti sele sẹyin?

Ìwé èsì àyẹ̀wò arùn Covid-19 lè di kòṣeémàní fáwọn tí o bá fẹ́ rìnrìn àjò sí ilẹ̀ òkèèrè

Ni bayi ti awọn ọmọ Naijiria n reti ilana ti wọn yoo tẹle ti wọn ba fẹ rinrin ajo ọkọ ofurufu lọ silẹ okeere lẹnu ijọba, a ni ki a fi to yin leti ohun ti awọn ileeṣẹ ọkọ ofurufu kan ni ẹ gbọdọ ṣe.

Ninu awọn ilana ti wọn gbe kalẹ leleyi to nii ṣe pẹlu ṣiṣe ayẹwo boya eeyan larun Covid-19.

Esi ayẹwo yi ni ẹnikẹni to ba fẹ rinrin ajo yoo mu wa si papakọ ofurufu ki o to le wọ baalu.

Àkọlé fídíò,

Coronavirus: Ọ̀pọ̀ àwọn arìnrìnàjò wá sí Nàíjíríà ló kọjá àbẹ̀wò tó lágbára

Awọn ileeṣẹ ọkọ ofurufu bi i Etihad Airways ti fi ọrọ yi sita loju opo wọn o to ọjọ mẹta.

Lọdọ ileeṣẹ ọkọ ofurufu Qatar afihan iwe ẹri mo moribọ lọwọ arun Covid 19 jẹ nkan ti eeyan gbọdọ mu wa paapa to ba n bọ lati orile-ede miran bi Turkey to si fẹ wọ Qatar.

Àkọlé fídíò,

Akomolede ati asa Yoruba: Ẹ wá kọ́ nípa àpòtí ìṣura èdè wa lórí BBC Yorùbá

Qatar ti pese aaye ayẹwo ni papakọ ofurufu Hamad International Airport nibi ti wọn yoo ti ṣe ayẹwo yi

Ohun to n kan awọn eeyan lominu bayi ni asiko ti wọn yoo fi ri esi ayẹwo yi gba.

Lọwọ lọwọ ni Naijiria iṣoro nla ni ṣise ayẹwo arun Covid-19 jẹ.

Pupọ awọn eeyan ni ko ribi ṣe ayẹwo yi tawọn to si ti ṣe kii tete ri esi ayẹwo wọn gba

Ìrìnna ọkọ́ òfúrufú s'ílẹ̀ òkèèrè bẹ̀rẹ̀ padà ní Nàìjíríà

Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti kede pe irinna ọkọ ofurufuru si ilẹ okeere yoo bẹrẹ pada ni ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹjọ ọdun 2020.

Minisita feto irinna ofurufu, Hadi Sirika lo fi eyi sita loju opo Twitter rẹ.

O ni igbesẹ yii yoo kọkọ bẹrẹ pẹlu papakọ ofurufu to wa ni ilu Eko ati Abuja.

Bakan naa lo fi kun un pe gbogbo igbesẹ ati ilana to ba yẹ fun idapada irinajo silẹ okeere naa yoo bo si ojutaye laipẹ.