Germany football naked protest: Àwọn olùfẹ̀hónúhàn bọ́ra sí ìhòhò lórí pápá lòdì sí sísọ eré bọ́ọ̀lù di jẹunjẹun

Awọn eeyan naa

Awọn eeyan kan lorilẹ-ede Germany ti lọ sori papa ni ihoho ọmọluabi lọna ati ṣefẹhonuhan lodi si sisọ ere bọọlu di jẹunjẹun.

Ifẹhonuhan naa lo waye nipasẹ ifẹsẹwọnsẹ kan ti ayaworan Gerrit Starczewski gbe kalẹ ni papa iṣere Stimberg ni Ruhr.

Awọn eeyan naa lọ sori papa lai wọ aṣọ kankan, yatọ si ibọsẹ ati bata ti wọn fi n gba bọọlu, bẹẹ ni wọn tun kọ nọmba agbabọọlu si ẹyin wọn.

Starczewski ni igbesẹ naa waye lọna ati fi ẹhonu han lodi si ohun ti wọn sọ ere bọọlu da laye ode oni pẹlu ihoho awọn eeyan naa.

O ni "Ere bọọlu ti da idakuda laye ode oni, idi niyii ti a fi wa ni ihoho."

Àkọlé fídíò,

Blind DJ: Etu Omotayo kò ríran àmọ́ ó le to irinṣẹ́ eléré pọ̀ láti kọrin láì sí ìrànwọ́