Akomolede ati asa Yoruba: Ẹ wá kọ́ nípa àpòtí ìṣura èdè wa lórí BBC Yorùbá

Akomolede ati asa Yoruba: Ẹ wá kọ́ nípa àpòtí ìṣura èdè wa lórí BBC Yorùbá

Ede Yoruba ti fẹ di ajeji laarin awọn ọdọ iwoyi, idi si ree ti BBC Yoruba fi se agbekalẹ eto yii lati maa kọ wa ni ede ati asa Yoruba.

Eto naa, ta pe ni Akọmọlede ati Aṣa Yoruba, lo n waye fun igba akọkọ lonii loju opo ikanni BBC Yoruba, ti yoo si maa kọ wa ni ede ati asa wa, ko maa ba parun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Akori ẹkọ wa fun toni ni Ẹya Litireṣọ ede Yoruba, olukọ wa si ni ọgbẹni Lawanson Olumuyiwa.

Ẹ wa kọ nipa itumọ Litireṣọ, isọri rẹ, abuda rẹ to fi mọ apoti isura ede Yoruba, ẹẹkan lọsẹ si ni eto yii yoo maa gun ori afẹfẹ.