Alaafin Oyo: Àwọn onílù mí ló ń tú àṣírí ìkà èèyàn tó bá wọ ààfin mi- Aláàfin

Alaafin Oyo

Oríṣun àwòrán, Alaafin Oyo

Wo ohun ti Oba Lamidi Adeyemi sọ nipa awọn Oniluu rẹ nigba aye Kabiesi.

Ojọ́ Abameta, ọjọ́ kẹtalelogun, oṣu kẹrin ọdun 2022 ni Oba Atanda Lamidi Adeyemi Keta lọ darapọ mọ́ àwọn Babba Nla rẹ̀.

Alaafin ilu Oyo, Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi kẹta ti sọ pe, awọn onilu ni afin oun lo maa n ta oun lolobo ti ẹni ibi tabi ọdalẹ ba wọle tọ oun.

Alaafin lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle ede Yoruba kan.

O ni "Gbogbo eeyan lo mọ pe aafin yii jẹ ibi aṣa ati iṣe, ti ẹ ba ri ti awọn onilu ba n lu ilu wọn ninu aafin, oriṣiriṣi nnkan ni ilu naa n tumọ si."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kabiesi ni, "Fun apẹrẹ, ti eeyan buburu kan tabi ọdalẹ ba bami lalejo ni aafin mi, awọn onilu yoo fi ilu wọn ki mi nilọ, bo tilẹ jẹ pe ẹni naa ko ni mọ oun ti ilu naa n sọ, ṣugbọn o ye mi."

Ọba Adeyemi ni "Gẹgẹ bi olori gbogbo awọn Ọba ilẹ Yoruba, mo maa sa ipa mi lati gbe ede, aṣa ati iṣe Yoruba leke, nitori o dabi pe o ti n di ohun igbagbe."

Kabiesi tẹsiwaju pe "Ti ẹ ba ṣakiyesi, ẹ o ri pe mi o fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ aṣọ wiwọ, bi a ṣe n ki ni ati ede Yoruba."

Àkọlé fídíò,

Akomolede ati asa Yoruba: Ẹ wá kọ́ nípa àpòtí ìṣura èdè wa lórí BBC Yorùbá

Ọba alaye naa pari ọrọ rẹ pe o yẹ ki awọn ọmọ ilẹ Yoruba ṣe ara wọn ni oṣuṣu ọwọ gẹgẹ bi ọmọ iya kan , ki wọn ma si jẹ ki eto oṣelu oin wọn niya.

Lẹyin naa lo ṣeleri pe oun yoo tẹsiwaju lati maa gbe aṣa ati iṣe Yoruba ga, ko ma ba parun.

Oríṣun àwòrán, Alaafin Oyo