Drums musical instrument: Ka bí o ṣe le mọ èdè Àyàn àti àgbọ́yé ìlù

Awọn onilu Bata

Oríṣun àwòrán, Others

Ilu dabi ipilẹ lara elo orin ni ilẹ Yoruba, Ko si si ẹni to n kọ iyan rẹ kere to ba ti di asiko orin, bakan naa lo lara idi ti awọn eniyan fi maa n fẹran ayẹyẹ to nise pẹlu Yoruba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oniruuru ilu ni a ni ni ilẹ Yoruba ti olukuku si ni isẹ ọtọọtọ ti wọn n ṣe, bi a ṣe ni eyi ti a n lo fun ayẹyẹ bẹni ti orisa wa, bakan naa ni eyi ti a n lo fun ayẹsi ọba laafin.

Awọn ilu Yoruba ilẹ Yoruba:

  • Gangan/Dundu
  • Iya ilu
  • Bata
  • Omele akọ
  • Gbẹdu/Ogido
  • Ashiko
  • Saworoidẹ

Gangan/Dundun:

Oríṣun àwòrán, Others

Gangan lo wọpọ julọ ti Yoruba maa n lo fun ayẹyẹ ọlọkan o jọkan nilẹ Yoruba.

Aaye ọtọ lo wa ninu iṣẹnbaye. Wọn maa n lo lati fi sọrọ ati lati fi sin ẹlomiran jẹ.

Bata:

Oríṣun àwòrán, Others

Ilu pataki miran nilẹ Yoruba tun ni, ilu oloju meji sugbọn ti oju kan a maa tobi ju ekeji lọ, ni ọpọ igba ibi ayẹyẹ orisa ni wọn ti n lo, bi iwuye, ifọbajẹ tabi ajọdun orisa kan.

Won n lo lati ti fi ohun ranṣẹ si ara ilu lasiko ogun, wọn fi n se ayẹsi, wọn si fi n parako ogun.

Ilu yii si ni orisa Sango yan laayo julọ laarin awọn ilu nilẹ Yoruba.

Omele Akọ:

Oríṣun àwòrán, Others

Omele ni a maa n saba pe eleyi, a mọ si ilu ti a n lu si orin sakara, asiko ayẹyẹ igbeyawo, iwuye, ati ajọdun ni a saba maa n lo.

Gbẹdu/Ogido:

Eyi tumọ si ilu to tobi, boya nítorí eti ni ọpọ se maa n pe orin ati ilu to dun ni 'Gbẹdu'.

Ṣugbọn Gbẹdu ni ilẹ Yoruba ti pẹ ti won ti n lo, ọwọja iṣẹ rẹ si ti tan kọja ilẹ Yoruba nikan, lati bi Senturi kẹtadinlogun ni Benin ti mu Gbẹdu gẹgẹ bi ami ọmọ alade.

Oríṣun àwòrán, Others

Wọn maa n lo lasiko ayẹyẹ nla, o si ti gbajumọ laarin awọn ọlaju, kii ṣe ohun elo orin abẹle.

Awọn ọba maa n saba jo si orin ti won ba lu ilu yii si, ẹlomiran ko le ba ọba jo si, o si maa n safihan ami Dansaki nibi kibi to ba ti jẹyọ.

Ashiko:

Oríṣun àwòrán, Others|

Ilu miran to tun wọpọ laarin Yoruba ni Ashiko, asiko ajọdun tabi ayẹyẹ orisa ni wọn n lo ohun naa, ori rẹ a maa tobi nigba ti idi rẹ a se roboto.

Awọ ewurẹ ni wọn maa n lo lati ṣe, ọwọ ni wọn n lo lati lu pẹlu, yatọ si gangan ti wọn lo gọngọ fun.

Saworo Id:

Saworo Idẹ dabi ilu gangan sugbọn, wọn ṣe ni ọṣọ pẹlu awọn agogo keekeeke.

Awọn agogo yii a maa dun bi wọn ba ti n lu ilu naa, yatọ didun ilu agogo eti rẹ naa ni adun lọtọ.

Pẹlu gbogbo alaye yii, o le mọ iru awọn ilu ti Alaafin Oyo, Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi kẹta n sọ nigba ti o fi lede pe, awọn onilu lo maa n tu asiri bi awọn ẹni ibi ba fẹ wọ aafin.

Oríṣun àwòrán, Others

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Alhaji Ayanyemi Atokowagbowonle, tii se gbajumọ onilu Juju ati Sẹkẹrẹ nilu Ibadan, salaye pe kii se gbogbo eniyan lo mọ ede ayan, ẹni to ba mọ nikan lo le ye.

O ni asiko ti oju o la ni awọn ayan maa n fi ilu bu eniyan, sugbọn laye ode oni, ko si ẹni to n se bẹẹ mọ.

Oríṣun àwòrán, Others

Ayanyemi ni orisirisi ilu lo si wa laye ode oni, paapa julọ, ni aafin ọba.

Bakan naa lo fi kun pe, ilu ni wọn maa n fi n ji Kabiyesi lori ibusun lowurọ, ati pe oniruuru iṣẹ ni wọn ṣe laafin.