Ibadan Divorce: Abílékọ Idowu faraya ní kóòtù kọkọ-kọkọ n'Ibadan, Ó ní òun ò leè pín ọkọ òun pẹ̀lú ẹnikẹ́ni

Aworan lọkọlaya to n ja

Oríṣun àwòrán, others

Olukọni kan nilu Ibadan, arabinrin Idowu Oluokun ti rọ ile ẹjọ kọkọ-kọkọ kan ni Mapo nilu Ibadan pe ki wọn tu igbeyawo ọlọdun mẹrindinlogun oun ati ọkọ oun ti orukọ rẹ n jẹ Oyetunji ka dipo ki oun maa pin ọkọ naa pẹlu iyawo keji to fẹ.

Arabinrin Idowu ṣalaye fun ile ẹjọ naa pe ọkọ oun ko ṣe e fi ọkan tan ati wi pe ni kete ti oun bi ọmọ ni ọkọ oun ti sọ fun oun pe oun ti fẹ iyawo keji ti awọn ẹbi rẹ fara mọ julọ nitori pe ọmọ ilu kan naa ni wọn.

"O tun sọ fun mi pe oun yoo maa sun oorun ni ile emi ati iyawo tuntun to fẹ"

Abilekọ Idowu faraya pe: Inu bi mi gidigidi nitori eyi ko si ninu adehun ti a jijọ ṣe, itiju nla leyi mu ba mi ladugbo ati ninu ẹbi."

"Mo si sọ fun Oyetunji pe ko di iyawo rẹ mu ko fi emi silẹ"

O fi kun un pe ọkọ oun ko ṣe ẹtọ gbogbo to yẹ lori ọmọ kan ṣoṣo ti wọn bi fun ara awọn.

Àkọlé fídíò,

Akomolede ati asa Yoruba: Ẹ wá kọ́ nípa àpòtí ìṣura èdè wa lórí BBC Yorùbá

Oyetunji salaye pe: lẹyin ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira to fi ranṣẹ fun owo idanwo aṣekagba girama WAEC rẹ, ko mọ bi ọmọ naa ṣe joko ṣe awọn idanwo gbogbo to ku ati bi o ṣe wọ ile iwe giga fasiti.

Ninu ọrọ tirẹ, Oyetunji ni pe aisi ifẹ, aini igbẹkẹle ati iwa kotọ iyawo oun lo fa ipẹjọ kọkọ-kọkọ naa.

O ni ọdun to kọja loun jawọ ninu fifi owo ranṣẹ fun itọju ọmọ awọn nitori owo kotọ lo maa n fi anfani owo itọju ọmọ ti oun maa n fi ranṣẹ beere fun.