Polio eradication in nigeria: Orísúnmibáre ni àìsàn 'Polio' tó kọlù mí ní kékeré - Fola

Folajogun Akinlami

Oríṣun àwòrán, folajogun akinlami

Oni, ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2020, ni ajọ eto ilera ni agbaye, World Health Organization, kede pe Naijiria ti bọ patapata lọwọ aisan rọmọ lapa-lẹsẹ, polio.

Ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ni aisan naa sọ di arọ ni orilẹ-ede Naijiria, ati kaakiri ilẹ Africa.

BBC ba eeyan meji lara wọn to kagbako aisan yii nigba ti wọn wa ni ọmọde sọrọ lori iriri wsn.

Ọkan lara wọn, Fola sọ pe oun dagba ba ipa aisan naa ninu ayeoun ni.

O sọ pe awọn obi oun sọ fun pe oun ko ju ọmọ ọdun kan lọ nigba ti iṣẹlẹ naa waye.

Oríṣun àwòrán, folajokun akinlami/facebook

"Iya mi sọ fun mi pe laarin oru ọjọ kan ni mo deede bẹrẹ aisan, ti oun si gbe mi lọ sileewosan.

"Ara gbigbona ni nọọsi to wa lẹnu iṣẹ ro pe o n ṣe mi, lo ba fun mi ni abẹrẹ laimọ pe aarun rọmọ lapa, rọmọ lẹsẹ lo wa nidi aisan yẹn (polio) ni.

"Mo gbọ pe abẹrẹ yẹn gan-an lo da gbogbo nkan ru, ti mo fi di ẹni ti ko le rin mọ."

Arabinrin Fola sọ pe oun dupẹ pe ko gba ju ẹsẹ ọtun oun lọ, nitori pe awọn kan wa ti aarun yii rọ lapa, ẹsẹ, to tun sọ wọn di aditi.

Àkọlé fídíò,

LASTMA Yesufa: Àwọn dókítà gbìyànjú lórí ojú mi ṣùgbọ́n...

"Ẹsẹ mi apa ọtun ni mo ti ni ipenija. Awọn dokita tiẹ sọ fun awọn obi mi pe ẹsẹ naa ko nii dagba ju ti ọmọ ọdun kan lọ, to jẹ ọjọ ori mi lasiko to mu mi."

Lori nkan ti aisan naa gba lọwọ rẹ, Arabinrin Fola sọ pe ki oun ṣa dupẹ lọwọ Ọlọrun ti ko fi aaye iyẹn silẹ.

O ni " Mo si dupẹ lọwọ awọn obi mi; mo lọ sileewe, mo ni iwe ẹri to dara, mo niṣẹ gidi lọwọ, mo ti rinrinajo kaakiri agbaye, mo tun n fun awọn eeyan ni nkan ni awujọ.

Koda, emi ni Igbakeji Aarẹ ẹgbẹ Mandela Washington Fellow ni Naijiria, eyi to jẹ pe ileeṣẹ aṣoju America lo n gbọ bukaata wa.

Ipa ti aisan naa yoo ni lori igbeaye ẹni to ba mu da lori awọn obi, awujọ ati ọlaju."

"Mo le sọ pe orisunmibare ni aisan rọpa-rọsẹ jẹ fun mi."

Idi ni pe, ti kii ba ṣe ti aisan yii, mi o ni ronu pe mo fẹ ẹ da ajọ alaanu silẹ. Awọn iriri mi lo sọ mi di alaanu, ati ẹni to n polongo fun awọn to tun ni aisan yii lati ni igboya lati koju gbogbo ipenija wọn.

Àkọlé fídíò,

Wòlíì Kasali sọrọ nípa awuyewuye pé o lè ìyàwó rẹ̀ jáde nílé

Nipasẹ ajọ naa ni mo fi ni anfaani lati ma a rinrinajo kaakiri agbaye.

Lori ọrọ ọkọ nini ọkọ tabi aya, ipenija kekere kọ ni awọn ti aisan yii ba mu ma n ni, paapa awọn obinrin.

Nitori naa, nkan ayọ ni bi ajọ WHO, ṣe kede pe aarun polio ko si ni Naijiria mọ, ati gbogbo Africa. Ọpẹ nla ni, nitori emi ni mo mọ nkan ti oju mi ri, ti eeyan ko le gbadura iru rẹ fun ẹnikẹni.

Iṣẹ kekere kọ ni awọn obi ọmọ ti aisan naa ba mu n ṣe.

Yemisi Adeoye

Ẹlomiran tun ni Arabinrin Yemisi Adeoye, to ti pe ẹni ọdun marundinlaadọta bayii.

O sọ fun BBC Yoruba pe 'measles' ti Yoruba n pe ni tita tabi igbona lo mu oun nigba naa, abajade rẹ ni pe o rọ lẹsẹ.

Àkọlé àwòrán,

Ibi ti nkan de duro lori aarun polia ni ilẹ Africa

"Awọn obi mi sọ fun mi pe lasiko naa, awọn ileewosan gan-an ko mọ nipa itọju rẹ, de bi i pe ti wọn ba fun ọmọ ni abẹrẹ, o npa wọn ni.

Eyi kii jẹ ki awọn eeyan gbe ọmọ lọ si ileewosan.

Àkọlé fídíò,

Ondo disability: Kò sí ẹni tí àkàndá kò lè ya ilé rẹ̀- Ayọdele

"Kii ṣe pe ko si ileewosan, ṣugbọn awọn ara igba naa kii fẹ ẹ gbe ọmọ lọ, nitori igbagbọ pe ọmọ ti wọn ba fun ni abẹrẹ yoo ku. Ewe ati egbo ni wọn gbẹkẹle."

O fi kun ọrọ rẹ pe awọn obi oun tun sọ pe oun o ti i ju ọmọ ọdun marun un nigba naa.

"Lootọ, idile onigbagbọ ni mo ti jade, imọran awọn eeyan lo mu wọn lọ si oriṣiriṣi ibi ti wọn juwe fun wọn. Ṣugbọn wọn sọ fun wọn pe o ti pẹ ju.

Ko si ibi ti wọn o gbe mi de."

O wa sọ pe oun ti gba pe bi Ọlọrun ṣe fẹ ki ọrọ aye mi ri niyii.

"Mi o ki n wo ibẹ. Mo ma n kuro laarin awọn to ba n fi mi ṣe yẹẹyẹ.

Mo kọṣẹ, mo si n ṣe iṣẹ mi."