Coronavirus in Kenya: Dípò ìlànà ìkẹ́kọ̀ọ́ àkókò abẹ́rẹ́ adìẹ ló wà lójú pátákó ní kíláàsì

Awọn to ni ileẹkọ ti sọ kilaasi di ibi ti wọn ti n sin adiẹ
Àkọlé àwòrán,

Joseph Maina ti yi kilaasi ikẹkọ rẹ pada di ile adiẹ

IIgbesẹ ijọba Kenya to ti awọn ileẹkọ pa di ọdun to n bọ, ti mu ki ọpọ olukọ di alainiṣẹ lọwọ gẹgẹ bi BBC ti ṣe iwadii rẹ.

Iyara ikẹkọ ileewe Mwea Brethren to ṣe pe ariwo awọn akẹkọ lo maa n gbalẹ nibẹ, ti di ibudo ti igbe awọn adìẹ ti gbalẹ kan.

Kaka ki wọn kọ iṣẹ iṣiro (Maths) si oju patako ikọwe, ohun to wa nibẹ ni alaye asiko tawọn adiyẹ yoo gba abẹrẹ ajẹsara.

Joseph Maina to ni ileẹkọ Central Primary School naa ti sọ kilaasi di ibudo ọsin adìẹ, ko ba le ri owo gbọ bukata to wa nilẹ.

'Ọna ọfun lọna ọrun''

Nkan ko rọgbọ fun Jonathan paapa julọ ni oṣu Kẹta ti wọn paṣẹ ki wọn ti awọn ileewe.

Lasiko taa n sọ yìí, o ni owo kan to ya lọwọ ile ifowopamọ, to si ni lati tun ijoko jokoo pẹlu wọn lori bi yoo ṣe da owo wọn pada.

O kọkọ da bii ẹni pe ko si ireti kankan fun ṣugbọn o pada pinu pe oun gbọdọ wa nkan ṣe pẹlu ileewe to wa nilẹ la ṣe nkankan.

Àkọlé àwòrán,

Niṣe ni wọn sun aga ati tabili ijoko sẹgbẹ kan lati le gba nkan ọgbin

Nitori pe awọn ileewe aladani a maa fi owo tawọn obi ba san lati fi san owo oṣu olukọ wọn, bi wọn ṣe ti awọn ileewe pa ṣe akoba fawọn to da iru ileewe bẹ silẹ.

Gẹgẹ bi ẹgbẹ awọn ile ẹkọ aladani ni Kenya ti ṣe sọ, diẹ ninu awọn ileewe aladani lo n gbiyanju lati maa kọ awọn akẹkọ loju ayelujara ṣugbọn owo ti wọn n ri nibẹ ko to lati san owo oṣu awọn oṣiṣẹ.

Nkan bi ida marundinlogorun awọn olukọ bii egberun lọ́nà oodunrun to n ṣiṣẹ pẹlu ileewe aladani ni wọn ti ni ki wọn lọ isinmi nile lai gba owo oṣu.

Peter Ndoro to jẹ alakoso ẹgbẹ yii fikun pe, ileewe metalelaadoje ni wọn sọ agadagodo si, ti wọn ko si mọ igba ti wọn yoo ṣi wọn pada.

'Ko buru to bayi ri'

Ki ọrọ baa ma di pe awọn naa yoo ti ileewe wọn pa, ileẹkọ Roka Preparatory ti tete yi ọgba wọn naa si oko.

James Kung'u to da ileewe naa silẹ ni ọdun mẹtalelogun sẹyin sọ fun BBC pe ''Nkan ko buru to bayi ri fun wa''

Ni ọgbà iṣere awọn akẹkọ ewebẹ ni wọn gbin sibẹ bayi.

O tun n sin adiyẹ nibẹ naa.

''Ọrọ mi ko yatọ si ti ọpọ awọn ileewe mii.Tipa ni mo fi n ri epo ra si ọkọ mi.

Awọn olukọ ati akẹkọ ko si nibi mọ. Ki ni naa ba wa gidi gan''

Oṣiṣẹ meji pere ni Mwea Brethren ati Roka gba ṣiṣẹ ti wọn n ran wọn lọwọ pẹlu iṣẹ oko wọn.

Ogbẹni Kung'u ni ''Ki ṣe lati ko ọrọ jọ. Ara ko ni wa pupọ bẹẹ si ni airikanṣe ko ba wa. O jẹ bi ọna lati ṣe itọju ọkan wa''

Ko si ọna iṣẹ fawọn olukọ

Bo tilẹ̀ jẹ pe awọn ileewe meji yii ti ri ọna gbe gba, awọn to ni ileewe naa ni àwọn n jaya lori awọn olukọ ti ko ri owo oṣu gba lati nkan bi oṣu marun un sẹyin.

Ṣugbọn ọrọ ko ri bẹ pẹlu awọn olukọ ileẹkọ ijọba tawọn n ri owo oṣu gba deede.

Ọgbẹni Maina sọ pe awọn olukọ ileewe oun kan ti pe lati beere pe ṣe awọn le ri nkankan ṣe ''O bami lọkan jẹ nitori awa naa n tiraka lati jẹun ni''

Nitori eyi, pupọ awọn olukọ lo ti n wa ọna ijẹ mii.

Baba onile ti le Macrine Otieno to jẹ olukọ fọdun mẹfa ni olu ilu Nairobi kuro nile to n gbe nitori ko ri owo ile san.

O sọ fun BBC pe ''Lati igba ti ajakalẹ yii ti bẹrẹ, ti wọn si ti ti ileewe wa pa, mi o ri iṣẹ kankan ṣe''

'Mo n tiraka lati ma ṣe awọn iṣẹ mii ṣugbọn ko rọrun fun mi.''

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: