NUJ ìpínlẹ Oyo bà àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tó lọ ìpàdé tí Femi Fani Kayode pè ní Ibadan wí

Oríṣun àwòrán, others
Ẹgbẹ awọn akọroyin Naijiria, ẹka ipinlẹ Oyo ti pe awọn ọmọ ẹgbẹ to lọ sibi ipade ti Femi Fani Kayọde pe ni ilu Ibadan lati wa wi tẹnuwọn niwaju igbimọ to n ba ni wi ninu ẹgbẹ naa.
Iwaju igbimọ olubaniwi yii ni awọn ọmọ ẹgbẹ naa ti ni anfani lati wa sọ iha ti wọn lori ohun to ṣẹlẹ.
Alaga ẹgbẹ naa, Ogbeni Ademola Babalola ṣapejuwe iṣẹlẹ naa pe ko dara to.
Saaju ni wọn ti ni pe ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ ma lọ sibi ipade naa ti Femi Fani Kayode pe latari bo ṣe ṣe si akọroyin Daily Trust ni ipinlẹCross River.
Ademola ni o yanilẹnu pe lẹyin aṣẹ ẹgbẹ yii ni awọn akọroyin miran gbẹyin lọ sibi ipade Femi Fani Kayode naa.
Temitope Akinnusi: Ọ̀pọ̀ iléeṣẹ́ ló takú láti gbà mí síṣẹ́ torí mo ní ojú kan
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Fani Kayode ti ní kí iléeṣẹ́ Daily Trust san 6 bilion Naira nítorí ọ̀rọ̀ kùbákùngbé tí wọ́n sọ sí i
Oríṣun àwòrán, Others
Minisita fun ọrọ irinna ọkọ ofurufu tẹlẹri ni Naijiria, Femi Fani-Kayode ti ni oun yoo gbe ileeṣẹ Iroyin Daily Trust lọ si ileẹjọ nitori wọn ba orukọ oun jẹ ninu iroyin ti wọn gbe jade.
Ija to waye laarin Femi Fani-Kayode ati ileeṣẹ iroyin Daily Trust ko ṣẹyin bi Fani-Kayode ṣe sọ ọrọ odi si akọroyin wọn lasiko ti Fani-Kayode n ba awọn akọroyin sọrọ ni Calabar, ni ipinlẹ Cross River.
Lasiko ti Fani Kayode n ba awọn akọroyin naa sọrọ lori iṣẹ ti gomina ipinlẹ Cross River n ṣe ni akọroyin naa bere lọwọ Fani Kayode wi pe tani o ran an niṣe to n ṣe.
- Sinimá àwòdamiẹnu, Ẹ̀fáńjẹ́líìsì jìyà àjẹmumi nílé aṣẹ́wó l'Ejigbo ní ìlú Eko
- Ìjàmbá ọkọ̀ tó ṣẹlẹ̀ sí Adams Oshiomole kìí ṣe ojú lásan, àwọn kan ló fẹ́ pa á- APC
- Ọba Saudi Arabia yọ ọmọ rẹ̀ àti àbúrò rẹ̀ kúrò nípò nítorí ìwà àjẹbánu lórí owó tó yẹ fún ààbò ìlú
- Èèyàn 239 míràn ṣẹ̀ṣẹ̀ kó COVID-19 ní Nàìjíríà
Ibeere yii mu ki Fani Kayode gbana jẹ, to si bẹrẹ si ni sọrọ kubakungbe si akọroyin ileeṣẹ Daily Trust to bere ibeere naa lọwọ rẹ.
Lẹyin iṣẹlẹ yii ni ileeṣẹ iroyin Daily Trust gbe iroyin kan jade ti wọn pe akọle rẹ ni "FFK, The Drug Addled Thug In Designer Wears" lati jẹ ki awọn eniyan mọ iru eniyan ti Femi Fani Kayode jẹ.
Amọ, Femi Fani Kayode lasiko to n fesi si atẹjade naa sọ wi pe iroyin naa tabuku oun, to si ba oun lorukọ jẹ.
Oríṣun àwòrán, others
Agbẹjọro fun Fani-Kayode kesi ileeṣẹ iroyin naa lati gbẹsẹle iroyin naa laarin ọjọ mẹ̀rinla,, ki wọn si san owo gba ma binu biliọnu mẹfa naira.
- Àwọn ará ìlú Ikarẹ Akoko ń ṣọ̀fọ̀ Ọba Adegbite, Ọwá Ale Ikarẹ tó wàjà
- Gbajúgbajà òṣèré “Blue film'' wọ gàù ẹ̀sùn fífipá bá obìrin 13 lòpọ̀
- Ẹgbẹ́ wa ò dàrú o! Kódà gbọingbọin la wà lẹ́yìn Akintoye gẹ́gẹ́ bíi adarí YWC nílé, lẹ́yìn odi
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Kogi kéde ọjọ́ ìwọlé àwọn akẹ́kọ̀ọ́
- Àṣírí tú! Wo àwọn tó ń jí owó Covid-19 tí Ìjọba ní wọ́n yóò káwọ́ pọ̀nyìn rojọ́
Agbẹjọrọ naa ni ti ileeṣẹ iroyin Daily Trust ko ba ṣe ifẹ awọn, awọn yoo gbe wọn lọ si ileẹjọ.
Laipẹ yii ni Femi Fani Kayode tọrọ aforijin lọwọ akọroyin ileeṣẹ Daily Trust ti o sọrọ kubakugbe si naa.
Bolaji Faleke ni Olùkọ́ tó ń kọ́ wa ní àṣà oge ṣiṣe lórí BBC Yorùbá
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin lori ọrọ yii:
Máa gbé kẹ̀kẹ́ rẹ lọ, àwọn akọròyìn kọ̀ ìpàkọ́ sí Femi Fani Kayọde
Awọn akọroyin ni ipinlẹ Ọyọ naa ti kọ ipakọ si ipade awọn akọroyin ti minisita tẹlẹ lorilẹ-ede Naijiria, Fẹmi Fani Kayọde nilu Ibadan.
Awọn to ṣe eto ipade oniroyin naa ti kọkọ rii daju pe iwọnba aṣayan awọn akọroyin ni wọn pe, wọn si fi kun un pe iwọnba awọn ti wọn fi iwe pe nikan lo yọju nibẹ.
Lẹyin o rẹyin, atawọn ti wọn fi iwe pe, atawọn ti wọn ko fi iwe pe lo kọ lati yọju sibi ipade naa.
Oríṣun àwòrán, Others
- Iléẹjọ gíga jùlọ da ẹjọ́ SDP àti PDP nù, wọ́n ní Yahaya Bello ló wọlé ìbò gómìnà Kogi
- Ààrẹ Buhari buwọ́lu gbígbé ìṣàkoso nọ́mbà ìdánimọ̀ (NIMC) lọ sí ẹ̀ka ìjọba tó ń rí sí ìbáraẹnisọ̀rọ̀
- Ìjà d'ópin, fún ìgbà àkọ́kọ́, bàálù gbéra láti Israel lọ sí UAE
- Yàtọ̀ sí Eko, wo ohun t'áwọn ìpínlẹ̀ meje míràn ń sọ nípa ìwọlé àwọn akẹ́kọ̀ọ́
- Ọba ni mí, mi ò le b'ọ̀rìṣà, Olorì tuntun tó ń bọ̀ já gbogbo ''scale''- Oluwo ti Iwo
Alaga NUJ ni ipinlẹ Oyo, Demola Babalola naa fidi ẹ mulẹ pe awọn pinnu lati ma bu ọla fun iwe ipe ti FFK ti kọkọ fi ranṣẹ si ẹgbẹ wọn
Eyi ko ṣẹyin bi awọn alaṣẹ ẹgbẹ akọroyin ti ṣe paṣẹ fawọn akọroyin pe ko si ẹnikẹni ninu wọn to gbọdọ de ibi idibo naa.
Igbesẹ yii n waye loriọrọ kobakungbe ti Fani Kayọde sọ si akọroyin ileeṣẹ iroyin Daily Trust ni ilu Calabar, ni ipinlẹ Cross Rivers.
Ṣaaju igbesẹ yii naa ni ẹgbẹ akọroyin ni ipinlẹ Akwa Ibom naa ti gbe igbesẹ yii.
Wo bí Sunday Orimola ṣe gba ikú ẹranko kú ní Ifon ni Ondo lórí ọ̀nà àtijẹ
Kìí ṣe torí ìbèérè ni mo ṣe bẹ́ Fani-Kayode, àwọn akẹẹgbẹ́ mi ló kó mi láyà jẹ - Eyo Charles
Akọroyin iwe iroyin Daily Trust, Eyo Charles, ti Femi Fani-Kayode, sọ ọrọ kobakungbe si sọ pe oun ti dariji i.
Eyo sọ eyi ninu ọrọ kan to ba BBC sọ pe ni kete ti iṣẹlẹ naa waye ni oun ti gba fun Ọlọrun.
Ọjọ Iṣẹgun ni iṣẹlẹ naa waye nibi ipade oniroyin kan ti Fani-Kayode, ti n ba awọn akọroyin sọrọ nilu Calabar, lori irinke-rindo rẹ ni awọn ipinlẹ to wa ni Gusu-Gusu Naijiria.
FFKVS JORNO:Mi o kabamọ ibeere ti mo beere lọwọ FFK
Lasiko ipade naa ni Ọgbẹni Eyo Charles ti beere lọwọ minisita tẹlẹ ri ọhun pe "ta alo n gbọ bukaata irinkiri rẹ".
Ibeere naa bi Fani-Kayode ninu, eyi to mu ko pe akọroyin naa ni "ọdẹ''. To si sọ fun un pe ko ye e beere iru nkan bẹ ẹ mọ.
"Tẹ ẹ ba gbagbe, mo sọ ninu fidio to lọ kaakiri ayelujara pe, Olori Alufaa, ati Biṣọpu ni mi ninu ijọ Brotherhood of the Cross and Star , nitori naa ni mo ṣe fa gbogbo nkan le Ọlọrun lọwọ."
'Oyenusi ló mú mi wọ ẹgbẹ́ adigunjalè kó tó di pé mo b'Ólúwa pàdé'
Kini idi ti Eyo Charles fi bẹ Fani-Kayode ninu fidio naa?
Ọgbẹni Eyo ṣalaye pe kii ṣe nitori ibeere to bi Fani-Kayode ninu ni oun ṣe bẹbẹ.
- Báwo ni obìnrin ṣe ń ní ìtura ìbálòpọ̀? Wo àbọ̀ tí ọmọba kan, obìnrin àkọ́kọ́ tó ṣe ìwádìí nípa rẹ̀ gbé jáde
- Ọlọ́pàá Funso ló fi ààyè sílẹ̀ fún mi láti sá kúrò ní àgọ́ ọlọ́pàá tó wà ní Mokola - Sunday Shodipe
- Aráyé ẹ gbà mí, nǹkan ń ṣe mí, èyí tó ju àìsàn lọ - Kanran
- Àwọn òṣèré Nollywood tí wọn ò sí lóri amóhùmáwòrán mọ́
O ni "Mo sọ pe ki o ma binu nitori bi awọn akẹẹgbẹ mi kan ti a jọ wa nibi ipade oniroyin naa ṣe n ba mi wi loju ẹsẹ pe n ko ba ma ti beere ibeere naa. Eyi mu ki ara mi gbọn jinnijinni, ti mi o si mọ nkan ti mo n ṣe mọ.
Mi o reti iru ọrọ lile to jade lẹnu minisita , pẹlu nkan ti awọn akẹẹgbẹ mi sọ.
"Gbogbo ẹ ba mi ni ojiji, eyi si mu ki n ro pe ọrọ abuku ni mo sọ ni, lo jẹ ki n bẹ ẹ pe ko ma binu.
- Ta ni ìyàwó Chadwick Boseman, tó jẹ́ àwòkọ́ṣe rere f'áwọn ọ̀dọ́ Adúláwọ̀?
- Ìjọba Ghana ṣí iléeṣẹ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà padà. Ó fún Nàìjíríà l'èsì àwọn ẹ̀sùn tó fi kàn-án
- Ìdí tí mo fi ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí 35 lọ́dọọdún rèé- Allwell Ademola
- Wo ojú Akeem t'Ọlọ́pàá mú pé ó fipá bá ọ̀dọ́mọbìnrin kan sùn létí odò l'Oṣun
- Iléẹjọ gíga jùlọ da ẹjọ́ SDP àti PDP nù, wọ́n ní Yahaya Bello ló wọlé ìbò gómìnà Kogi
Ibeere wo gan-an lo fa ibinu yọ lapo Fani-Kayode?
Ọgbẹni Eyo sọ pe Minisita ti kọkọ sọ pe oun ti lọ si ipinlẹ bi mẹfa tẹlẹ, lati wo awọn iṣẹ akanṣe ti awọn gomina naa n se.
Eyi lo si mu ki oun beere pe ta a lo n gbọ bukaata irinajo naa.
Mo ni "Sir, botilẹ jẹ pe ẹ ko sọ fun wa ẹni to n gbọ bukaata yin, ko jẹ ki n pari ibeere mi, to fi han mi pọnkan."
Fani-Kayode ko ọrọ rẹ jẹ
Minisita Naijiria nigba kan ri, Femi Fani-Kayode ni oun ko ọrọ pe akọroyin Daily Trust jẹ.
O ni lẹyin ijiroro pẹlu awọn olugbani nimọran oun, oun ti ko gbogob ọrọ ti oun sọ si akọroyin naa nilu Calabar jẹ.
"Mo ni ọpọ awọn ọrẹ to pọ ninu iṣẹ iroyin, ti mo si ti ṣẹ wọn nipa ihuwasi mi nipa lilo awọn ọrọ ti ko ṣe e gbọ seti naa.
"Mi o ni ṣe ohunkohun ti yoo pa oniroyin lara, nitori pe mo ti ja fun awọn oniroyin ni ọpọ igba.
"Mo ni igbagbọ pe, eyi yoo rọ ọpọ to ti n binu nitori nkan to ṣẹlẹ naa, lọkan.
" Mo ti fi ṣe afisẹyin, ti eegun n fi aṣọ, mo si ti tẹsiwaju."
Ṣe Eyo Charles ti dariji Fani-Kayode?
Ni bayii ti Fani-Kayode ti sọ pe oun ko ọrọ ti oun sọ si akọroyin naa jẹ, Eyo sọ pe bo tilẹ jẹ pe ko ti i pe oun gan-an lati tọrọ aforiji, "nitori pe emi lo sọ ọrọ kọrọ si, ṣugbọn nitori ipo mi gẹgẹ bi biṣọpu, mo ti dariji."
"Mo reti pe ko bẹ mi, nitori pe mi o sọ ọrọ kọrọ si, ibeere naa jẹ dandan. Mo n ṣe iṣẹ mi gẹgẹ bi akọroyin ni.
Kini Fani-Kayode sọ ṣaaju ko to o pada bẹbẹ?
Akọroyin naa sọ fun BBC Yoruba pe ibéèrè òun ko ju pe gbogbo irinajo to n rin lọ si iha Guusu, taa gan lo n ṣe onigbọwọ rẹ tabi gbowoo lẹ.
Ẹwẹ, Fani Kayode ni kii ṣe ibeere rara lo bi oun bi kii ṣe ọrọ lasan to si jẹ eebu.
"To ba si wa sọ iru ọ̀rọ̀ eebu yii niwaju aarẹ Trump tabi OBJ, mo mọ iru esi ti wọn yoo fun un".
Kayode ni oun o kabamọ rara pe oun da akọroyin naa lohun bi oun ṣe sọrọ.
O ni arakunrin naa ni ki oun ma binu lasiko ipade oniroyin ọhun o si tun fi ọrọ ẹbẹ rẹ ranṣẹ lẹyin ipade kan naa mo si ti gba ẹbẹ rẹ pẹlu ọkan kan a si ti n ba igbesi aye lọ pada.
Fani Kayode ni ifura pe awọn ọlọtẹ ọta oun ninu oṣelu lo lee ṣe agbatẹru iru ibeere yii ti wn si fẹ lo arakunrin naa lati doju ti oun ati lati ba daadaa oun jẹ.
Ṣugbọn o ni "wọn ri gba ju oun ti wọn gbe wa lọ".
O ni "mo tun un sọ pe ọrọ eebu gbaa ni eleyii, mi o si le gba iru ẹ latọdọ ẹda kankan taa bi ninu obinrin".
BBC Yoruba ba akọroyin naa, Charles Eyo sọrọ
Akọroyin ileeṣẹ iroyin Daily Trust Eyo Charles ti ba BBC Yoruba sọrọ lori ohun to waye laarin rẹ pẹlu Minisita Naijiria tẹlẹ, Femi Fani Kayode.
Ko ṣẹyin fọnran fidio ti Fani Kayode ti n bu pe ko yẹ ki o beere ibere agọ lọwọ ohun ṣe lawọn eeyan bẹnu atẹ lu Fani Kayode pe ko yẹ ko bu akọroyin naa to bẹ.
Ninu ọrọ ti Eyo Charles sọ, o ni ohun kan ṣoṣo ti oun kabamọ ni pe oun tọrọ aforiji lọwọ rẹ lori gbolohun ti oun lo.
''Mo bere lọwọ Minisita tẹlẹri ọhun pe ta ni ni to san owo abẹwo rẹ si awn ipinlẹ ti o n ṣe abẹwo si kaakiri Naijiria.Iyẹn awọn ipinlẹ meje to ni oun lọ''
Ibeere mi ko ju bayi lọ ti Minisita si gbanajẹ to bẹrẹ si ni mu mi bu.
Ipade awọn akọroyin to waye ni nkan bi ago mẹwa owuro lỌjọbọ ni ile itura Gomina Ben Ayade ni Cross River ni iṣẹlẹ naa ti waye.
Ki ni ileeṣẹ iroyin Daily Trust sọ
Akọroyin naa sọ pe Fani Kayode mu ileri rẹ ṣẹ ti o si pe awọn ọga ohun nileeṣẹ iroyin rẹ.
World Press Day: Ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn jàǹdùkú ká mi mọ́lé nítórí ìròyìn tí mo kà
O ni lẹyin toun ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fun ọga oun, wọn ni ki oun ma foya ti wọn ko si kọkọ gbe iroyin iṣẹlẹ naa sita.
Charles sọ pe lẹyin ti ariwo pọ loju opo ayelujara awọn olootu iwe iroyin naa ṣẹṣẹ wa kọ iroyin nipa iṣẹlẹ naa ṣugbọn wọn ko ni i ki Fani Kayode tọrọ aforinjin lọdọ akọroyin wọn.