DSTV Price Hike: Ọmọ Nàìjíríà faraya lórí èlé owó DSTV tó ń wáyé ní ẹ̀ẹ̀kan lóṣù mẹ́rin

DSTV

Oríṣun àwòrán, others

Ileesẹ Multichoice tun ti kede pe, oun yoo tun ṣe afikun owo tawọn ọmọ Naijiria n san fun oju opo iworan DSTV ati GOTV.

Ọjọ kinni osu kesan ọdun 2020 si ni ele owo naa yoo bẹrẹ, eyi tii ṣe afikun ẹẹkeji laarin oṣù mẹrin pere.

Gẹgẹ bi ele owo oju iworan DSTV ati GOTV tuntun yoo ṣe lọ, DSTV Premium yoo kuro ni náírà merindinlogun ati igba (N16,200) bọ si naira mejidinlogun o le irinwo naira (N18, 400) ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ninu alaye to ṣe nipa afikun owo naa, Ileesẹ Multichoice ni owo ọjà to gbowo lori, owo ori ọjà, ati agbara owo naira to dinku lo fa a.

Amọ ikede Ileesẹ Multichoice yii ti bọ sapo ibinu awọn ọmọ Naijiria lori ayelujara ati loju popo.

Ọpọ awọn ọmọ Naijiria si lo n koro oju si ijọba apapọ pe o gba Ileesẹ South Africa laaye, lati maa yan wọn jẹ nilẹ baba awọn.

Ọpọ awọn eniyan naa lo ni lai naani ìnira ti arun Coronavirus ko ba ọrọ aje awọn, ati iṣẹ pẹlu òsì to gogo si lawujọ wa, sibẹ Ileesẹ DSTV si tun n fara ni awọn.

Bákan naa ni wọn tun kesi ile asofin apapọ lati dìde si ọrọ naa, ko to bọ̀wọ sori.

Wọn ni awọn n fẹ ki ìjọba atawon asofin lati pasẹ fun Ileesẹ Multichoice pe iye akoko ti onibara ba fi wo oju opo wọn, ni ko maa sanwo rẹ, eyi ti wọn pe ni Pay As You Go.

Àkọlé fídíò,

'Ní ìjọ wa, ọtí mímú la fi ń pe ẹ̀mí Ọlọ́run sọ̀kalẹ̀'