Gani Adams: Àwọn agbébọn ń jí ọmọdé, àwọn obìnrin, ti wọn sì ń dúnkookò mọ ọrọ̀ aje Oke Ogun

Oríṣun àwòrán, @OnwardNG
Yoruba ni agbalagba to n lu irin loju kan ṣoṣo, o ni ohun to fẹ gba lọwọ irin ni.
Fun igba keji laarin osu kan, Aarẹ Ọna Kakanfo nilẹ Yoruba, Iba Gani Adams tun ti n ke tantan pe awọn agbébọn ti farasin siluu Kishi, lagbegbe Oke Ogun.
O fikun pe bakan naa lawọn agbébọn ọhun tun tẹdo sinu igbo igbafẹ Old Oyo National Park lagbegbe Oke Ogun yii kan naa.
- Adunni Oluwole, akọni obìnrin tó tako òmìnira Nàìjíríà, ó ní òyìnbó kò gbọ́dọ̀ lọ
- Ìròyìn ayọ̀! Bunkunmi Oluwasina ṣe ìgbèyàwó, ẹ̀yin bẹ́lẹ́jayán ẹ lọ sẹ́mpẹ́
- Ọpọ̀ ọkọ̀ bàjẹ́ nígbà tí alátìlẹ́yìn PDP àti APC kọlù àrà wọ́n l'Ondo
- Àwòrán òkú ọmọ mi ni mo kọ́kọ́ rí lójú òpó ayelujara - Bàbá ọmọ tí SARS lé dójú ikú
- Ọdún méjì, wàhálà méjì lójúbọ Osun Osogbo,
Atẹjade kan ti Kehinde Aderemi, tii ṣe akọwe feto iroyin Gani Adams fisita L'ọjọru lo sísọ loju ọrọ yii.
Gani Adams ni ojuse oun ni lati lọgun faraye nipa awọn ọṣẹ táwọn agbébọn naa n ṣe nilu Kishi ati lagbegbe Oke Ogun lapapọ.
O fikun pe awọn iṣẹlẹ to n waye lagbegbe naa lẹ́nu lọọlọọ yii, jẹ ewu nla feto aabo ilẹ Yoruba lapapọ.
Oríṣun àwòrán, others
"Awọn agbébọn yii n ji eeyan gbe, paapaa awọn ọmọde ati obinrin, ti wọn si n fi tipa ba wọn lopọ.
Eti mi ti kun nipa ọpọ iwa aidaa awọn agbébọn naa ti wọn farasin si agbegbe Oke Ogun ati bi wọn ṣe n dunkooko mọ eto aabo ilẹ Yoruba lapapọ.
Aarẹ Ọna Kakanfo wa n kọminu pe ilẹ Yoruba ti n di ibudo fáwọn afẹjẹwẹ ati adunkooko mọni, to n dibọn bii darandaran.
Atunto Naijiria la n fẹ - Aarẹ Onakakanfo, Gani Adams
Adams wa n kede pe yoo dara kijọba tete wa egbo dẹkun fáwọn eeyan naa ko to pẹ ju, ki eto aabo nilẹ Yoruba ma baa mẹhẹ bii ti Oke Ọya.O wa fikun pe táwọn agbofinro ba gba oun laaye, oun yoo ṣe koriya fáwọn eeyan ti eto aabo gberu labẹle bii awọn ọmọ ẹgbẹ OPC, fijilante, ọdẹ ibilẹ, awọn ọdọ ati Agbekoya.Adams ni pẹlu atilẹyin awọn eniyan naa, yoo rọrun lati le awọn agbebọn ọhun kuro lagbegbe Oke Ogun.
Oríṣun àwòrán, Others
Ẹ fura o, Boko Haram ti pàgọ́ sí Abuja, yóò ṣe ìkọlù láìpẹ́ - Iléèṣẹ́ Aṣọ́bodè lọgun
Ilé iṣẹ́ aṣọbode Naijiria (NCS) ti kéde fún àwọn òṣìṣẹ̀ rẹ̀ ní'lú Abuja láti bẹ̀rẹ̀ sí ni fi ojú ṣọ́rí nítorí asiri to tu pe ikọ̀ Boko Haram ti ni ìpagọ́ ni ilú Abuja ati gbogbo agbègbè rẹ̀.
Ìwé ìfilọ kan ti nọ́mba rẹ jẹ NCS/ENF/ABJ/180/S.I/VOL.II, ti ọga agba ilé iṣẹ́ náà fi ọwọ si ni olu ile iṣẹ̀ aṣọ́bodè, ti agbegbe H.A Sabo ni Wuse Zone 3 Abuja, ni asiri ọrọ naa ti tu sita.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Mo gbọ́dọ̀ fún ọ lóyún ká tó kúrò nílé BB Naija - Neo sọ fún Vee
- Tinubu, yé é sọ̀rọ̀ abẹ́lẹ̀, bọ́ sí gbangba láti bèèrè àtúntò Nàíjíríà lọ́dọ̀ Buhari - Afẹnifẹrẹ
- Wo àànfàní ‘Masturbation’, fífún ara rẹ̀ ní adùn ìbálòpọ̀
- Wo àwọn ìlànà tuntun ti o gbọdọ tẹlèé rèé ki ó to le wọkọ̀ òfurufú lọ sókè òkun
- Ìdí ti mo fi da sọ́ọ̀sì rú lásìkò ìgbéyàwó ìyáwó mi tó ló fẹ́ ọkọ míran- Osadebe
Nínú ìwé ìfilọ̀ náà, ti wọ́n pe àkọle rẹ̀ ni "ìwádi abẹ́nú lori ọ̀rọ̀ ààbò ìlú", ileesẹ asọbode ni ìròyìn to ń tẹ̀ òun lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bi ọ̀gá àgba ilé iṣẹ́ yìí fihan pé, àwọn ikọ̀ ọmọ ogun Boko Haram ti wà ní ilu Abuja àti gbogbo agbègbè rẹ̀.
Oríṣun àwòrán, others
Lórí ìwé ìfitóniléti ọ̀hún tó jáde ni ogúnjọ́ oṣù kẹjọ, ọdún 2020, lo ti sọ pé, àwọn ikọ̀ Boko Haram náà ṣètò láti ṣe ìkọ̀lù si àwọn ibì kan nílùú Abuja àti agbàgbè rẹ̀.
Wọ́n ni wọ́n ti ṣetò ibùdó wọ́n sínú igbó Kunyan lópópónà Airport.
Ó fi kun pé, ibùdó míràn tún wà ninú igbó Robochi/Gwagwalada, igbó Kwaku ní Kuje àti igbó Unaisha ní ìjọba ìbílẹ̀ Toto ní ìpińlẹ̀ Nasarawa.
Ẹ̀wẹ́, àgbẹnusọ ilé iṣẹ́ aṣọ́bodè Joseph Attah sọ pé, òun kò mọ ẹni to fún wọ́n ni àwọn aṣírí yìí, sùgbọ́n ìwádìí ń lọ lọ́wọ́.
Oríṣun àwòrán, others
Tí ẹ o bá gbàgbé, irú ìròyìn báyìí náà ti ẹnu olórí ogún nílẹ̀ Yorùbá, Ààrẹ Ọ̀nà Kakanfo, Iba Gani Adams jáde ni ǹkan bi ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́yìn.
- Àwòráń ọdún Ashura àwọn ẹlẹ́sìn Shiite tí ọ̀pọ̀ ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lórí ayélujára
- Risikat olójú búlù dí aya Wasiu ní ìlànà Islam, tẹbí tará péjú síbẹ̀
- Ó ń bọ̀ lọ́nà! Odunlade Adekola, Femi Adebayo, Jenifa ṣi aṣọ lójú àwọn fíìmù tuntun tẹ́ẹ ti ń retí
- Ìdí ti mo fi da sọ́ọ̀sì rú lásìkò ìgbéyàwó ìyáwó mi tó ló fẹ́ ọkọ míran- Osadebe
Gani Adams ni ikọ̀ asẹrubani ISIS ti ni ibùdó si agbègbè Oke Ogun ní ìpińlẹ̀ Oyo, o si yẹ kawọn ọmọ Yoruba fura.
ISIS in Oyo: Ó ń bọ̀ ó ń bọ̀ àwọ̀n làá ń dẹ dè é, ISIS ti wọ ìpińlẹ̀ Oyo o -Gani Adams
Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba Iba Gani Adams ti ke gbàjarè pé awọn ọmọ ẹgbẹ agbesumọmi Islamic State, (IS) wa wọ ipinlẹ Oyo.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú BBC lówùrọ̀ òní sàlàyé pé bi ìgbìmọ̀ ààrẹ kò bá ri kò ni sọ.
Ó ní àwọn gómìnà àti àwọn ọba aláde ilẹ̀ Yorùbá ti sùn àsùn píye ti gbogbo àwọn oríṣirisi ṣì n wọle tọ wọ́n wá.
Gẹ́gẹ́ bi ó ṣe sọ, ó ni ìwádìí ti fi han pé àwọn aggbésùmọ̀mi Islamic State ti wà nínú igbó Lùsádà, ilú yìí ló já si ìgbó ọra eyi ti kò sì ju wákàti méji lọ si ìpínlẹ̀ Sokoto.
"Àrídáju wá, a ri àwọn alùpùpù olówó ńla tó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta tó wọ inú igbó náà, wọ́n di ẹru ìjà olóró àti òunjẹ wọ́n sórí rẹ̀.
Oríṣun àwòrán, Others
O fí kún pé, wọ́n kìí ṣe Boko Haram tàbi Fulani daran-daran ti wọ́n ti mọ̀ tẹ́lẹ̀, "ìmúra wọ́n kò jọ bi àwọn ti a mọ̀ tẹ́lẹ̀"
Wọ́n ti wọ Ibariba nipìnlẹ̀ Niger, wọ́n ti wọ òkè-ògùn., o ní ọ̀pọ̀ wọ́n wọ asọ sọja, ti wọ́n sì n rìn káàkiri inú igbó náà.
Ó rọ ìjọba àpapọ̀ àti àwọn gómìnà ìpínlẹ̀ Yoruba la'ti gbé ìgbẹ́sẹ nítorí ààrẹ ọ̀nà kò lé ṣe ńkan kan ti ìjọba kò bá lọ́wọ́ síí
Iba Gani Adams mẹnu ba ọ̀rọ̀ MURIC ti wọ́n fẹ̀sùn kan pé ó gbowó lọ́wọ́ ISWAP láti gba awọn Fúlani fún ìgbésùmọmi, sùgbọ́n ó ṣeni laáànu pé, ìjọba kọ̀ láti ṣe ìwádìí nípa pípe adari MURIC, ọjọgbọ́n IShiaq Akintola.À kò gba owó kankan lọ́wọ́ àwọn ẹgbẹ́ agbésùmọ̀mí ISWAP- MURIC
Olóyè Gani Adams ni ìlanilọ́yẹ ni àkọ́kọ báyìí láti ṣe fún àwọn ènìyàn àti àwọn lọ́balọ́ba láwọn agbègbè náà.
Oríṣun àwòrán, @OnwardNG
Igbimọ Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba ti sọ pe, awọn ọmọ ẹgbẹ agbesumọmi Islamic State, IS, ti rapala wọ agbegbe Okeogun, ni ipinlẹ Oyo.
Igbimọ naa lo kede bẹẹ ninu atẹjade kan ti Atoloye Aare Ona Kakanfo, oloye Babajide Tanimowo buwọlu
O ni lẹyin ọpọ iwadii ati ifimutolẹ ni Naijiria ati loke okun, igbimọ Aarẹ ọna Kakanfo le e fidi rẹ mulẹ pe, awọn agbesumọmi ati Fulani darandaran ti gunlẹ si agbegbe ọhun.
Atẹjade naa ni "Eyii to kan wa lominu julọ nibẹ ni pe awọn ọmọ ẹgbẹ ISIS ti kora wọn wa si agbegbe Okeogun ni ipinlẹ Oyo."
Baby abandoned on dunmpsite: Mo ti bímọ mẹ́rin tẹ́lẹ̀ fún bàbá méjì nínú òṣí- Dupe Ogbomos
O tẹsiwaju pe alupupu alagbara bii ẹẹdẹgbẹta ati awọn ohun ija oloro to jẹ ti awọn ọmọ ẹgbẹ agbesumọmi naa ni wọn ti foju gaani loju ọna Lusada si Sokoto, eyii to jẹ apa kan ọna to gba Igbo-Ora kọja ni ipinlẹ Oyo.
- "Mi ò kábàámọ̀ pé mo béèrè ìbéèrè tó fàbínú wá lọ́dọ̀ Femi Fani Kayode"
- 'Sanwo-Olu kò ní ṣ'àyẹ̀wò covid-19 míì nítorí kọmíṣọ́nà ètò ìlera ṣẹ̀ṣẹ̀ k'árún náà'
- Ọkọ Funke Akindele kó eléré àti òṣìṣẹ́ jọ fi ṣe "Surprise Pato" fún un lọ́jọ́ ìbí rẹ̀
- John Blake wà ní ICU, ọlọ́pàá tó yìnbọn fún un bẹ̀rẹ̀ ìsinmi tipá tipá
- Ẹ má rán ọmọ lọ ilé ìwé ní Cyprus mọ́ - Abike Dabiri
Igbimọ naa wa rọ awọn gomina iha Ariwa Naijria, pẹlu gomina ipinlẹ Kwara ati Kogi lati kẹkọọ lara gomina ipinlẹ Benue, Samuel Otom, to ni ki awọn eeya ipinlẹ rẹ lọ gba aṣẹ lati ni ibọn fun abo ara wọn.
Bakan naa lo rọ ijọba apapọ lati di ala ilẹ Naijiria ti awọn ọmọ ẹgbẹ agbesumọmi naa atawọn Fulani daran daran n gba wọle lati orilẹ-eded miran.
Bí ẹ ṣe mọ̀wé tó, ẹ wá dánrawò níbí pẹ̀lú "Àpólà Ọ̀rọ̀ Orúkọ - Noun Phrase