Spartan in Ogun: Èèyàn márùn-ún ní ọlọ́pàá sọ pé afurasí náà pa léraléra

Afurasi Feyisola Dosumu

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Afurasi apaayan ati amu oogun oloro to n daomi alaafia ilu Ogere ati Iperu ru ti awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun si ti n wa la gbọ pe wọn ti yinbọn pa bayii.

Ọkunrin naa, Feyisola Dosumu to ti na papa bora fun ọjọ melo kan naa ni wọn ti n wa kiri.

Iroyin taa gbọ ni wipe apapọ ikọ amuṣẹya alaabo ni agbegbe Ogere nipinlẹ naa lọjọ Iṣẹgun ọsẹ.

Ṣaaju, ileesẹ Ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti kede pe ọwọ sinkun oun ti ba afurasi apaayan, ọmọ ẹgbẹ okunkun ati amu oogun oloro ti wọn n wa.

Orukọ afurasi naa ni Feyisola Dosumu, ti ọpọ eeyan mọ si Spartan, deede aago kan ọ̀san si ni ọwọ awọn ọlọpaa tẹ ẹ.

Agbenusọ fun Ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi, ẹni to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ tun fikun pe wọn ti gbe afurasi naa lọ si Olu Ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ naa to wa ni adugbo Eleweran.

O ti to ọjọ mẹta ti iroyin Spartan ti gbalẹ kan pe awọn ọlọpaa n wa nitori pe wọn fura si pe oun lo n gba ẹmi pupọ nilu Iperu ati Ogeere.

Àkọlé fídíò,

Bí ẹ ṣe mọ̀wé tó, ẹ wá dánrawò níbí pẹ̀lú "Àpólà Ọ̀rọ̀ Orúkọ - Noun Phrase

Koda, ọpọ awọn olugbe agbegbe yii ni wọn ti n fi ile wọn silẹ nitori iku ojiji to n pa wọn.

Olugbe kan lagbegbe naa ni lẹyin to ti ran eeyan mẹta sọrun nibẹrẹ ọdun yii, afurasi naa tun pa eeyan meji miran nipari osu keje ọdun yii.

Spartan, to kẹkọ jade nile ẹkọ Gbogbo Nse Poly Moshood Abiola to wa nilu Abeokuta, ni wọn lo jẹ igi wọrọkọ tii da ina ru nilu abinibi rẹ Ogere Remo.

Wọn ní kete to wọ ile ẹkọ Gbogbo Nse tan, lo dara pọ mọ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun, to si tun n mu oogun oloro.

Koda, iroyin naa ni wọn ti gbe afurasi apaayan naa lọ tọju nile iwosan alarun ọpọ to wa ni Aro ri, amọ to sa kuro nibẹ pada silu Ogere, to si n ṣe wọn bi ọsẹ ti n ṣe oju.

Iroyin naa tun fikun pe ṣe ni Dosumu maa n fọnnu kiri pe oun setan lati pa ọpọlọpọ eeyan lagbegbe naa, eyi to n ko ibẹru-bojo ba ọpọ eeyan nibẹ.

Àkọlé fídíò,

'Ìgbà tí mo máa fi lajú sáyé padà, ọ̀fọ̀ ikú mi ní wọ́n ń kígbe'