Lionel Messi: ''Kò sí ohun to lè mú Messi dúró sí Barcelona mọ́''

Lionel Messi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bi gbogbo nnkan ti n lọ yii, afaimọ ki agbaọjẹ agbabọọlu Barcelona, Lionel Messi ma fi ikọ agbabọọlu naa silẹ ni kopẹ kopẹ.

Ileeṣẹ redio kan, Cadena Ser lorilẹede Spain ti sọ pe adehun ọdun meji ni Manchester City fẹ ṣe pẹlu Messi ti wọn ba ti ra a tan lati Barcelona.

Oludari kata-kara awọn agbabọọlu ni Barcelona, Txiki Begiristain ti de si ilu Barcelona lati duna dura lori ati ra Messi lọ si Man City.

Bakan naa ni a gbọ pe baba Messi, Jorge yoo ṣe ipade pẹlu awọn alaṣẹ Barcelona lọsẹ yii lati sọrọ lori bi Messi yoo ti fi ẹgbẹ agbabọọlu silẹ.

Ọpọ lo gbagbọ pe Messi lo le ran Man City lọwọ lati gba ife ẹyẹ UEFA Champions League eyi ti wọn ko tii gba ri ninu itan wọn.

Lionel Messi ati Pep Guardiola

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Messi kọ lati ṣe ayẹwo coronavirus lọsẹ to kọja lẹyin ti Barca ni ki gbogbo agbabọọlu lọ fun ayẹwo ki wọn le bẹrẹ igbaradi fun saa bọọlu tuntun.

Koda akọnimọọgba tuntun Ronald Koeman ti ṣe igbaradi akọkọ pẹlu awọn agbabọọlu Barca ṣugbọn Messi ko si nibẹ.

Ẹwẹ, oludije fun ipo aarẹ ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona, Toni Freixa ti sọ pe ko si ṣiṣe ko si aiṣe, Messi o le duro mọ ni Barca.

Freixa ni ko si iru adehun ti Barcelona le fẹ fun Messi to le mu duro si Barcelona, o ni aṣọ ko ba ọmọyẹ Messi mọ.

Freixa ni ''ọdun 2015 ti Barcelona ti gba ife ẹyẹ Champions League kẹyin, eyi si lo n kọ Messi lominu nitori o tun fẹ gbade Champions League sii.''

Oludije fun ipo aarẹ ẹgbẹ Barcelona sọ pe o ti han gbangba bayii pe Messi fẹ lọ ba akọnimọọgba rẹ tẹlẹ, Pep Guardiola ni Man City.

Níbo ni Messi fẹ́ mórí lé báyìí lẹ́yìn tó jáwée ó tó gẹ́ fún Barcelona?

Ko si ohun to ni ibẹrẹ ti ko l'opin, lo difa fun gudugbẹ to ja lọjọ Iṣẹgun nigba ti iroyin jade pe elegee ara, Lionel Messi ti kọwe si ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona pe oun ṣetan lati dagbere fun ẹgbẹ agbabọọlu naa pe o digba o ṣe.

Ipinnu Messi ko ṣẹyin rukerudo to n ṣẹlẹ lọwọ ni Barcelona papaajulọ lati igba ti Bayern Munich ti lu wọn laluki pẹlu ami ayo mẹjọ si meji ninu idije UEFA Champions League.

Iṣẹ ti bọ lọwọ akọnimọọgba Quique Setien lẹyin abuku nla naa, koda wọn ti le Eric Abidal naa to n ri sí katakara ati pasiparọ awọn agbabọọlu fun Barca lọ.

Lẹyin ti Ronald Koeman di akọnimọọgba tuntun fun Barcelona, ẹgbẹ agbabọọlu naa ti bẹrẹ awọn atunto kan lati tẹ ikọ naa siwaju.

Lionel Messi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lara awọn awọn igbesẹ ọhun ni pe ẹlẹsẹ ayo Luis Suarez at'awọn mii yoo ni lati fi ẹgbẹ agbabọọlu naa silẹ.

Lẹyin naa ni Messi sọ fun Barca pe asiko ti to lati fi ikọ Barca silẹ.

Awọn ẹgbẹ agbabọọlu bii Manchester City, Manchester United, PSG ati Inter Milan lawọn kan n sọ pe o ṣeeṣe ki Messi mori le.

Iroyin kan tiẹ sọ pe Messi ti kan si akọnimọọgba rẹ tẹle, Pep Guardiola to wa ni Man City bayii.

Ohun to wa ninu adehun ti Messi ṣe pẹlu Barca ni pe oun le fi ẹgbẹ agbabọọlu naa silẹ lọfẹẹ, ṣugbọn Barca ni o gbọdọ jẹ ipari oṣu karun ti saa bọọlu yoo pari.

Awọn alaṣẹ Barcelona ni Messi ko le lọ bayii nitori oṣu karun ti kọja, amọ Messi ni ajakalẹ arun coronavirus ni ko jẹki oun sọrọ lati igba yii wa.

Àkọlé fídíò,

'ìjà ṣẹlẹ̀ láàrín èmi àti ọ̀gá mi ní Lebanon tórí mi ò lè dá N300K padà'