Babatunde Olatunji: E wo ọmọ Yorùbá tó kọ́kọ́ jà fún ẹ̀tọ́ àwọn aláwọ̀dúdú ní America!

Babatunde Olatunji

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ilumọọka onilu nilẹ America ati nilẹ Afrika, Babatunde Olatunji ti tako ofin ẹlẹyamẹya ni ọdun mẹta saaju ki Rosa Park to tako ofin ẹlẹyamẹya ninu ọkọ igboro lorilẹ-ede America.

Akọroyin BBC, Aaron Akinyemi ni ọdun mẹta saaju Rosa Park ni Babatunde Olatunji ti bẹrẹ ijijagbara fun ẹtọ awọn ọmọ ilẹ Afrika gẹgẹ bi eniyan bi i alawọfunfun ni ilẹ America.

Ọdun 1950 si ọdun 1960 ni awọn alawọdudu dide lati ja fun ẹtọ wọn gẹgẹ bi i ọmọniyan.

Ọkan lara wọn ni Babatunde Olatunji, eleyii ti Ajafẹtọ ọmọniyan, Opal Tometi to jẹ adari ikọ ''Black Lives Matter'' sọ wi pe wọn jẹ iwuri fun oun ni aye ode oni lati tako ẹlẹyamẹya ati ifiyajẹni nitori awọ ara eniyan.

Babatunde Olatunji fi orin ati ilu ja fun ẹtọ alawọdudu

Ọlatunji wa nibẹ pẹlu awọn gbajugbaja ajafẹtọ to jẹ ilumọọka bii James Baldin, Harry Belafonte ni ọdun mẹtadinlọgọta sẹyin nigba ti Martin Luther King Jr sọ ọrọ akinkanju lasiko ifẹhọnuhan to waye nigba naa lati fopin si idẹyẹsini nitori ẹya lorilẹede America.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Babatunde Olatunji pẹlu Martin Luther King (L) ati Malcolm X (R) ni 1964

Ọdun 1927 ni wọn bi Olatunji to jẹ ọmọ Yoruba nipinlẹ Eko, ko to di wi pe Olatunji gba ami ẹyẹ lati lo kawe ọfẹ ni oke okun ni ''Morehouse College'' ni Atlanta, lorilẹede America ni ọdun 1950.

Olatunji da ilumọọka lẹyin to ṣe awo orin mẹtadinlogun pẹlu awo orin to kọkọ ṣe lọdun 1959, eyi to pe akọle rẹ ni "Drums of Passion".

Wọn gbe oriyin fun Olatunji pe orin rẹ ṣe igbalarugẹ asa ati orin ilẹ Afrika, eleyii to gbe awo orin naa wa si gbagede lagbaye.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Babatunde Olatunji ati Malcolm X ni Nigeria ni 1960

Bawo lo ṣe bẹrẹ?

Ọdun 1952 ni Olatunji bẹrẹ ifẹhọnuhan tirẹ ni awọn ọkọ igboro ni Guusu ilẹ Amerika.

Lasiko ti Olatunji wa ni ileese Morehouse, ọpọlọpọ nkan to buru jai lo waye nigba naa ti awọn alawọfunfun ṣe si awọn alawodudu nitori ofin ẹlẹyamẹya.

Àkọlé fídíò,

Baby abandoned on dunmpsite: Mo ti bímọ mẹ́rin tẹ́lẹ̀ fún bàbá méjì nínú òṣí- Dupe Ogbomos

Bakan naa ni Olatunji to ma n kọrin ilẹ Afrika ni Amerika ni awọn ile ijọsin ati fasiti ni awọn agbẹgbẹ ilu Atlanta, ni ilẹ Amẹrika.

Ni ọdun 1952 ni Olatunji bẹrẹ ifẹhọnuhan tirẹ ni awọn ọkọ igboro ni Guusu agbegbe naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Olatunji ati awọn ọrẹ rẹ tilẹ ma n wọ aṣọ alaranbara ilẹ Yoruba lati wọ awọn ọkọ igboro naa.

Bakan naa ni wọn ma n ṣe ifẹhọnuhan tako ofin ''Jim Crow'' ni Guusu ilẹ Amẹrika.

Oríṣun àwòrán, Olatunji family

Àkọlé àwòrán,

Babatunde Olatunji fẹ iyawo rẹ Ammiebelle Bush ni ọdun 1957

Awọn ẹbi Olatunji sapejuwe rẹ gẹgẹ bi akinkanju eniyan

Iyawo Olatunji, Iyafin Ammiebelle Olatunji to jẹ ẹni ọdun mọkandinlaadọrun ṣe apejuwe ọkọ rẹ gẹgẹ bi ẹni to gbe igbeaye rẹ lati ṣe igbelarugẹ fun ifimọsọkan awọn ọmọ ilẹ Afrika.

Ni ọdun 1964, Olatunji ṣiṣẹ pọ pẹlu aarẹ akọkọ lorilẹede Tanzania, Julius Nyerere ati Malcolm X lati fopin si ofin ẹlẹyamẹya lorilẹede Amerika.

Awọn ọmọ meji ninu awọn mẹrin ti Olatunji bi, Folasade ati Modupe Olatunji ṣe apejuwe baba rẹ gẹgẹ bi akinkanju eniyan to si kọ awọn ọmọ rẹ ni ṣiṣe iṣẹ takuntakun lọna ati jẹ ki wọn jẹ akinkanju eniyan nibi gbogbo ti wọn ba de.

Ọdun 2003 ni Olatunji sun ti ko ji mọ ni ẹni ọdun mẹrindinlọgọrin.

Iṣẹ takuntakun to ṣe ni ẹka orin kikọ ti jẹ ki Babatunde Olatunji jẹ awokọṣe fun Afrika ati awọn ọmọ ilẹ Afrika ti wọn bi tabi ti wọn n gbe ni Amerika.