Water resources bill: Wo òhun tó yẹ kí o mọ nípa Àbádòfin lórí pínpín àti àmúlò omi ní Nàìjíríà tó bá di ìtẹ̀wọ́gbà

Aworan awọn to n pọn omi

Oríṣun àwòrán, Reuters

Bi eeyan ba ti n fọkan tẹle iṣẹlẹ to n waye nile aṣofin Naijiria lẹnu ọjọ mẹta yi, yoo ri wi pe niṣe ni iriwisi ọtọọtọ n waye nipa abadofin to da lori pipin ati amulo omi ni Naijiria.

Abadofin yii lọdọ awọn kan jẹ ọna ti ijọba yoo fi tubọ fun okun mọ awọn eeyan Naijiria lọrun.

Ṣugbọn lọdọ awọn aṣofin, wọn ni ọrọ ko ri bẹ bi kii ṣe pe awọn yoo fi abadofin naa da aabo bo alumọni omi ti Naijiria ni ko ba le kari ara ilu.

Lọwọlọwọ bayi, ijiroro lori ofin yi ti mu ki iyapa maa waye laarin awọn aṣaaju ile aṣojuṣofin Naijiria.

Lọjọ Iṣẹgun lawọn iwe iroyin Naijiria kan jabọ pe bi awọn aṣofin kan ti ṣe n sọ pe awọn fẹ joko gba ero ara ilu lori abadofin yi, lawọn aṣofin miran ni wọn ko ni sọrọ nipa rẹ mọ.

Ki gan an labadofin yi ko sinu ati pe awọn wo lo n tako sisọ aba yi dofin?

Orukọ abadofin naa lẹkunrẹrẹ:

Lede Gẹẹsi, orukọ abadofin yi ni National Water Resources Bill 2020 ti ẹka apaṣẹ Naijiria si kọkọ fi sọwọ si ile aṣofin kẹjọ.

Nigba ti wọn fi ṣọwọ, awọn aṣofin tapa si abadofin naa paapaa julọ awọn to wa lati guusu Naijiria lori ẹsun pe o fẹ gba ọna ijẹ lẹnu awọn eeyan to n lo omi ti Eledua fi jinki wọn.

Ero awọn apa kan Naijiria ni pe ijọba fẹ lo ofin yi lati fi gbalẹ ati agbara lilo omi fawọn Fulani darandaran ni.

Bayi ti wọn tun fi abadofin naa sọwọ pada nile aṣofin kẹsan an yi lọjọ Kẹtalelogun, oṣu Keje, ọdun 2020, awọn eeyan ti n beere pe ki lo mu ki ijọba fi abadofin yi ṣọwọ lẹyin tawọn eeyan tako.

Awọn wo lo lewaju ni atako abadofin yi?

Ninu awọn to gbohunsoke tako abadofin yi la ti ri Ọjọgbọn Wole Soyinka ati Gomina ipinlẹ Benue.

Yatọ si awọn wọn yi, ẹgbẹ oṣiṣẹ Naijiria naa ko gbẹyin ninu awọn to ni abadofin yii fẹ tubọ mu awọn kan lẹru ni Naijiria ni tawọn kan yoo si jẹ gaba le wọn lori.

Oríṣun àwòrán, Benue State Government

Awọn ti o tako abadofin yi naka abuku si ijọba Aarẹ Buhari pe o fẹ fi ofin yi gba iṣakoṣo omi lọna eru ni.

Loju opo Twitter awọn ẹgbẹ ajafẹtọmọniyan ni Naijiria bi SERAP ni awọn yoo tako abadofin yi nile ẹjọ tawọn aṣofin ba fi le buwọlu

Awọn koko to wa ninu abadofin ọhun

Ni ṣoki, ohun ti abadofin yo ko sinu ni pe ijọba Naijiria fẹ ki awọn le ṣe akoso lori lilo ati pipin omi ti Eledua fi ta Naijiria lọrẹ lapapọ.

Labẹ abadofin yi, ijọba apapọ tabi ijọba ipinlẹ yoo lagbara lati paṣẹ bi ara ilu yoo ti ṣe maa lo omi to ba wa ni agbegbe wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Koko miran to wa ninu abadofin yi ni pe eeyan tabi ileeṣẹ kankan to ba fẹ gbẹ omi pẹlu ẹrọ ''bore-hole'' yoo ni lati gba iyọnda lọdọ ijọba.

Bakan naa ni ofin naa yoo ṣe atunto awọn ileeṣẹ ijọba to n ṣe akoso ipese ati lilo omi lọwọlọwọ bayi.

Ni ipari ijọba n gbero pe abadofin yi yoo mu opin ba gbogbo ipenija to n ba Naijiria nipa lilo ati ipese omi.

Àkọlé fídíò,

Baby abandoned on dunmpsite: Mo ti bímọ mẹ́rin tẹ́lẹ̀ fún bàbá méjì nínú òṣí- Dupe Ogbomos