Fuel hike protest: Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ìpínlẹ̀ Oyo, Osun àti Ondo ṣe ìfẹ̀hónúhàn lórí èlé owó iná àti owó epo

Oyo

Oríṣun àwòrán, @eniola_opeyemi

Awọn akẹkọọ ile iwe giga ni ipinlẹ Oyo, Osun ati Ondo ti gunle ifẹhonuhan nitori ele to gori owo ina ijọba ati epo bẹntiro ni Naijiria.

Awọn akẹkọọ naa korajọ si oriṣiriṣi ojuko ni olu ilu awọn ipinlẹ naa lati fi aidunun wọn han si ijọba lori ibi ti eto ọrọ aje Naijiria n dori kọ.

Wọn ko awọn kaadi ti wọn kọ oririṣiriṣi akọle si, eyii ti wọn fi n bu ẹnu atẹ lu ele ori owo naa.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọro, agbẹnusọ awọn akẹkọọ ọhun, Kazeem Israel, sọ pe ele naa jẹ ọna lati mọọmọ ni awọn ara ilu lara.

O ni "Lai ṣe aniani, ijọba to wa lode yii ṣe afikun iṣoro awọn ọmọ Naijiria eyii to jugunba lọwọ ijọba ana ni, koda, ijọba Buhari n ṣapẹrẹ pe awa akẹkọọ ni lati pada si bi aṣe maa n fa 'aluta' laye atijọ."

Oríṣun àwòrán, Sahara Reporters

Kazeem ni eto ẹkọ ati eto ilera ti dẹnukọlẹ ti awọn to n ṣejọba ko si bikita fun igbeaye awọn ti wọn n ṣejọba le lori.

Àkọlé fídíò,

Akomolede ati Aṣa lori BBC: Mọ̀ si nípa oríṣìí ẹ̀ka ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ àti ìwúlò wọn

O fi kun pe ni ṣe lo yẹ ki Aarẹ Muhammadu Buhari kọwe fiposilẹ ti ko ba lee da owo epo bẹntiro pada si naira mẹtadinlọgọrun un.

Aṣoju awọn akẹkọọ naa ni ohun to yẹ ki ijọba ṣe ni ko ṣafikun iye owo to la kalẹ fun eto ẹkọ ni ida marundinlogoji ati iye owo to la kalẹ fun eto ilera, ko maa san owo ajẹmọnu ẹgbẹrun lọgọrun un nairan fun awọn akẹkọọ atawọn nnka miran.

Ṣaaju iwọde naa ti ẹgbẹ awọn ọmọ ile iwe ni Naijiria, NANS. ṣagbatéru rẹ, ni ijọba ti ṣafikun iye owo ina mọnamọna ati owo epo bẹntiro, ti ọpọ awọn ọmọ Naijiria si bu ẹnu atẹ lu igbesẹ naa.

Ṣugbọn Aarẹ Muhammadu Buhari ti fesi oun ko ni yi ipinu oun pada lori ele owo naa nitori bi nnka ṣe ri lasiko yii.

Àkọlé fídíò,

Temitope Akinnusi: Ọ̀pọ̀ iléeṣẹ́ ló takú láti gbà mí síṣẹ́ torí mo ní ojú kan

Ààrẹ Buhari pọ́n ọ̀dọ́ Nàíjíríà lé, ó ya Nov 1st sọ́tọ̀ fún àyájọ́ ọ̀dọ́

Oríṣun àwòrán, Kunle Adeleke

Aarẹ Muhammadu Buhari ti fọwọ si yiya ọjọ kan sọtọ lọdun lati maa ṣe ayajọ ọjọ awọ ọdọ jakejado Naijiria.

Eyi waye ninu atẹjade kan ti minisita to n ri si ọrọ awọn ọdọ ati ere idaraya, Sunday Dare fi sita loju opo Twitter rẹ.

Sunday Dare sọ pe ''pẹlu aṣẹ aarẹ, gbogbo ọjọ kini oṣu kọkanla ọdun ni wọn yo maa fi ṣe ayajọ ọjọ awọn ọdọ Naijiria.''

O ni Aarẹ Buhari sọ pe ọjọ yii ni wọn yo maa fi pe akiyesi ati wiwa ojutuu si awọn ọrọ to ni ṣe pẹlu ọdọ atawọn iṣoro ti wọn n koju.

Minisita ọrọ awọn ọdọ ni eyi tun fihan pe aarẹ Buhari ni ifarajin ati atilẹyin fun awọn aato to ba wa fawọn ọdọ Naijiria.

Pẹlu ikede yi, awọn ọdọ Naijiria yoo dara pọ mọ awọn akẹgb wọn lorileede Ghana ati Cameroon lati ṣe ayajọ ọjọ yi.

Ki lawọn ọdọ maa n ṣe lọjọ yi

Lawọn orileede ti wọn ti n ṣe ayajọ yi, awọn ọdọ a maa ṣe iwọde toun ti pọpọsinsin orin ati ijo.

Amọ lawọn ilẹ mii, niṣe ni wọn maa n fi ọjọ yi ṣe agbeyẹwo awọn ohun to kan ọdọ.

Ko ti daju boya wọn yoo ya ọjọ yi sọtọ lọjọ isinmi lẹnu iṣẹ ni Naijiria.