MKO Abiola: Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ àwọn olè tó kó góòlù àti ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ mílíọ̀nù lọ nílé Abiola l'Eko

MKO Abiọla ati Adebisi, iyawo rẹ

Oríṣun àwòrán, @mko_abiola

Ileeṣẹ ọlọpaa ti mu awọn afurasi adigunjale to ṣọṣẹ nile oloogbe Oloye Moshood Abiola to wa ni Ikeja niluu Eko nibi ti wọn ti ji nkan to to ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu lọ.

Abiola lo jawe olubori ninu ibo aarẹ gbogbogbo to waye lọdun 1993 eyi ọgagun fẹyinti Ibrahim Babangida wọgile nigba naa.

Kọmiṣọnna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu lo sọ pe ọwọ awọn agbofinro ti tẹ awọn kọlọnbiti ẹda ọhun ti wọn yabo ile Abiola l'Ọjọru.

Kọmiṣọnna ọlọpaa to ṣabẹwo si ile ọhun fidi rẹ mulẹ pe mẹta lawọn ole ọhun ṣugbọn ọkan lara wọn lo gbe ibọn dani.

Ọgbẹni Odumosu ni ''ẹbi Abiola sọ f'oun pe awọn ole naa ji ọpọlọpọ goolu ati owo lọ.''

''Awọn agbofinro ti wa lojufo bayii legbegbe Ikeja ti ile naa wa to fi de ọdọ awọn ọlọpaa to wa ni ibode Idiroko ati Seme,'' kọmiṣọnna ọlọpaa lo sọ bẹẹ.

Kọmiṣọnna ọlọpaa ipinlẹ Eko ni ko si ẹni to farapa ninu iṣẹlẹ naa ninu iyawo Abiola, Bisi ati ọmọbinrin meji to wa nile.

Ọgbẹni Odumosu fikun ọrọ rẹ pe iwadii ṣi n lọ siwaju lori iṣẹlẹ naa.

Awọn aladugbo to bawọn akọroyin sọrọ ṣalaye pe geeti to wa lẹyin lawọn ole ba wọle, wọn ni laago mẹrin idaji ni iṣẹlẹ naa waye nigba tawọn ẹṣọ to wa nile ile naa ti sun lọ.