Anthony Joshua: Ajagba akẹ̀ṣẹ́ ọmọ Nàìjíríà lóun ṣetán láti f'ẹ̀ṣẹ́ dín dòdò ìyà fún AJ

Anthony Joshua ati Efe Ajagba

Oríṣun àwòrán, Instagram

Yoruba bọ, wọn ni o di oni karangida, adiẹ n jẹ ifun ara wọn. Bayii lọrọ ri abẹṣẹ ku bi ojo ọmọ Naijiria, Efe Ajagba to ni oun ṣetan lati fi ẹṣẹ din dodo iya fun ogbontarigi akẹṣẹ Anthony Joshua.

Ilẹ Amẹrika ni Ajagba to ti ṣoju orilẹede Naijiria ri ninu idije ''Olympics'' fi ṣe ibugbe bayii lẹyin to ti wa niluu Eko fun ọpọlọpọ ọdun.

Ọrọ naa da bi ẹni to maa ku pade ẹni to maa pa, nirori Joshua gan an funra rẹ ti sọ tẹlẹ pe o wu oun lati fija pẹta pẹlu akẹṣẹ to jẹ ọmọbibi ilẹ Afirika bi t'oun naa.

Ajagba tiẹ ti bẹrẹ si ni sọ ọna ti o fi le fẹyin AJ gbalẹ ti wọn ba koju ara wọn.

Ajagba sọ fawọn akọroyin pe ko ba wu oun ki Joshua gba lati ba oun ja lorilẹede Naijiria tawọn mejeeji ti wa.

Abẹsẹ ku bi ojo ọmọ Naijiria ṣalaye pe lootọọ ni pe Joshua lagbara, amọ ọgban inu loun maa fi ṣẹ AJ leegun ẹyin tawọn koju ara awọn.

O ni ati oun ati Joshua lawọn jọ lagbara ṣugbọn o ni ọgbọn ju ọgbọn lọ.

Ajagba ni otitọ ni pe Joshua ti gba ami ẹyẹ goolu ninu idije ''Olympics'' ri, oun si tun ni abẹṣẹ ku bi ojo to lami lahaka taye ti aye n fẹ lọwọ bayii.

Oun oun naa gboṣuba fun AJ fun awọn aṣeyọri rẹ lagbo ẹṣẹ kikan, amọ oun mọ awọn ibi ti Joshua ku si ninu ẹṣẹ kikan.

Joshua gba awọn igbanu rẹ mẹtẹẹta, IBF, WBA ati WBO pada lọwọ Andy Ruiz Jr pada lẹyin ti Ruiz ti kọkọ lu u bi aṣọ ofi nigba ti wọn kọkọ koju ara wọn.

Joshua naa fẹ ṣe bi agbọjẹ ninu ẹṣẹ kikan, oloogbe Muhammad Ali to ba George Foreman ja ni Zaire lọdun 1974.

Amọ Ajagba ti kepe Joshua pe ko jẹ ki awọn ṣe ere ọwọ papọ ni Naijiria, o ni ti o ba ti ya eegun Joshua, o ti ya ọlọrẹ t'oun naa.