Makurdi Church theft: Àga oníke mẹ́wàá ní wọ́n kọ́kọ́ ni Joseph jí tó fi di èrò ẹ̀wọ̀n ní NASME Barracks ní Benue

Prison

Oríṣun àwòrán, others

Ọkùnrin ẹni ọdun marunlelogun kan, Joseph Ada ti NASME Barracks ni Makurdi ti foju bale ẹjọ majisireeti fun ẹsun ole jija, igbimọ iwa ọdaran.

Ọlọpaa to wa nidi ẹjọ naa, Sajẹnti Regina Ishaya sọ fun ile ẹjọ pe, Arabinrin Myina Ifeyunwa lo mu ẹjọ naa wa si agọ ọlọpaa 'D' Division ni Markudi ni ogunjọ, oṣu kẹjọ, ọdun 2020.

Olufisun ọ̀hún ni oun gba ipe lati ọdọ Ebenezer pe ẹnikan ti oun ko mọ ri jalẹkun wọ ile ijọsin Holy Ghost Sanctuary to je ti 'Penticostal' kan ni agbegbe Vita Foam, opopona oja tuntun ni Makurdi.

Àkọlé fídíò,

Akomolede ati Aṣa lori BBC: Mọ̀ si nípa oríṣìí ẹ̀ka ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ àti ìwúlò wọn

O ni àwọn mu ẹni ti wọn fẹsun.kan naa pẹlu aga onike mẹwaa to jẹ ti ijọ naa.

Sajẹnti Regina fi kun un pe, ěni ti wọn fẹsun kan naa fẹnu ara rẹ jẹwọ pe lootọ ni oun ji awọn aga naa amọ oun nikan kọ.

O ka Usman Jafaru ati Terdoo Moses naa mọ wọn sugbọn ko si ẹni to mọ ibi ti wọn wa.

Wọ́n tun ka awọn nkan miran ti wọn ji bi ẹrọ amunawa, faanu, ina lanta igbalode, ati aga onike mẹrinlelogoji ti owo gbogbo rẹ si to ẹgbẹrun lona ọọdunrun naira din diẹ, sugbọn iwadii si n tẹ siwaju.

Ẹwẹ, ẹni a fẹsun kan naa ni oun ko jẹbi ẹsun ohun ti wọ́n fi kan oun tan.

Àkọlé fídíò,

Mayowa Omoniyi: Kò sí orin Obey, Sunny Ade abí tàkasúfèé tí ń kò le ta gìtá sí

Adajọ Erdoo Ter to n dajọ ni majisireei naa wa ni ki wọn gba iduro pẹlu oniduro kan ati ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira.

Wọn ti sun igbejọ naa si ọjọ kọkandinlọgbọn, ọsu kesan an, ọdun 2020.