Oba Olajide Olayode: Ó pe ọlọ́pàá láti yanjú aáwọ̀ ìlú lórí owó orí, bílísì bá dé

Aworan aafin Soun ti Ogbomosọ ati ade ọba

Awọn ọba alaye nilẹ Yoruba ni ọwọ nla gidi, tawọn araalu si maa n wa riri fun wọn.

Ojuse awọn ọba si ni lati pa ina aawọ to ba fẹ suyọ laarin ilu, ko to di rogbodiyan.

Amọ wahala nla kan bẹ silẹ lọdun 1969 nilu Ogbomoso to wa nipinlẹ Oyo bayii, eyi to kọja agbara ọba, koda, o tun mu ẹmi rẹ lọ pẹlu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

A si le pe itan yii ni apa keji Ogun Agbekoya nitori ara afikun owo ori tawọn agbẹ n ja fun lo fa sababi iṣẹlẹ yii, gẹgẹ ba ṣe ka a loju opo itakun agbaye.

Oríṣun àwòrán, Others

Bi ifẹhonu han to gba ẹmi ọba ṣe bẹrẹ:

Ọjọ nla, ọjọ manigbagbe ni ọjọ kinni oṣu Keje ọdun 1969 nilu Ogbomoso lasiko ti ogun abẹle n lọ lọwọ ni Naijiria.

Asiko yii naa tun ni ogun Agbekoya n waye nilu Ibadan eyi to bẹ silẹ nitori afikun owo ori tijọba ṣe fun awọn agbẹ.

Ọba Soun tilẹ Ogbomoso nigba naa ni Ọba Immanuel Olajide Olayode Keji, o si wa laafin rẹ to n dari ilu, bẹẹ lo n fi oye da awọn ọtọkulu ilu lọla.

Gẹgẹ baa se gbọ latẹnu iya agba kan nilu Ogbomoso, Ọba Olayode, lasiko to gori itẹ jẹ ni ti aye n fẹ nitori inu gbogbo ọmọ Ogbomoso lo dun lasiko to jọba lọdun 1967.

Oríṣun àwòrán, Others

Koda orin ti wọn n kọ nigba naa ni " Olayode jọba, ilu toro nini...", ti gbogbo ilu si n tuba tusẹ lasiko rẹ.

Ni ọdun 1969 ni Ọba Olayode fi oye Asipa Ogbomoso da Ajagunfẹyinti Benjamin Adekunle, ti ọpọ eeyan mọ si Black Scorpion lọla, lai mọ pe isẹlẹ manigbagbe kan yoo waye laipẹ sigba naa.

Lẹyin ọjọ diẹ ti ayẹyẹ ifinijoye naa waye, ni awọn agbẹ ati ọdẹ nilu Ogbomoso taku pe awọn ko le san iye owo ori ti wọn bu fun awọn, ti wọn si n bẹ ọba Olayode lati bawọn se adinku rẹ.

Àkọlé fídíò,

Temitope Akinnusi: Ọ̀pọ̀ iléeṣẹ́ ló takú láti gbà mí síṣẹ́ torí mo ní ojú kan

Asiko yii naa si ni irufẹ ibeere yii n waye nilu Ibadan, eyi to papa di Ogun Agbekoya.

A gbọ pe Ọba Olayode da ọjọ fawọn agbẹ lati wa ba se ipade laafin lati dijọ fẹnuko lori iye owo ori ti wọn yoo san.

Nigba ti ọjọ pe, awọn agbẹ ati ọdẹ peju biba si aafin ọba lai mọ pe ọba naa ti ransẹ pe awọn agbofinro, pe ki wọn maa bọ lati koju awọn eeyan naa.

O ni pẹlu ọwọ lile latọdọ awọn agbofinro, eyi yoo jẹ ki wọn gba iye owo ori ti wọn ni ki wọn san tipatipa.

Àkọlé fídíò,

Mayowa Omoniyi: Kò sí orin Obey, Sunny Ade abí tàkasúfèé tí ń kò le ta gìtá sí

Gẹgẹ bi ẹni ti isẹlẹ naa soju rẹ ti sọ fun BBC Yoruba, bi awọn ọlọpaa naa ti n bọ lati Ibadan, oju wọn kọrẹ lọwọ, bi wọn si se wọ ilu Ogbomoso ni wọn kọju oro sawọn araalu ti ko mọwọ mẹsẹ.

Iro ibọn n dun lakọ-lakọ, ti ọpọ ẹmi si n bọ titi ti ilẹ fi su lọjọ naa, koda, iya agba to ba wa sọrọ ni diẹ lo ku ki ibọn ba oun lasiko ti oun n tilẹkun isọ awọn.

Amọ o ni ibọn ba ọmọbinrin kan to n kiri ila lọ loju popo, to se alabapade awọn ọlọpaa naa, ti ibọn si gba ẹmi rẹ.

Àkọlé fídíò,

Ogbologbo ijapa l'aafin Sọun

Ni kete tawọn agbẹ ati ọdẹ gbọ nipa iporogan to n waye laarin ilu, wọn faraya, awọn naa bẹrẹ iwọde lọ saarin ilu, bẹẹ ni wọn n kọrin owe, tawọn ọlọpaa si n koju wọn.

Ọṣẹ ti awọn ọlọpaa ṣe laarin ilu naa gba odi, awọn ọdẹ, agbẹ ati araalu lapapọ fa ibinu yọ, wọn ba ọpọ dukia to wa ninu aafin jẹ, ti wọn si tun sọ ina saafin Ọba Layode naa.

Ṣugbọn lasiko tawọn agbofinro n pitu ọwọ wọn niwaju aafin fawọn agbẹ ati ọdẹ yii, to fi de aarin ilu lapapọ, diẹ lara awọn afẹhonu han yii ti yọ kẹlẹ wọnu aafin Soun, ti wọn si ni o di dandan ki ọba faye silẹ lọjọ naa.

Àkọlé fídíò,

Akomolede ati Aṣa lori BBC: Mọ̀ si nípa oríṣìí ẹ̀ka ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ àti ìwúlò wọn

Iya agba ni, Ọba Layode naa kii se ọba yẹpẹrẹ ti wọn kan le pa tuẹ bii ẹni pa adiẹ nitori oun gan le pawọda nilana ti ibilẹ pẹlu oogun abẹnu gọngọ.

Wọn ni ọba yii parada di orisirisi nnkan bii ologbo, okuta ,titi de ori ọmọ tuntun, ti ọkan lara awọn ayaba gbe pọn, nigba tawọn oluwọde yii wọnu iyẹwu rẹ.

Amọ awọn eeyan naa pasẹ fun ayaba lati gbe ọmọ naa kalẹ nitori awọn ko ri gbọ pe ayaba kankan bimọ laafin lasiko igba naa.

Oríṣun àwòrán, Others

Ọba Layode papa parada di eeyan, tawọn afẹhonu han naa si pa a sinu aafin rẹ, wọn la ọfun rẹ, ge e lori, ti wọn si tun yọ nnkan ọmọkunrin rẹ.

Koda, a gbọ pe wọn pin ẹran ara rẹ yẹlẹ yẹlẹ ni, ti wọn si kun ni ijanja, idi si ree ti wọn se maa n pe awọn ara Ogbomoso nigba miran pe "Ogbomoso a pọba jẹ."

Esi ti awọn naa si maa n fọ pada ni pe, "o ni ohun ti ọba se, ki wọn to pa a, nitori ti ko ba si ẹsẹ, ẹsẹ kii dede sẹ".

Àkọlé fídíò,

Baby abandoned on dunmpsite: Mo ti bímọ mẹ́rin tẹ́lẹ̀ fún bàbá méjì nínú òṣí- Dupe Ogbomos

Itan yii ko tii tan sibẹ, a gbọ pe wọn gbe ori ọba Olajide Olayode atawọn ẹya ara rẹ yoku sọwọ, wọn n jo yika ilu pẹlu ẹjẹ bala-bala ati orin eebu, ti gbogbo ilu Ogbomoso si daru lọjọ naa.

Ohun ti wọn fun eṣu, eṣu gba a lọjọ naa, ti ọpọ dukia si bajẹ laarin ilu, o kere ẹmi eeyan to le ni ọgọrun ba iṣẹlẹ naa rin.

Kii si ṣe ọba nikan ni eekan ilu ti ẹmi rẹ bọ sinu laasigbo ọhun, koda ẹmi awọn ijoye kan gan lọ si, ti ẹjẹ nla si san nilu Ogbomoso lọjọ naa.

Nibi ti ọrọ naa buru de, ọgọọrọ ọlọpaa ati ọmọ ologun ti wọn fi ransẹ silu Ogbomoso ko lee dẹkun laasigbo naa, tori ọpọ dukia lo bajẹ sinu iṣẹlẹ naa, ti ọpọlọpọ oku si sùn pẹlu.

Àkọlé fídíò,

'Oyenusi ló mú mi wọ ẹgbẹ́ adigunjalè kó tó di pé mo b'Ólúwa pàdé'

Bẹẹ ni ọwọ ọlọpaa ba lara awọn eeyan ko n gbe ori ọba jo kiri ilu naa, ti wọn si ko wọn wa silu Ibadan fun ẹsun ipaniyan ati idaluru.

A gbọ pe ọpọ lara awọn ti wọn ko si ahamọ nilu Ibadan lori isẹlẹ ọhun ni ko pada mọ silu Ogbomoso, ti awọn ẹbi rẹ ko si mọ boya o ku ni tabi o sọnu.

Amọ lẹyin o rẹyìn, alaafia jọba, ti ilu Ogbomoso si pada tuba tusẹ titi di oni, bi o tilẹ jẹ pe nnkan to dara ti bajẹ saaju.

Àkọlé fídíò,

Owu Water Fall: Ọba Oyewole ni ibùdó ìrìn àjò afẹ́ gidi ni àmọ́ ọ̀nà ibẹ̀ burú jáì

Ẹkọ ti itan yii kọ wa:

  • Ẹkọ akọkọ ni pe ka maa tẹti silẹ lati gbọ alaye ara wa ko to di iporogan.
  • Ẹkọ keji ni pe o yẹ kawọn asiwaju maa setan lati gbọ tẹnu awọn araalu nigbakuugba ati nibikibi
  • Ẹkọ kẹta ni pe ki araalu maa ni suuru ati ifarabalẹ, ki wọn si takete si iwa jagidi jagan nitori a ko mọ ẹmi ẹni to le e mu lọ
  • Ẹkọ kẹrin ni pe ki ọwọ wa maṣe ya lati da ẹmi ẹnikẹni legbodo tabi fun ẹnikẹni ni ọgbẹ lasiko aigbọraẹniye nitori ọba oke nikan lo mọ iye ẹni ti wahala naa le kan
  • Ẹkọ karun ni pe ka yẹra fun iwa ailaju nibikibi abi nigbakuugba nitori iwa ailaju lo le mu ka maa gba ẹmi ara wa tabi ti ọpọlọpọ eeyan lori ohun ti ko to nnkan
  • Bakan naa, lo yẹ ki awọn agbofinro maa lọra lati yinbọn pa araalu lori nnkan kekere eyi to le fa bilisi lẹsẹ.