Donald Trump gbìyànjú nípa ètò àlááfíà ló jẹ́ kí n fàá kalẹ̀ fún àmì ẹ̀yẹ Nobel Peace Prize- Christian Tybring- Gjedde

Aworan Trump

Oríṣun àwòrán, Reuters

Wọn ti fa Aarẹ ilẹ Amerika, Donald Trump kalẹ fun ami ẹyẹ Nobel Peace Prize ti ọdun 2021.

Ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Christian Tybring- Gjedde, to jẹ ọkan lara awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin orilẹ-ede Norway lo fa Trump kalẹ fun ami ẹye naa.

Gjedde sọ fun ileeṣẹ iroyin Fox pe Aarẹ Trump yẹ lẹni to n gba ami ẹyẹ naa fun iṣẹ ribiribi to ti ṣe lati jẹ ki alaafia wa laarin awọn orilẹ-ede kan lagbaye.

O ni "ami ẹye ọhun yẹ Trump gan ni nitori o gbiynaju lati jẹ ki alaafia wa laarin awọn orilẹ-ede kan agbaye ju awọn eeyan miran to ti gba ami ẹyẹ naa ṣaaju rẹ."

Ninu iwe to kọ si awọn igbimọ to n fun eeyan ni ami ẹyẹ ọhun, o sọ pe ijọba Trump gbiyanju lati lati jẹ ki alaafia gbilẹ laarin ijọba ilẹ United Arab Emirates ati Israel.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Gjedde sọ fun ileeṣẹ iroyin Fox pe kii ṣe pe oun gba ti Aarẹ Trump to bẹ lo jẹ ki oun faa kalẹ fun ami ẹyẹ naa, ṣugbọn o n gbiyanju tirẹ to ba jẹ ni ti eto alaafia.

O ni "O yẹ ki awọn igbimọ to n ri si ami ẹyẹ ọhun wo ti awọn akitiyan Trump gẹgẹ bi ohun amuyẹ fun ami ẹyẹ ọhun, kii ṣe iwa rẹ."

Aṣofin naa ni pupọ ninu awọn to ti gba ami ẹyẹ naa ṣeyin, bii Aarẹ ana l'Amẹrika, Barack Obama, ko ṣe to ohun ti Trump ti ṣe.

Àkọlé fídíò,

Mayowa Omoniyi: Kò sí orin Obey, Sunny Ade abí tàkasúfèé tí ń kò le ta gìtá sí