Àlàyé rèé lórí bí 'Popular Jingo' ṣé dí inagijẹ akọrin Juju tó bí Wale Thompson 'Lalalẹ Friday'

Aworan Popular Jingo lara ọkọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Popular Jingo

Pupọ awọn to ba dagba saaju igba kọmputa ta wa yii ni yoo ti gbọ ki wọn maa pe ẹni to ba jẹ ilumọọka tabi gbajumọ ni ''Popular Jingo.''

Inagijẹ yi wọpọ laarin awọn Yoruba ṣugbọn diẹ lawọn ẹni ti yoo ṣi ranti pe eeyan kan to jẹ akọrin Juju ni apejẹ rẹ n jẹ ''Popular Jingo.''

Ta wa ni ẹni taa n sọ yi ati pe iru ipasẹ wo lo ni lagbo ere Juju?

BBC Yoruba ṣe iwadii ọrọ yii nipa biba alagba David Anwo Agbolade ti awọn eeyan mọ si Popular Jingo sọrọ.

Oríṣun àwòrán, Popular Jingo

Ilumọọka Akọrin Juju ni David Agbolade tawọn eeyan si ni o wa lara awọn to mu ki orin Juju fẹsẹrinlẹ nilẹ kaarọ o jiire.

Lasiko rẹ, eeyan ko le darukọ olorin Juju lagbegbe Ijebu Igbo, Eko ati Ibadan ki wọn ma pe Popular Jingo mọ wọn.

Bi awọn Sunny Ade ati Ebenezer Obey ti ṣe n fi orin juju da awọn eeyan lara ya nilu Eko ni Popular Jingo naa n migboro titi laaye tiẹ naa.

Ọdun 1943 ni wọn bi alagba David Anwo Agbolade ti o si bẹrẹ ileewe ni Saint Luke's Primary School ni Japara Ijebu Igbo, lọdun 1949.

Alagba David ni ''nigba ti mo wa ni ileewe alakọbẹrẹ ni mo ti bẹrẹ si ni fifẹ han si orin kikọ''

''Koda mi o ti kẹkọ pupọ ki n to mọ lọkan mi pe iṣẹ orin lọna mi''

Oríṣun àwòrán, Popular Jingo

Amọ ṣa baba to bi David iyẹn, alagba Moses Anwoloju Aina ko nifẹ si ki ọmọ rẹ kọrin.

Popular Jingo ni ''Ada ni baba mi yọ si mi nigba ti mo ni mo fẹ bẹrẹ orin. Inu wọn ko kọkọ dun si nigba naa''

Yatọ si pe o jẹ akọrin Juju, Popular Jingo a tun maa gba bọọlu nigba ewe rẹ.

Idi ere boolu gbigba gẹgẹ bi o ti ṣe sọ ni awọn akẹgbẹ rẹ ti fun ni apejẹ rẹ, Popular Jingo.

Oríṣun àwòrán, Populkar JINGO

Ifẹ to ni si orin kikọ yii tun tẹsiwaju si ni igba to wa ni Saint Vincent Catholic Modern School.

Ni igba taa n wi yii, Agbolade a maa ta jita pẹlu 'Mouth Organ' ki o to wa pada wa maa lo 'Accordion'.

''Ni ọdun 1979 ni mo mọ daju lọkan mi pe mo ni ẹbun orin kikọ. Ohun to si ṣẹlẹ ni pe mo kọrin nigba ti eeyan kan ku lagboole wa''

Oríṣun àwòrán, Popular Jingo

Lọjọ naa lọhun Jingo sọ pe niṣe ni gbogbo ile pa lọọlọ ti oun si fi orin da awọn eeyan lara ya.

'Awọn eeyan tẹwọgba orin mi lọjọ naa ti inu mi si dun''

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC,Popular Jingo ni ohun ko ni ọga kan pato.

Amọ o salaye pe ẹnikan ti wọn n pe ni Kolawole Ijaduoye alias 'Kolly Jo' lawọn bẹrẹ orin Mamba lọdọ rẹ ki awọn to yi pada si Juju ṣugbọn ko pe ti awọn lo lọdọ rẹ.

''IK Dairo, Ojoge Daniel, Tunde Nightingale, ati Rosa Adetola ni mo maa n wo lawokọṣe ni igba naa.''

Oríṣun àwòrán, Popular Jingo

Agbolade sọ pe ninu gbogbo wọn, ''Tunde Nightingale ni mo maa n tọ ipasẹ re.''

Nigba naa lọhun, Popular Jingo sọ pe Haruna Ishola olorin Apala to jẹ ọmọ Ijebu Igbo a maa gba oun ni imọran lati maa mu diẹ ninu 'style' Tunde Nightingale.

Spika kan, Makrofoonu kan ni mo fi bẹrẹ orin juju kikọ

Royal Brothers Band lorukọ ẹgbẹ akọrin ti Agbolade sọ pe oun da silẹ lọdun 1962.

O si ni nigba naa lọhun irinṣẹ tawọn fi n kọrin ko pọ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Popular Jingo

Tohun ti bẹ awọn eeyan a maa gbadun orin Juju Popular Jingo paapa lagbegbe Ijebu Igbo, ilu Eko ati Ibadan.

Wale Thompson onijuju ọmọ Popular Jingo nii ṣe

Popular Jingo gbe awo orin orisirisi jade to fi mọ 'Oridamilare', 'Ile ẹkọ ni ile ọkọ' ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Alagba David fẹ iyawo, o bimọ, o kọ ile koda ninu awọn ọmọ rẹ ati ọmọ ọmọ rẹ, awọn to n kọrin juju wa ninu wọn.

Oríṣun àwòrán, Popular Jingo

Wale Thompson, gbajumọ olorin Juju nii to kọ orin 'Lalalẹ Friday', ni akọbi Popular Jingo to si tẹwọ gba jita lọwọ baba rẹ.

Ẹni ọdun mejidinlọgọrin ni Popular Jingo ti ko si ti maa ṣere ode onijuju mọ.

''Mo dupẹ fun igbe aye mi,inu mi a si maa dun pẹlu ti awọn eeyan ba pade mi ti wọn a si maa sọ pe emi ni mo kọrin nibi ikomọ awọn''

Nilu Ijebu Igbo ni alagba David n gbe titi di asiko yi pẹlu awọn mọlẹbi rẹ.