Adunni Oluwole: Akíkanjú obìnrin àkọ́kọ́ to dá ẹgbẹ́ òṣèlú àti tíátà silẹ ṣáájú Ogunde

Adunni Oluwole

Oríṣun àwòrán, wikipedia

Yoruba ni ẹni to ba mọ ibi ti ọrọ yoo wo si, ọta ọlọrọ ni.

Bẹẹ lo ri pẹlu akikanju obinrin kan, to rinu rode bii Olodumare, to si mọ bi ọjọ ọla yoo ṣe ri fun orilẹ-ede Naijiria, ka to gba ominira.

Adunni Oluwole, ni akọni obìnrin ọmọ Yoruba to tako ominira fun orile-ede Naijiria nitori igbagbọ rẹ pe awọn ọlaju yoo fi iya nla jẹ awọn mẹkuunu, ti oyinbo ba gbe akoso le wọn lọwọ.

Gẹgẹ ba ṣe ka a loju opo wikipedia atawọn itakun agbaye yoku, obìnrin bii ọkùnrin ni Adunni Oluwole, ajàfẹ́tọ̀ọ́ ẹni ati ajijagbara nla si ni nigba aye rẹ.

Bi itan igbe aye rẹ si ṣe lọ ree pẹlu awọn isẹ akikanju to ṣe lati ja fun mẹkuunu.

Itan aye Adunni Oluwole

Ọdun 1905 ni wọn bi Adunni sile aye, idile awọn jagunjagun nilu Ibadan si ni baba rẹ ti wa.

A si le ni Adunni jogun ba awọn iwa akikanju to ni yii ni, nitori inu ẹjẹ rẹ lo wa, o si laya bii kiniun.

Lasiko ti Adunni wa ni ewe, wahala kan ṣẹlẹ ninu ẹbi rẹ, eyi to mu ki iya rẹ ko ẹru kuro nile, gba ilu Eko lọ.

Agboole Aroloyo nilu Eko, ni iya Adunni n gbe, eyi to mule ti sọọsi Johannu mimọ, St John, ti alufa oyinbo, Adolphus Howells n dari.

Adugbo yii ni wọn ti tọ Adunni dagba, ti alufa Howells si maa n ran ẹbi rẹ lọwọ nípa jijẹ ati mimu.

Nigba to ya, Alufa Howells mu Adunni si ọdọ rẹ lati maa gbe, to si fi sile ẹkọ alakọbẹrẹ St John, Aroloya, amọ Adunni pada sọdọ iya rẹ lẹyin to pari eto ẹkọ alakọbẹrẹ rẹ.

Adugbo Mushin ni Adunni ti lo igba ọdọ rẹ, to si jẹ ọmọ ti ẹnu rẹ mu, ṣe ọmọ ti yoo jẹ asamu, kekere ni yoo ti maa jẹ ẹnu samu samu.

Fun apẹẹrẹ, laarin ọdun 1925 si 1932, nigba ti Adunni wa ni ọdọ, ó kọ ere onise kan fun ẹgbẹ ọdọbinrin Girl's Guild ti ìjọ St John nilu Eko, Ọlọla Herbert Macaulay si lo dari ere naa.

Ere onise yii dun, o larinrin, to si jẹ itẹwọgba ọpọ eeyan, a si le ni Adunni ni obìnrin akọkọ ti yoo da ẹgbẹ akọṣẹmọṣẹ oṣere tiata silẹ ni Naijiria.

Koda, a gbọ pe Adunni da ẹgbẹ oṣere tiata rẹ silẹ siwaju Herbert Ogunde, ti ọpọ mọ bii ọkùnrin akọkọ to da ẹgbẹ oṣere tiata silẹ ni ẹkún ìwọ oorun Afíríkà.

Ibẹrẹ iwa ijijagbara Adunni Oluwole

Lati inu ìjọ Ọlọrun ni Adunni ti bẹrẹ iwa ijijagbara rẹ, eyi to papa sọ di ilumọọka ko to jade laye.

Akinkanju obìnrin yii di oniwaasu akin, koda, o tako iwa gbigbe oku wọ inu ìjọ fun isin ikẹyin, o ni oun ri iran lati ọdọ Ọlọrun, to ni Ọlọrun alaaye ni oun, oun kii ṣe Ọlọrun oku.

Ọrọ oye, imọ ati ọlọgbọn to maa n ti ẹnu Adunni jade jẹ ki ọpọ eeyan fẹran rẹ pupọ, ti wọn si maa n tẹle lẹyin bii asaaju wọn.

Iwa ijijagbara akọni obinrin yii si lo mu ko ko awọn obinrin jọ lati ṣe atilẹyin fáwọn oṣiṣẹ reluwe to da isẹ silẹ lọdun 1945.

Koda, Adunni tun gbe owo nla silẹ fun ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ naa lati fi tọju ara wọn nigba táwọn ijọba amunisin ko sanwo osu fun wọn tori iyanselodi yii.

Nigba to di ọdun 1954, Adunni da ẹgbẹ oselu silẹ fawọn mẹkuunu, to pe ni Nigerian Commoners Liberal Party (NCLP), ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ oselu naa si lo jẹ ọkùnrin.

Lati jẹ ka mọ bi ẹgbẹ oselu rẹ ṣe gbajumọ laarin ilu si, ko pe osu marun ti wọn da ẹgbẹ NCLP silẹ, lo gba ijoko kan ni ẹkún idibo ariwa Osun, to si fi ẹyin ẹgbẹ alakukọ NCNC ati ọlọpẹ AG janlẹ ninu idibo sile asofin naa.

Lara awọn ọna ti Adunni gba seto ipolongo ibo rẹ, ti araye fi gba ti ẹgbẹ oselu rẹ ni pe, o n mura bii ẹlẹ́wọ̀n lati polongo ibo, ti okiki rẹ ati ti ẹgbẹ oselu rẹ si gbale ẹ kan.

Oludije latinu ẹgbẹ NCLP to moke ni D. L Olateju, to si fi awọn Oludije latinu ẹgbẹ oselu Obafemi Awolowo ati Nnamdi Azikiwe, to lagbara nigba naa gbolẹ.

Amọ nigba to di ọdun 1956, ti wọn kede pe Naijiria yoo gba ominira lọwọ oyinbo amunisin, Adunni yari patapata pe ko ṣeeṣe.

Alaye rẹ ni pe awọn oloselu alawọ dudu yoo fiya jẹ awọn mẹkuunu ni, ti agbara ba bọ sọwọ wọn tan.

Àkọlé fídíò,

Wo ìdílé tí ìyá àti gbogbo ọmọ kara bọ iṣẹ́ ṣíṣe epo tà

Ọpọ igbesẹ Adunni Oluwole lati tako ominira Naijiria

Iṣẹ kekere kọ ni Adunni ṣe lati ri daju pe awọn oyinbo amunisin ko fun Naijiria ni ominira lọdun 1960, gẹgẹ bi wọn ti kede rẹ.

Bi awọn eeyan kan si ṣe n fi oju were wo igbesẹ Adunni naa, ni awọn eeyan miran tẹwọ gba a, paapaa awọn mẹkuunu.

Awọn mẹkuunu yii si lo ko ara wọn jọ si abẹ akíkanjú obìnrin naa gẹgẹ bii ẹgbẹ, ti wọn pe orúkọ rẹ ni 'Ẹgbẹ́ Kí Òyìnbó Máì Lọ'.

Amọ ọda owo, awo olokun to n ba ẹgbẹ naa finra ko jẹ ko fi bẹẹ ri ẹsẹ walẹ, to si ku lairotẹlẹ nigba ti owona n da wọn laamu.

Ṣugbọn Yoruba ohun to ba n dun ni, nii pọ lọrọ ẹni, Adunni ko sinmi iwa ijijagbara rẹ, to si lọ saafin Olubadan ni ọjọ kẹẹdọgbọn osu kẹjọ ọdun 1955, lati salaye idi to fi tako ki Naijiria gba ominira, eyi to n atilẹyin Olubadan lori rẹ.

Olubadan ransẹ pe awọn oloye ati eekan ilu wa si aafin rẹ lati wa gbọ ti ẹnu akikanju obinrin, to ni Naijiria ko tii setan lati gba ominira.

Lara awọn to wa ni aafin Olubadan lọjọ ti Adunni wa ni gbajumọ oloselu kan nilu Ibadan, Adegoke Adelabu.

Adelabu pa akọni obinrin yii lẹ́nu mọ, to si pe e ni awọn orukọ abuku bii 'Aṣẹ́wó', koda o tun dunkoko pe oun yoo fi igbalẹ na a jade ni aafin Olubadan.

Ṣugbọn bi wọn ṣe n ge Adunni lọwọ, bẹẹ lo n bọ oruka, kaka ki ewe agbọn Adunni dẹ nidi atako to n ṣe fun gbigba ominira Naijiria, ko ko ko lo n le si.

Adunni ko sun, bẹẹ ni ko wo, koda, o tun morile ilu Akure lati tẹsiwaju nidi ipolongo atako fun ominira Naijiria to n ṣe.

Nilu Akure, Adunni ni ki wọn so okun mọ oun nidii, to si ni ki akọni ọkùnrin meji maa fa okun naa, eyi ti wọn fi n wọ ọ kiri oju popo.

Bi wọn ṣe n wọ kiri, bẹẹ lo n kigbe tako awọn oloselu Naijiria, to ni wọn yoo maa rẹ mẹkuunu, ti oun jẹ ọkan lara wọn jẹ.

Lasiko naa, ọpọ eeyan ni oye ohun ti Adunni n ṣe yii ko ye amọ to bẹrẹ si ye wa lẹyin ta gba ominira ọhun tan, ti oju wa si n ri mabo lọwọ awọn oloselu.

A si le pe Adunni Oluwole ni wolii ti ko niyi nile rẹ laye igba naa, tori ọpọ iwa ijẹgaba, aye familete ki n tutọ, ajẹbanu ati ifiyajẹni táwọn oloselu n hu bayii lo ti sọ asọtẹlẹ rẹ saaju, to si kilọ fun wa.

Àkọlé fídíò,

Ìtàn ọ̀rẹ́ tó fi ògùn gba ọkọ ọ̀rẹ́ rẹ̀ ni Akomolede BBC Yorùbá fẹ́ kọ́ wa lònìí

Iku Adunni Oluwole saaju ominira Naijiria

Ọrọ buruku, kii ba ikun nile ni iku Adunni Oluwole jẹ saaju ki ominira Naijiria lọwọ oyinbo amunisin to waye.

Adunni maa n gbadura pe oun ko fẹ ki oju oun ri rẹdẹ-rẹdẹ lẹyin ti Naijiria ba gba ominira tan, ki awọn oun to ti sọ asọtẹlẹ nipa rẹ, wa maa sẹlẹ loju aye rẹ.

Koda, akọsilẹ ni o sọ nita gbangba pe oun ko fẹ wa laye nigba ti Naijiria ba n gba ominira.

Boya idi ree ti Adunni Oluwole fi jẹ Ọlọrun nipe lọdun 1957, nigba to ku ọdun mẹta ti Naijiria yoo gba ominira.

Gẹgẹ bi akọsilẹ iku rẹ ti wi, akandun lásán-làsàn lo mu Adunni Oluwole ni ika, eyi to ja okun ẹmi rẹ lẹni ọdun mejilelaadọta pere.

Ohun to wa ṣe ni laanu ninu itan aye akọni obìnrin naa ni pe ọjọ ti ọmọ rẹ n ṣe ayẹyẹ igbeyawo, ni oun gan jade laye.

Ẹkọ ti itan aye Adunni Oluwole kọ wa

Itan aye Adunni Oluwole kọ wa lati ni ẹmi akin ati igboya, boya a jẹ ọkùnrin ni abi obìnrin.

Itan akọni obinrin naa tun kọ wa lati dide tako iwa ifiyajẹni, ìjẹgaba ati imunilẹru ni gbogbo ọna.

Itan aye Adunni Oluwole tun kọ wa lati jẹ akinkanju ni ipokipo ta ba wa.

Bakan naa la tun kọ ẹkọ pe ka ma fi ẹnu wa sọ ọrọ odi tabi ṣẹ epe nitori o le wa si ìmúṣẹ.