Osogbo JTF vs Youth Protest: Àwọn ẹbí Idris Ajibola ń fẹ́ ìdájọ́ lórí ikú ọmọ wọn

Osogbo JTF vs Youth Protest: Àwọn ẹbí Idris Ajibola ń fẹ́ ìdájọ́ lórí ikú ọmọ wọn

"Iku ẹ ko gbọdọ lọ lasan o, gbogbo awọn to wa nidi ẹ, mo fi wọn si ọwọ Ọlọrun".

Temitope, ẹgbọn Idris Ajibola ti ikọ amuṣẹya alaabo niluu Osogbo le oun atawọn ọrẹ rẹ de oju iku faraya.

Ọjọ kẹẹdogun oṣu kẹsan ọdun 2020 ni Idris salabapade iku.

BBC Yoruba ṣe ibẹwo si idile ti ọfọ ṣẹ yii niluu Osogbo nibi ti ẹsẹ ko ti gbero gẹgẹ bi awọn eeyan ṣe n wọ lati lọ bawọn kẹdun iku ọmọ wọn.

Ọ̀rọ̀ gbogbo ṣe wọn maa n ni Ọlọrun lo ye - Ọtọ lọrọ tawọn ọlọpaa sọ ọtọ la ba lẹnu awọn mọlẹbi Idris.

Ṣaaju ni baba ọmọdekunrin naa arakunrin Kehinde Ajibola sọ pe ọmọ oun kii ṣe oni yahoo yahoo ati pe iwa aibọwọ fofin lawọn agbofinro to ṣeku pa ọmọ naa hu.

Ẹgbọn rẹ ọkunrin to ba BBC Yoruba sọrọ sọ pe "ọmọ tiwa ko ki n ṣe yahoo boy o, amojuẹrọ ni ọmọ wa to si ti n ṣiṣẹ titun foonu ṣe latigba to ti pari ileewe".

O ṣalaye pe ṣaadede loun gba ipe lọjọ naa pe wọn ti pa aburo oun ti wọn si ti lọ t oku rẹ siwaju ọfiisi gomina ipinlẹ Osun, Gboyega Oyetola.