Oba Abd-Ganiyu Adekunle Salaueen Oloogunebi Ajinese 1 ti kéde pẹ orò ló kù láti lé àwọn ajínigbé

Oro festival

Oríṣun àwòrán, Oro Festival

A fẹ́ gbé orò láti lé àwọn ajínigbé kùrò ní ìpínlẹ̀ Oyo- Asẹyin

Aseyin ti ilu Iseyin, Oba Abd-Ganiy Adekunle Salaueen Oloogunebi Ajinese 1 ti sọ idi pataki ti ọdun oro yoo fi waye ni ilu Isẹyin ni asiko yii.

Oba Abd-Ganiy sọ eyi lasiko to n ke gbajare wi pe awọn ajinigbe ti poju lagbegbe naa, lẹyin ti wọn kede orisirisi iṣẹ ijinigbe to ti waye lagbegbe Ibarapa ati Oke-Ogun ni ipinlẹ Oyo.

O rọ ijọba apapọ lati gbiyanju lati ba wọn da si ọrọ naa ni kiakia nitori o ti n da ọrọ ojoojumọ.

Oríṣun àwòrán, Google

Oba Abd-Ganiy sọ eyi lasiko ti ọdun ọrọ bẹrẹ ni aafin Iṣẹyin ni opin ọsẹ.

Aṣẹyin ni ọdun oro ni ọdun 2020 yii yoo wa fun adura lati le awọn ajinigbe kuro ni ayika wọn, ki ijọba Makinde le ni alaafia.

Bakan naa lo ni wi pe ọjọ keje ati ikarundinlogun ọdun oro naa ni awọn yoo gbe oro naa.

Ni ọjọ ti wọn ba gbe oro naa, awọn obinrin kii jade titi oorun yoo fi wọ ni awọn ọjọ wọnyii.

Asẹyin ni: ''A ti fun awọn ajinigbe ni epe lati ma ṣe rojuraye ni agbegbe wa mọ, nitori o ti pọju ni agbegbe Ibarapa ati Oke-Ogun.''

''Bakan naa ni a kesi ijọba apapọ lati jọwọ ran wa lọwọ lati wa ọna abayọ si ijinigbe yii.''

Ninu atẹjade naa ni wọn ti fikun un wi pe awọn ẹsọ alaabo ti wa ni pesẹ lati ri i wi pe ayẹyẹ naa lọ ni irọwọ-rọsẹ.

Aseyin ti ilu Iseyin, Oba Dr. Abd-Ganiy Adekunle Salaueen Oloogunebi Ajinese 1 fikun un pe igba ati akoko gomina Seyi Makinde yoo rọ wọn lọrun.

O gba awọn adari nimọran lati ṣe ohun to yẹ fun igbadun ati alaafia ara ilu nitori awọn alalẹ ati ara ọrun n wo wọn.

Ṣaaju ni Ifayemi Elebuibọn ti sin awọn Ọba alade ni gbẹrẹ ipakọ lori oro gbigbe gẹgẹ bii aṣa ti ko yẹ ko parun

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ọbalayé ní kò yàtọ̀ sí èèyàn lásán - Elebuibon

"Ọpọlọpọ awọn ọbalaye ni ilẹ Yoruba ni ko yatọ si eeyan lasan nitori wọn n tapa si iṣẹṣe ati iṣẹmbaye".

Araba ilu Oṣogbo, Oloye Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn lo ṣọ ọrọ yii lasiko ajọdun ọdun kẹwaa rẹ lori oye gẹgẹ bi araba awo ilu Oṣogbo.

Oríṣun àwòrán, Crown-art

Oloye Ifayẹmi ni ọpọlọpọ awọn Ọba ni ko karamasiki orò ilu tabi aṣa ati iṣẹṣe mọ.

"Ọba ti wọn ko ba ṣoro fun, ti ko tẹfa ti ko ṣe gbogbo nnkan ibilẹ to jẹ ọba le lori, ko yatọ si eeyan lasan."

Baba Araba ni ohun to n da awọn ọba ya sọtọ naa ni awọn oro, ati nnkan ibilẹ ati iṣẹdalẹ ilu rẹ to jẹ ọba le lori.

Ọba ti ko ba ti wa ṣe e, baba Araba ni kii ṣe Ọba, eeyan lasan ni.

Àkọlé fídíò,

'Búrẹ́dì tí wọn ó fi jẹ ẹ̀wà ni wọ́n lọ rà ni wọ́n pàdé ikú gbígbóná'

O ni bi awọn Ọbalaye ba n tẹriba fun iṣẹṣe ati iṣẹdalẹ ilu wọn ni yoo mu ki ilu o toro ki o si tuṣẹ.

O rọ awọn aṣiwaju ni ilẹ Yoruba lati gbe aṣa ati iṣe Yoruba nitori ibi a gbe laa ṣe.

Oríṣun àwòrán, Getty Images / flev

O wa rọ awọn adari lorilẹede Naijiria pe ki wọn ṣee re nitori ohun wọn ba ṣe silẹ n labọwaba.

Ni ọdun 2010 ni wọn fi oloye Ifayẹmi jẹ oye Araba awo ti ilu Osogbo eyi to fihan pe oun ni olori gbogbo onifa ati alawo ni ilu Oṣogbo.