Iwo Kingmakers: Ìjọba Osun ní òun sí ń wo ọ̀rọ̀ Oluwo àtàwọn afọbajẹ lọ́wọ́ kó tó mọ ìgbésẹ̀ tó kàn

Oluwo tilu Iwo

Oríṣun àwòrán, Oluwo/instagram

Yoruba ni agba kii wa lọja, kori ọmọ tuntun wọ, bẹẹ si ni agbalagba ti ko ba kẹu sọrọ, afaimọ ko ma kẹtan sare.

O ti to ọjọ mẹta bayii ti iporogan ti n waye laarin Oluwo tilu Iwo, Ọba Abduilrasheed Adewale Akanbi ati awọn afọbajẹ ilu naa.

Idi ni pe awọn afọbajẹ yii lo n kesi ijọba ipinlẹ Osun pe ko yọ Ọba Akanbi kuro nipo ọba nitori awọn ohun kan to tọkasi bii asemase rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bi Oluwo se n salaye tirẹ, naa ni awọn ijoye, afọbajẹ ati araalu lapapọ ko sinmi lori awijare tiwọn naa, ti laasigbo naa si n fọnna soju lojoojumọ.

Lọwọ lọwọ bayii, Oluwo ti gbe awọn afọbajẹ naa lọ sile ẹjọ, ti awọn afọbajẹ naa si ti gbe Oluwo lọ sile ẹjọ miran.

Oríṣun àwòrán, Oluwo/instagram

Sugbọn bi eruku laasigbo naa se n sọ lala to nilu Iwo, ijọba ipinlẹ Osun ko fọhun rara lori ọrọ naa, titi to fi de ile ẹjọ bayii.

Idi ree ti BBC Yoruba fi kan si ijọba Osun lati gbọ tẹnu wọn lori isẹlẹ ọhun nitori bawọn ọmọde ba n ge igi ninu igbo, awọn agba lo maa n mọ ibi ti igi naa yoo wo si.

Nigba to n jẹwọ pẹlu wa, Kọmiṣọna fun ileesẹ to n ri si ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ ni ipinlẹ naa, Adeleke Yekini Adebayo ni ijọba ipinlẹ Osun si n ṣagbeyẹwo ọrọ naa.

Àkọlé fídíò,

Obateru Akinruntan: Wíwá ohun tá jẹ títí láé ló gbé wa kúrò nílé Ife

O ni wọn si n wo iwe ẹhonu ti awọn afọbajẹ ilu Iwo kọ mọ Oluwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi, Telu Kinni, ki awọn to gbe igbesẹ kankan.

Adebayo ni "Mo le e sọ fun yin ni kedere pe, ootọ ni wọn kọ iwe mọ Oluwo, ṣugbọn ijọba ṣi n yẹ iwe naa wo lọwọ."

Kọmisana naa, ti ọpọ eeyan mọ si Banik sọ pe, ijọba ipinlẹ Osun ko tii gbe igbesẹ kankan lori iwe ẹhonu ọhun.

O ṣalaye pe, ijọba yoo wo iwe ọhun wo finni-finni ko to gbe igbesẹ kankan, ṣugbọn ni bayii, o ṣi n ṣagbeyẹwo rẹ ni.

Oríṣun àwòrán, Instagram/oluwoofiwoland

Kọmiṣona naa pari ọrọ rẹ pe, ijọba ipinlẹ Osun yoo kede igbesẹ to kan fun awọn eeyan ipinlẹ Osun, ni kete to ba ti ṣe ipinnu lori ọrọ naa.

Lọwọ lọwọ bayii, awọn afọbajẹ mejila nilu Iwo ti n rọ ile ẹjọ giga ijọba ipinlẹ Osun, lati da Oluwo lọwọkọ, ko maa baa rọ wọn loye.

Ninu iwe ipẹjọ oloju ewe mejila ni agbẹjọro awọn afọbajẹ naa, John Enworo, ti fẹsun kan Oluwo pe, o ti n gbe igbesẹ lati fi awọn eeyan miran rọpo awọn afọbajẹ ọhun.

Ṣaaju ni awọn afọbajẹ ọhun ti kọwe mọ Oluwo lọdọ gomina ipinlẹ Osun, iyẹn Gboyega Oyetola lọjọ kẹsan an, oṣu Kẹsan an, ọdun 2020.

Àkọlé fídíò,

SS3 ní mo wà báyìí, mo sì ti gba àmì ẹ̀yẹ̀ púpò nílé-lóko gẹ́gẹ́ bí onílù - Ayansike

Wọn wa n rawọ ẹbẹ pe ko gba ade ọba lori Oluwo, nitori awọn iwa kobakungbe ti wọn fi kan an.

O ti to nnkan bi ọjọ mẹta kan ti eruku aawọ ti n waye laarin Oluwo ati awọn afọbajẹ naa to taku pe lilọ ni Oluwo gbọdọ lọ fun awọn.

Wayii, awọn afọbajẹ ọhun ti ke gbajare si ile ẹjo giga ipinlẹ Osun, lati dẹkun Oluwo ninu yiyẹ aga oye mọ awọn nidii.

Ki lo ti ṣelẹ sẹyin?

Iwo Kingmakers: Osa tìlú Iwo ní Oluwo fẹ́ máa dá owó ilú ná ló fa wàhálà

Oríṣun àwòrán, Instagram/oluwoofiwoland

Ani ka jẹ ekuru ko tan, se ni wọn tun n gbọn ọwọ rẹ sinu awo, ni ọrọ ariwo pe wọn fẹ yọ Oluwo tilu Iwo lori oye, eyi to gba igboro kan.

Bẹẹ ba gbagbe, o ti to ọjọ mẹta bayii ti eruku aawọ ti n waye laarin Oluwo ati awọn afọbajẹ to taku pe lilọ ni Oluwo gbọọdọ lọ fun awọn.

Lara awọn Baalẹ to wa nilu Iwo, lasiko ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ ni, awọn eeyan kan to n se ilara Oluwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi, Telu Kinni, lo n pariwo pe awọn fẹ rọ loye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bẹẹ ni Oluwo naa ti salaye pe iwa ajẹbanu lo n da awọn afọbajẹ to fẹ rọ oun loye laamu nitori pe awọn eeyan kan lo gbe owo fun wọn lati se bẹẹ.

Amọ asaaju afọbajẹ tilu Iwo, tii tun se Osa ilu naa, Oloye Yekeen Bello, lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ salaye pe, bi Oluwo fẹ, bo kọ, lilọ ni yoo lọ lori oye naa.

Nigba to n salaye idi ti eyi yoo fi ri bẹẹ, Oloye Bello ni ọrọ owo tijọba n fun awọn , eyiun Oluwo, awọn ijoye ati Baalẹ lo fa jaadi yii nitori pe Oluwo fẹ maa da owo naa na.

Bello ni ohun to buru jai ni ki Ọba maa fun awọn ijoye ni ẹgbẹrun mẹta si mẹrin losoosu lati maa mu lọ sile, bẹẹ ni oun, Osa, si ni igbakeji rẹ nilana oye ilu Iwo.

Oríṣun àwòrán, Instagram/oluwoofiwoland

"Aarin awa ati Oluwo ko gun rara nitori naa la se n kọwe ẹhonu pe ki wọn yọ loye.

O ro pe a ko laju, o n sọ fun wa pe ka lọ wa isẹ mii se nitori Ọba nikan lo ni owo tijọba n fun wa losoosu, o ro pe a ko mọ bo se n lọ, ẹrin rẹ pa mi nitori ko tii mọ nnkan kan."

Osa ilu iwo fikun pe, ọpọ eeyan lo n kọwe ẹhonu nipa Oluwo ati awọn iwa to n hu, koda, ohun tawọn eeyan maa n sọ nipa rẹ lawọn oju opo ibanidọrẹ lori ayelujara ko bojumu rara.

"Iwa rẹ n ko abuku ba ilu Iwo ati orilẹede wa Naijiria lapapọ, ti Ọba ba se bo se yẹ, ko si ẹni ti yoo sọrọ si, amọ ti Ọba ko ba bọwọ fawọn ijoye rẹ ati agbaagba ilu, ki lẹ ro pe yoo sẹlẹ gan."

Oríṣun àwòrán, Oluwo/Instagram

Oloye Bello tẹsiwaju pe ọpọ igba lawọn ti gba Oluwo nimọran, ti ko gbọ, awọn ko si le tẹsiwaju lati maa fara daa mọ nitori idojuti nla ni Oluwo n ko ba awọn.

Osa Iwo ni, nitori iwa abuku Oluwo yii ni wọn se ni ko lọ rọọkun nile ninu ipade igbimọ awọn lọbalọba nipinlẹ Osun.

O ni to ba si jẹ pe awọn fẹ gba eyi kanri ni, ọrọ naa ko ba ti bọwọ sori fun Oluwo amọ awọn kii se ọmọde nitori naa lawọn se fi ọwọ ẹrọ mu ọrọ ọhun nigba naa.

Àkọlé fídíò,

Yemen Water Child: Ọmọdé 44 ni Sọ́jà pa, tí 100 míì sì kú látọwọ́ ohun ìjà olóró

Osa wa fọwọ gbaya pe ori ohun tawọn sọ si lawọn wa o pe, lilọ ni Oluwo yoo lọ nitori pe o si n tẹsiwaju lati maa ba awọn ni orukọ jẹ, bẹẹ ni ko setan lati yanju aawọ naa nitunbi n nubi.

Oluwo kéde ọdún tí yóò gbé adé Iwo sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Gistube

Kabiyesi Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Rasheed Akanbi ti jẹ ko di mimọ fun awọn to n pe fun irọloye rẹ pe ọdun mẹtadinlaadọrin lo ku fun oun lati lo lori oye gẹgẹ bi Oluwo.

Ilẹ poyi ni ilu Iwo lọjọ Ẹti lẹyin ti awọn afọbajẹ kan dide pẹlu iwe ẹhonu si ijọba ipinlẹ ṣun lati rọ Oluwo loye nitori ohun ti wọn pe ni awọn iwa aṣemaṣe rẹ lori oye.

Bi awsn kan ṣe n wọde tako igbesẹ awọn afọbajẹ naa lawọn araalu miran n sọ pe ohun to tọ si kabiyesi oluwo naa.

"Ọdun mẹtadinlaadọrin lo ku funmi lori apere awọn baba mi . gọfa ọdun ni n o lo laye. Awọn to fẹ le mi kuro lori oye yoo nilo lati ṣe pẹlẹ daadaa nitori asiko mi niyi."

Àwọn tó fẹ́ kí ọba máa ta ilẹ̀ ilú ló fẹ́ yọ Oluwo lóyè- Ẹgbẹ̀ Baálẹ̀ Iwo.

Àkọlé fídíò,

Iwo Kingmakers: Ìlú fẹ́milóye ni Ọba Abdulrasheed Akanbi- Ẹgbẹ̀ Baálẹ̀ Iwo

Ìwa jẹgúdú jẹra àti àjẹbánu ló ń da àwọn afọbajẹ ti wọ́n fẹ́ yọ Olúwo ọba Abdulraheed Akanbi nípò.

Ó ni àwọn kan to fẹ́ jẹ ọba ni wọ́n ń fẹ yọ Olúwo kúrò nípò, nítori ìwà ọ̀tẹ ni

Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Báálẹ̀ ìlú papa Ademola Adegoke tó sójú gbogbo àwọn Baálẹ jákèjádò gbogbo ilú Iwo, tó sàlàyé pé, Ilúfẹmilóye ni Oluwo jẹ gbogbo àwọn ọmọ ilú ló sì wà ni ẹ̀yin rẹ.

Adegoke ni àwọn afọbajẹ náà ń fẹ́ ki Oluwo, Oba Abdulrasheed Akanbi maa ta ilẹ̀ mọ́ àwọn ènìyàn Iwo lórí nítorí wọ́n ni owó kò tó .

Láìẹ́k yìí ní àwọn kan wọ́n sọ fún Kabièsí láti maa ta ilẹ̀. Bákan náà lo fi kun pé, láti ìgbà tí o ti de orí oyè ni wọn ti n lo àwọn afọbajẹ kógun tii.

Ẹ̀wẹ̀, Ilé iṣẹ́ BBC pe ọ̀kan lára àwọn afọbajẹ ti wọ́n buwọ́lu iwé ẹsùn Yekini Oosa ti wọ́n fi síta pé ki o sàlàye lórí ìdí tí wọ́n fi fk yọ Oluwo.

Èsì tí o fún BBC ni pé"Gbogbo rẹ lo ti wa lóri ayélujára ki a lọ wòó níbẹ̀ àti pé kò síi ọ̀rọ̀ ti òun fẹ́ sọ síi

Oluwo kọ̀ láti sọ̀rọ̀ lórí àwọn afọbajẹ tó fẹ́ yọ ọ́ nípò, aráàlú fọ́n síta láti fẹ̀hónú hàn

Oba AbdulRasheed Akanbi, Oluwo ti fesi sawọn Afọbajẹ mejila ti wọn kọwe si Gomina Gboyega Oyetola pe ko rọ Oluwo loye.

Nigba to ba BBC Yoruba sọrọ, Oluwo sọ pe ohun ko ni ọrọ kankan ti oun le sọ nipa ọrọ naa.

Amọ, ohun to sọ nipe awọn oloye kan buwọlu iwe ti awọn oloye naa kọ si Gomina ipinlẹ Oṣun, nigba ti awọn mii kọ lati buwọlu iwe naa.

O ni ọrọ naa tun kan ẹnikan to n wa oye lati ọpọ ọdun sẹyin ti ko ri.

Ẹwẹ, ọpọ araalu Iwu lo fọn sita lati fi ẹhonu han lori igbesẹ awọn oloye to fẹ yọ Oluwa ni ipo.

Ọpọ ninu wọn lo n sọ pe Oba AbdulRasheed Akanbi ti ṣe iranwọ nla fun awọn araalu.

Wọn ni ki Oluwa maa ba ijọba rẹ lọ wi pe o tẹ awọn lọrun.

Oríṣun àwòrán, Instagram/oluwoofiwoland

Wo ìdí tí àwọn afọbajẹ ìlú Iwo ṣe fẹ́ kí ìjọba ìpínlẹ̀ Osun rọ Oluwo l'óyè

Igbimọ ijoye mejila nilu Iwo, ipinlẹ Osun, ti kọwe si ijọba ipinlẹ naa, lati rọ Oluwo ti Iwo, Oba Abdulrasheed Akanbi, loye, fun 'awọn iwa adojutini to hu gẹgẹ bi ọba. Awọn ijoye naa to ko ara wọn jọ labẹ orukọ' Awọn afọbajẹ ti ọrọ ilu kan gbọn-gbọn', beere fun igbesẹ yii ninu iwe ẹsun kan ti wọn fi ránṣẹ si gomina ipinlẹ Osun, Adegboyega Oyetola. Awọn ijoye naa fi ẹsun kan Oba Akanbi pe o kede ara a rẹ gẹgẹ bi Olu Ọ̀ba 'Emperor', lẹyin ti wọn fi jẹ ọba lọdun 2016. Wọn ni orúkọ oye tuntun yii jẹ nkan ti awọn ko gbọ ri ninu itan ilu Iwo.

Àkọlé fídíò,

Akomolede àti Aṣa: Ọ̀rọ̀ Ẹ̀yán ni Bunmi Femi Amao ń kọ́ wa lórí ètò Akọ́mọlédè àti Àṣà lóri BBC Yoruba

Wọn fi kun ọrọ wọn pe Oluwo tun da awuyewuye silẹ lasiko to kede ninu oṣu Keje ọdun naa, pe gbogbo ọkunrin ilẹ Yoruba, ni itẹ Ooni Ile-Ife tọ si. Ko tan sibẹ o, àwọn ijoye naa tun fi ẹsun kan Oba Akanbi pe o doju ija kọ awọn eeyan pataki nilu Iwo, ati ibomiran.Wọn ni lọwọ-lọwọ, Oluwo ba Oloye Abiola Ogundokun, Imran Adio (olori ẹṣin Isilaamu) to yọ nipo Otun Ajanasi, ja.

Oríṣun àwòrán, Instagram/oluwoofiwoland

Bakan naa ni wọn lo sọ ọrọ abuku si Alaafin Ọyọ, Oba Lamidi Adeyemi ; Ooni Ile-Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi ; Orangun Ila, ati awọn ọba miran nipinlẹ Osun.Àmọ́ o, Akọwe Iroyin fun Oluwo, Alli Ibrahim, sọ ninu atẹjade kan pe "diẹ lara awọn to fọwọ si iwe ẹsun naa ko finu-findọ ṣe e."Aṣini lọna kan lo fi agidi mu wọn."

Àkọlé fídíò,

Toyin Atoyebi mechanic: Ẹ wo Toyin, ọmọbinrin ọdún 16 tó ń tún skadà àti gẹnẹrátọ̀ ṣe ní

O ṣalaye pe kii ṣe igba akọkọ niyi ti ẹni naa ti n tabuku Oba Akanbi, sugbọn to n ja si ofo."Dipo ijakulẹ, awọn aṣeyọri ti Oluwo ti ṣe tubọ n mu ki awọn ara ilu Iwo fẹran rẹ si ni."