Kano-Niger rail line: PDP ní àìmèyí tó kàn n'ìgbèsẹ̀ ìjọba láti ná $1.95bn sórí reluwé làti Kano sí Niger Republic.

Oríṣun àwòrán, Twitter/Nigeria Railway Corporation
Ẹgbẹ osẹlu alatako PDP ti bu ẹnu atẹ lu bi ijọba apapọ orilẹ-ede Naijiria ti buwọlu $1,959,744,723.71, fun iṣẹ agbaṣe oju ọna ọkọ reluwe ti yoo so orilẹ-ede Naijiria pọ mọ Niger Republic.
Akọwe agba ati alukoro ẹgbẹ oṣelu PDP, Kola Ologbondiyan to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe aimọ eyi to kan lo jẹ ki ijọba gbe igbesẹ naa.
Ọgbẹni Ologbindiyan sọ pe kii ṣe asiko ti ijọba ṣe afikun owo ina ati owo epo bẹntiro yii lo yẹ ki ijọba tun maa na ẹgbẹlẹgbe biliọnu owo dọla sori ojuurin reluwee lati Kano si orilẹede Niger.
- Wo bí ìwọ náà ṣe lè rí gbà nínú owó ìrànwọ́ tí ìjọba Nàìjíríà fẹ́ pín
- Ẹ yé parọ́ kiri! Orílẹ̀-èdè Amẹrika kò ṣọ́ wọlé-wọ̀de mi àti ìdílé mi- Atiku fèsì
- Ẹ dín iye ìgbà tẹ n gorí obìnrin kù torí ìdìbò tó n bọ̀, kẹ́ẹ lè lágbára láti ṣe ... - Ọ̀gá àgbà ọlọ́páà
- Wo bí ìwọ náà ṣe lè rí gbà nínú owó ìrànwọ́ tí ìjọba Nàìjíríà fẹ́ pín
''Nisinyii ti ijọba n ṣe oju ọna reluwee lọ si Niger lati ran wọn lọwọ, iranlọwọ wo lawọn ọmọ Naijiria gan an tii riu lati ọdọ ijọba yii,'' Ologbondiyan lo sọ bẹẹ.
Ologbondiyan ni ọgbọn ati ko owo jẹ naa ni gbogbo ohun ti ijọba apapọ n ṣe pẹlu ṣiṣe ojuurin lọ si ilẹ Niger.
Akọwe agba ati alukoro ẹgbẹ oṣelu PDP ni kii ṣe nitori araalu ni wọn fi n ṣe ohun ti wọn n ṣe lori reluwee lọ si Niger.
Ologbondiyan ni ẹgbẹ PDP ko tako ojuurin ti ijọba yii ṣe lati Eko si Ibadan nitori awọn mọ pe anfaani lo wa nibẹ fun araalu.
Oríṣun àwòrán, Twitter/Nigeria Railway Corporation
O ni nkan to ba yẹ ki ijọba Buhari fi si iwaju lo n fi sẹyin.
O ṣalaye pe ọkọ ojuurin ti ilu Eko si Ibadan ti ijọba Muhammadu Buhari fẹ ṣi gan an, ẹgbẹ PDP naa lo bẹrẹ rẹ.
Nibi ipade igbimọ alasẹ ijọba apapọ ti Aarẹ Muhammadu Buhari dari l'Ọjọru ni wọn ti fi ontẹ lu owo naa.
SS3 ní mo wà báyìí, mo sì ti gba àmì ẹ̀yẹ̀ púpò nílé-lóko gẹ́gẹ́ bí onílù - Ayansike
Minisita fun eto irinna, Rotimi Amaechi, gẹgẹ bi iwe iroyin The Punch ṣe jabọ, sọ fún awọn akọroyin pe ijọba buwọlu owo naa fun idagbasoke oju ọna ọkọ reluwe ti yoo so bẹrẹ lati ipinlẹ Kano-Dutse-Katsina-Jibia, titi de Maradi lorilẹ-ede Niger Republic.
Oju ọna irin naa, tó jẹ kilomita 248 ni ireti wa pe yoo sisẹ fun gbigbe eporọbi.
Oríṣun àwòrán, Twitter/Nigeria Railway Corporation
Yatọ si eyi, Amaechi tun sọ pe igbimọ naa tun buwọlu isẹ agba ṣe ti owo rẹ le ni biliọnu mẹta Naira ₦3.049bn, fun ṣíṣe, ayẹwo ati ikojade ẹ̀rọ ti yoo ma a gbe reluwe to ba ni ijamba kuro loju ọna.
Ẹwẹ, laarin oṣu kẹsan ọdun 2020 yii ni ileeṣẹ ọkọ ojuurin sọ tẹlẹ pe ọkọ reluwe yoo bẹrẹ si ni ṣiṣẹ lati ilu Eko si Ibadan.
- Wo oríṣi inú rírun márùn-ún tí o kò gbọdọ̀ pa mọ́ra
- Mo ṣetán láti ṣe Paulo Costa bí ọṣẹ sẹ ń ṣojú lọ́la- Israel Adesanya
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ arábìnrin tó fẹ́ ta alòkù kọ́ńdọ́ọ̀mù 324,000 padà f'áwọn èèyàn
- Kọ́ sí i nípa àwọn oúnjẹ aṣaralóore tó yẹ kí Aláboyún máa jẹ
- Wike, má gbé jàgídíjàgan wá sí Ondo, APC kò ní ṣ'èèrú nínú ìdìbò gómìnà tó ń bọ̀- Kalejaye
Oludari ileeṣẹ reluwee lorilẹede Naijiria, Fidet Okhiria lo sọrọ naa niluu Ibadan nigba ti minisita eto irinna, Rotimi Amaechi n ṣe abẹwo ibi ti iṣẹ de lori ojuurin reluwee lati Eko si Ibadan ninu oṣu kẹjọ.
Okhiria sọ pe ibudokọ reluwee to wa ni Yaba ni irinna naa yoo ti gberasọ niluu Eko si Ibadan.
Ọgbẹni Okhiria ṣalaye pe awọn ọkọ reluwee naa yoo maa na Eko si Ibadan ni igba mẹrindinlogun lojoojumọ.
- Nǹkan yan, àwọn aṣẹ́wó fẹ́ daṣẹ́ sílẹ̀ nítorí ẹ̀kúnwó epo ní Nàìjíríà
- Ìbúgbàmù gbogbo ìgbà nílù ú Èkó, kí ló ń ṣokùnfà rẹ̀?
- Ọlọ́pàá kọlu àwọn ọmọ onílẹ̀, ní ìbọn àṣìyìn pa ènìyàn méjì
- Ẹ wá ná, kí ló ń ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú APC àti Kayode Fayemi ní Ekiti gan an?
- Afurasí Boko Haram pa ológun àti ọlọ́pàá mẹ́rìnlá ní Borno
- Èèmọ̀! Àwọn adigunjalè yabo ṣọ́ọ̀ṣì, wọ́n fipá bá obìnrin kan lòpọ̀, wọ́n yìnbọn fún òmíràn
- Ìpínlẹ̀ Bauchi àti Kaduna láti máà tẹ àwọn afipábánilopọ̀ lọ́dàá