Nigeria at 61: Ikọ̀ Boko Haram, ìbò June 12, ìwọ́de EndSARS wà lára ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò bá sọ Nàíjíríà sójú ogun

Awọn isẹlẹ to n da ilu ru

Oríṣun àwòrán, @andybes50484929

Orilẹede Naijiria jẹ orilẹede to n san fun wara ati oyin, ti ọba oke si fi ọpọ ohun alumọọni jinki rẹ, ki ogun abẹle to wọle de lọdun 1967.

Bakan naa ni awọn ọlọpọlọ pipe ẹda kun orilẹede yii dẹnu ni ẹka eto iselu, ọrọ aje, eto ẹkọ, imọ ẹrọ, eto ilera ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Sugbọn ni aarin ọdun mọkanlelọgọta ti Naijiria ti n tukọ ara rẹ, lai si ọwọ awọn eebo amunisin nibẹ, oju ti ri.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Nàìjíríà kàn wà ni, ẹ ò páàsì, ẹ ò féèlì, ẹ ò kúrò ní kíláàsì kan náà - Àwọn ọ̀dọ́

Aara ti san, atẹgun nla ati iji lile ti fẹ pẹlu, koda, iji ti ja lorilẹede Naijiria, eyi to ti dunkooko mọ eto irẹpọ ati isọkan orilẹede yii, diẹ si lo ku ki orilẹede yii tuka.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọba Oke nikan si lo mọ idi taa fi wa papọ titi di oni, bi o tilẹ jẹ pe diẹ lo ku, ki iji da omi inu agbọn orilẹede Naijiria nu, paapaa lati ipasẹ ogun abẹle ta ja kọja.

Amọ lero ti awọn eeyan kan, orilẹede yii ko tii kọgbọn rara lati ipasẹ ogun abẹle naa, ta ba wo awọn iwa adaluru ta tun n hu.

Koda, aimọye awọn isẹlẹ adaluru lo ti waye, ti ko ba tun pada di ogun abẹle miran, amọ ti Ọba oke ba wa dẹkun rẹ.

Oríṣun àwòrán, @mavel

Idi ree ti BBC Yoruba fi wọ inu itan lọ lati se agbeyẹwo igba meje ọtọọtọ ti ẹpọn agbo Naijiria ti mi, amọ ti Ọlọrun ko jẹ ko ja, ba se n se ajọdun ominira.

Awọn isẹlẹ meje ti ko ba ti sọ Naijiria sinu ogun abẹle:

Iwọde EndSARS:

Ọpọ ọmọ Naijiria, paapaa awọn ọdọ ni ko le gbagbe iwọde EndSARS yii, eyi to ku diẹ ko sọ Naijria sinu ogun abẹle miran.

Awọn ọdọ Naijiria lo ko ara wọn jọ lati tako iwa ika ati ifiyajẹni tawọn ọlọpaa n hu, paapaa awọn ikọ ọlọpaa to n gbogun tiwa idigunjale ni Naijiria, ti wọn n pe ni SARS.

Awọn ọdọ lo yari pe ki ijọba apapọ wọgile ikọ naa nitori iwa ika ti wọn n hu sawọn ọdọ ati bi wọn se n pa wọn ni ipakupa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Laarin osu kẹsan si ikẹwa ọdun 2020 ni awọn ọdọ yii fi n se iwọde alagbara eyi to mu ki ijọba kede pe oun tu ikọ SARS naa ka.

Amọ eyi ko mu kawọn ọdọ naa dẹkun iwọde ọhun, ti wọn si n gbe idi dina lati dena lilọ bibọ ọkọ ati ero, titu ọgba ẹwọn silẹ, kikọlu awọn osisẹ ọlọpaa, ti wọn si tun n kslu awọn ileesẹ ati dukia ijọba gbogbo.

Idi ree tawọn ipinlẹ kan fi kede ofin konile o gbele lọna ati fopin si ifẹhonuhan awọn ọdọ yii.

Sugbọn ni ogunjọ osu Kẹwa ọdun 2020, tijọba ipinlẹ Eko kede ofin konile o gbele tiẹ, ni iroyin tan kalẹ ni irọlẹ ọjọ naa pe awọn ologun ti lọ kọlu awọn ọdọ to n se iwọde lẹnu iloro Lekki nilu Eko.

Oríṣun àwòrán, Twitter

Ọpọ ọdọ ni wọn lo jalaisi lọjọ naa, tawọn miran si fara pa bi o tilẹ jẹ pe ileesẹ ologun ni oun ko yin ọta ibọn to le gbẹmi eeyan nibẹ.

Isẹlẹ naa lo mu ki ibinu awọn ọdọ tubọ ru soke, ti awọn janduku kan si ya si igboro lọjọ keji yika Naijiria, wọn n jo ile, mọto, ileesẹ ijọba, agọ ọlọpaa, bẹẹ ni ọpọ ẹmi ba rogbodiyan naa rin.

Ọpọ Ọba oke ti ko jẹ ki ọrọ naa ju bo se wa lọ, ko to ba wa bomi pa ina rẹ, amọ rabaraba isẹlẹ naa ko ti tan nilẹ ni Naijiria.

Eto idibo June 12:

Igba keji ti isọkan ati ifẹsẹmulẹ Naijiria yoo mi pupọ nilẹ ni asiko ti ijọba ologun Ibrahim Badamosi Babangida wọgile eto idibo aarẹ ta di lọjọ kejila osu Kẹfa ọdun 1993.

Eto idibo aarẹ naa, ti wọn ni Oloye MKO Abiola lo bori rẹ, nijọba ologun Babangida wọgile, eyi to fa laasigbo nla, paapaa nilẹ Yoruba.

Oríṣun àwòrán, @MKO_Abiola10

Awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ajafẹtọ ẹni nilẹ yii ati ni awujọ agbaye lapapọ ni wọn gbọnmu lori igbesẹ naa ti oniruuru iwọde ati atako si n waye.

Lasiko naa, ara ko rọ okun, bẹẹ ni ko rọ adiẹ pẹlu, tawọn osisẹ gunle iyansẹlodi, awọn osisẹ elepo rọbi ko sisẹ, ohun gbogbo dẹnu kọlẹ, ti ẹya Yoruba si n dunkooko lati ya kuro nilẹ Naijiria ti wọn ko ba kede oloye Abiola bii aarẹ Naijiria.

Nitori ọrọ yii nijọba Babangida fi yẹba kuro lori aleefa, ti ijọba ologun miran, ti Sani Abacha lewaju rẹ, si gba akoso orilẹede yii lọwọ rẹ.

Oríṣun àwòrán, Wikipedia

Sugbọn sibẹ, ilu ko tuba tusẹ, titi ti Sani Abacha fi ku sori aleefa, MKO Abiola naa jade laye, ti ijọba ologun Abubakar Salami si gba akoso orilẹede yii lọdun 1998.

Ijọba Salami yii lo seto idibo mii, ti Oloye Olusegun Obasanjọ fi jawe olubori ninu ibo aarẹ to waye lọdun 1999, eyi to fopin si laasigbo oselu ati ti ẹlẹya mẹya naa.

Ọba oke si lo mu ki ẹsẹ Naijiria duro re pada, bibẹẹkọ, wahala ibo June 12 ko ba ti ree isọkan ati irẹpọ Naijiria ni ẹfasẹ.

Ikọlu ikọ adunkookomọni Boko Haram:

Oríṣun àwòrán, Sabah

Isẹlẹ miran to tun n dunkooko mọ isọkan ati irẹpọ orilẹede Naijiria, to si tun wa nibẹ lọwọlọwọ bayii ni idasilẹ ati ọsẹ ikọ adunkooko msni Boko Haram.

Gẹgẹ ba se gbọ, ikọ alatilẹyin awọn oloselu ni ikọ naa, eyi ti Mohammed Yussuf ko sodi, amọ nigba to ya lo parada di ijọ ẹlẹsin Islam.

Ikọ Boko Haram yii lo n beere pe oun n fẹ amulo ofin Sharia lorilẹede Naijiria, ti ko si gbọdọ si ohunkohun to jọ mọ ẹkọ iwe tabi ọlaju igbalode.

Oríṣun àwòrán, @BokoHaramWatch

Awọn ọmọ ikọ Boko Haram yii wa gbagbo sori nigba ti asaaju wọn, Mohammed ku si ahamọ awọn agbofinro, ti wọn si bẹrẹ si ni soro bii agbọn.

Wọn ri atilẹyin ikọ agbesunmọmi lagbaye, Al Queda gba, tawọn naa si bẹrẹ si ni yin ado oloro kaakiri orilẹede Naijiria.

Bi o tilẹ jẹ pe ẹkun ariwa ni ọwọja ikọ afẹjẹwẹ Boko Haram naa pọ si, sibẹ, awọn eeyan ẹkun iwọ oorun ati ila oorun guusu Naijiria naa n mọ ipa rẹ lara.

Awọn ọmọ ikọ Boko Haram maa n jo ile, pa eeyan bo se wu wọn, wọn n ji eeyan gbe gba owo, ti wọn ko si mọ ọmọde tabi agba, koda, eremọde ni ado oloro jiju jẹ fun wọn.

Oríṣun àwòrán, @trueNija

O tiẹ to akoko kan, ti ẹkun guusu Naijiria n beere pe ti ajọse ko ba see se, ki wsn jẹ ki onikaluku pinya, ki alaafia lee jọba.

Ọpọ ẹmi lo bọ sọwọ awọn ọmọ ikọ Boko Haram eyi to si tun n peleke si bayii, bi o tilẹ jẹ pe ẹkun ariwa Naijiria lo n fi ara gba ikọlu wọn julọ.

Sugbọn nigba ti ina wọn jo de ori koko, akude nla lo mu wọ isọkan ati irẹpọ Naijiria, ọpẹ Ọlọrun ti ko si fẹ ki okun irẹpọ ati isọkan ja ni orilẹede yii.

Ikọlu awọn Fulani darandaran ati agbẹ:

Ikọlu miran to tun n fẹju mọ isọkan orilẹede Naijiria ni aawọ ojoojumọ to n waye laarin awọn Fulani darandaran ati awọn agbẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bi wahala yii si se n waye lẹkun ariwa, paapaa lawọn ipinlẹ to wa ni ẹkun aarin gbungbun Naijiria bii Plateau ati Benue, naa lo n waye ni guusu Naijiria.

Ko fẹẹ si ipinlẹ kan kan to bọ lọwọ ikọlu awọn Fulani darandaran yii, ti wọn n wa oko tutu fawọn maalu wsn lati jẹ.

Ọpọ igba si ni itorin ti sọ nipa oniruuru ọsẹ ti wọn n se fawọn agbẹ, yatọ si pe wsn n ba ire oko wọn jẹ, wọn yoo tun sa wọn lọgbẹ tabi gba ẹmi wọn.

Oríṣun àwòrán, ECWA

Atobi ma see bawi la lee pe awọn darandaran naa, nitori ọwọ ofin kii saba mu wọn, ohun gbogbo ti wọn ba si se, asegbe ni.

Ọwọja ikọlu wọn naa wa tubọ peleke si lasiko ti ijọba Muhammadu Buhari de ori aleefa, ẹni ti oun gan jẹ ẹya Fulani.

Bi awọn darandaran, ti iwadi ni ọpọ wọn kii se ọmọ Naijiria si se n gba ẹmi ni Plateau, ni wọn n se ọsẹ ni Benue, ti ipinlẹ Oyo, Ekiti, Akwa Ibom, Rivers ati bẹẹ bẹẹ lọ si n pariwo wọn pẹlu.

Bi ijọba ko se lee dẹkun ati wawọ isẹ laabi awọn darandaran yii wọlẹ, lo n dunkooko mọ isọkan ati irẹpọ Naijiria, ti gbogbo ẹya si n kọrin ki Ọlọmu da ọmu iya rẹ gbe.

Lọwọlọwọ bayii, ikọlu awọn darandaran naa ko tii ni ojutu, eyi to n dunkooko gidi mọ irẹpọ Naijiria nibayii to n sami ajọdun ominira ọgọta ọdun rẹ.

Ija ẹsin ati ti ẹlẹyamẹya:

Eto aabo to mẹhẹ pupọ lorilẹede Naijiria ti sokunfa ọpọ aisedeede eyi to dunkooko mọ ifẹsẹmulẹ ati isọkan rẹ.

Lọwọ lọwọ bayii, okun irẹpọ Naijiria ti yinrin, Ọba oke nikan si lo lee se ti okun irẹpọ naa ko fi ni rẹ ja laipẹ, gẹgẹ bi igbakeji aarẹ, Yemi Osinbajo se woye.

Oríṣun àwòrán, @Chibuzo76881211

Eyi ko si sẹyin orin lilọ laa lọ, bilẹ yii ko ba wọ mọ, a lọ ilọ miran tuntun, ti ọpọ ẹya to wa ni Naijiria n kọ lẹnu.

Awọn ẹya Yoruba, Igbo, Efik atawọn ẹya ke ke ke miran lo gba pe ẹya Hausa/Fulani n jẹ gaba le awọn lori, ti wọn si n pariwo pe ki ipinya wa.

Lọpọ igba ti eto idibo ba si n bọ, ni ariwo yoo gba ilẹ kan, ti ibẹru bojo yoo si wa pe se orilẹede Naijiria ko ni pin si yẹlẹyẹlẹ bayii.

Koda, orisun ọrọ aje wa gan n fa isoro, tawọn ẹya ti epo rọbi pọ si naa si n dunkooko pe awsn fẹ ya kuro ni Naijiria lati lee se akoso ohun alumọni ti ọba oke fi jinki awọn.

Oríṣun àwòrán, Olayomi Koiki

Bi iran Yoruba se n beere fun idasilẹ orilẹede Oduduwa, ni Igbo n beere fun idasilẹ orilẹede olominira Biafra.

Ẹgbẹ ọmọ bibi ẹya kọọkan bii Arewa, Afenifere, Ohaneze, Pandef ati bẹẹ bẹẹ lọ ni orin isọkan Naijiria ko si lẹnu wọn mọ, orin bo le di ogun , ko di ogun ni wọn n kọ.

Koda, ọrọ ẹlẹsinjẹsin ati ẹlẹya mẹya gan wa lara ohun to n mi ẹsẹ isọkan ati irẹpọ Naijiria , tawọn klẹsin Kristiẹni ati Musulumi si n fi ojoojumọ tutọ si ara wọn loju.

Oríṣun àwòrán, @Dray4lyf

Iwa ipani nipakupa naa n dakun wahala yii, ti ọpọ ẹya ko si ni igbẹkẹle mọ ninu orilẹede Naijiria.

Ta ba wa wo oniruuru isoro ati isẹlẹ to n mi ifẹsẹmulẹ Naijiria, ki ni ọna abayọ?

Ọpọ eeyan lo si n beere pe, se Naijiria yoo se ajọdun ọgọrun ọdun gẹgẹ bii orilẹede kan soso bi?

Àkọlé fídíò,

Ado Ekiti Blind Couple: Tọkọ-taya Oke ní Ọ́ba òkè ló fi àwọn dá àrà tó wù ú

Idahun si ibeere naa wa lọwọ iwọ ati emi ati iwa ta ba hu lati fẹsẹ irẹpọ Naijiria mulẹ tabi pagidina rẹ.