Independence Day Nigeria: Lamido Sanusi gbóṣùbà fún ìjọba lórí bó ṣe yọwọ́ ìrànwọ́ epo

Sanusi Lamido Sanusi

Oríṣun àwòrán, @Realshisha

Emir ilu Kano nigba kan ri, Sanusi Lamido ni ọpọ awọn to n kigbe kiri pe awọn n ja fun ẹtọ ẹkun awọn, ifẹ apo wọn nikan ni wọn fẹ.

O ni lẹyin ti wọn ba fi ija ẹlẹmẹya ati ẹsin de ipo ijọba tan, wọn maa bẹrẹ si sin ilu nibamu pẹlu ifẹ ọkan wọn.

Lamido sọrọ yii nibi eto kan ti ijọ Convenant Christian Centre, ti pasitọ Poju Oyemade n dari pe ni ipinlẹ Eko.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nibi ipade ori ayelujara ọhun, ni wọn ti pe gomina tẹlẹ fun ile ifowopamọ apapọ Naijiria naa, lati wa sọrọ lori ọrọ ija ẹlẹyamẹya ati ẹlẹsin to n fojoojumọ peleke si ni Naijiria.

Àkọlé fídíò,

Ìṣẹ̀lẹ̀ Kàyéèfì: Ìpáǹle tú Abass Owonikoko sí ìhòòhò ayé, kó tó gba kéú lọ́gbà ẹ̀wọ̀n

O ni isoro naa ko fi bẹẹ niṣe "pẹlu awọn eniyan orile-ede yii, bikose awọn ọtọkulu rẹ"

"Mi o lero pe awọn ti wọn ni awọn n ja fun ẹya Hausa, Igbo tabi Yoruba ni ifẹ awọn eniyan naa lọkan.

Ni kete ti wọn ba ti de ijọba tan, imọ ti ara wọn ati ẹbi wọn nikan lo ku.

"Ko si ẹni kankan to n soju Arewa, Guusu tabi Ila oorun, nnkan ti mo nsọ ni pe, wọn ni awọn n soju ibẹ sugbọn irọ ni.

Ninu itan Naijiria, ko ti si ijọba ti ko ni asoju lati gbogbo ẹya Naijiria.

Oríṣun àwòrán, @Realshisha

"Nnkan akọkọ to yẹ ka mojuto ni pe, a gbọdọ gbagbe ero pe nigba ti eniyan ba wa nijọba, lo n jẹ asoju ẹya abi ẹsin rẹ, ko yẹ ki o ri bẹẹ".

Sanusi ni, ọkan lara isoro Naijiria ni ọrọ" Federal Character " lai fi ti ijafafa ati mimọ iṣẹ doju ami ṣe, ko ni itumọ kankan"

Lasiko to n fi iyatọ han laarin iṣẹ aladani ati iṣẹ ijọba, Sanusi sọ pe, o ṣe pataki lati ṣe agbekalẹ ilana ti yoo yọwọ oṣelu kuro patapata ninu iṣẹ ijọba.

O salaye, "O yẹ ki a ni" federal Character, sugbọn ki lo de ti a ni minisita, to mọṣẹ rẹ doju ami, to si n mu esi jade, sugbọn ti a tun ni minisita miran ti ko le gbe nkan tuntun ṣe?

Ki lo de to jẹ pe ẹya ni "Federal Character n gbajumọ, lai fi ti awọn to mọ iṣẹ naa ṣe si.

Sanusi wa dupe lọwọ ijọba lori bi wọn se yọwọ iranwọ kuro lori epo, o ni nkan to tọ lati ṣe ni, nitori pe, o ti pẹ to yẹ ki ijọba ti ṣe tori bi eto ọrọ aje ṣe ri.

Oríṣun àwòrán, @tundefashola

Ninu ọrọ tirẹ minisita fun iṣẹ ode ati ilegbe, ọgbẹni Babatunde Fashola ni ki awọn ọmọ Naijiria kọju si ijọba ipinlẹ ati ibilẹ, fun ọna abayọ si isoro wọn, kaka ti wọn yoo fi maa di gbogbo rẹ le ijọba apapọ lọrun.

Fashola ni kii ṣe ijọba apapọ lo ni ile ẹkọ alakọbẹrẹ tabi ile iwosan alabọde ijọba ibilẹ.

Ni Naijiria, ile ẹkọ girama to jẹ ti ijọba apapọ ko ju ọgọrun kan ati meje lọ.

"Mo fẹ rọ awọn eniyan lati lọ ka, iwe ofin Naijiria.

Àkọlé fídíò,

Obateru Akinruntan: Wíwá ohun tá jẹ títí láé ló gbé wa kúrò nílé Ife

O ni ida mẹẹdọgbọn ninu ida ọgọrun ni agbara ti ijoba apapọ ni, ile igbimọ asofin ati ẹka idajọ lo ni eyi to pọju lọ.

Bọ́ síta láti ṣe ìwọ́de mọ́ ìjọba Nàìjíríà lónìí, ko rugi oyin - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá

Ileeṣẹ ọlọpa ipinlẹ Eko ti fi ikilọ sita pe, ki ara ilu kankan maa ṣe kopa ninu iwọde loni tii ṣe ayajọ ominira Naijiria.

Ikilọ yii kun ikede ti ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria lapapọ ti fi sita ṣaaju pe, awọn yoo da ọlọpaa sita jakejado Naijiria lati dena iwa kankan ti yoo ṣakoba fun alafiaa ilu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lasiko ipade kan pẹlu awọn ọga ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, ni Kọmisana ọlọpaa Eko, Hakeem Odumosu fi ikilọ yi sita.

O ni awọn ko ni fi aye gba akojọ kankan tabi iwọde, to fi mọ ifẹhonu han eyi to le mu ipalara ba iṣọkan Naijiria.

Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Eko fun ara rẹ ati ti ipinlẹ Ogun ti ni, ko ni si afẹfẹ yẹyẹ kankan lasiko ajọdun ominira Naijiria.

Ni ti ipinlẹ Ogun, awọn tun sọ pe, ko ni si lilọ bibọ ọlọkada bẹrẹ lati alẹ ọgbọnjọ oṣu Kẹsan titi di owurọ ọjọ keji oṣu Kẹwa.

Bẹẹ ni wọn ni konileogbele yoo wa lalẹ ọjọ meji, iyẹn ọgbọnjọ oṣu Kẹsan ati ọjọ Kini oṣu Kẹwa

Ninu awọn to n palẹmọ lati ṣe iwọde lọjọ ayajọ ominira Naijiria ni Omoyele Sowore ati awọn ajafẹtọ ominira mii, labẹ akori RevolutionNow.

Bẹẹ naa ni awọn agbarijọpọ ẹgbẹ ọmọ Yoruba mii naa ni awọn fẹ ṣe iwọde lati beere fun Oduduwa Republic.

Awọn ikede wọn yii, yala lati ọdọ ileeṣẹ ọlọpaa ati awọn ijọba ipinlẹ, lawọn eeyan ti n ṣe eemọ si ṣugbọn ti awọn onwoye ni ko ba ofin mu.

Loju opo Twitter awọn eeyan ti n sọ tẹnu wọn nipa aṣẹ tawọn ijọba gbe kalẹ.