10,000 Police constables: Ilé ẹjọ́ wọ́gilé ètò ìgbanisíṣẹ́ tí ọgá ọlọ́pàá ṣé lọdun 2019

Osisẹ ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG

Ọrọ ti di maa kẹru rẹ pada sile fawọn ọlọpaa ẹgbẹrun mẹwa, ti ọga agba ọlọpaa Naijiria ṣeto igbanisiṣẹ fun lọdun 2019.

Eyi ko si sẹyin bi ile ẹjọ kotẹmilọrun ni Abuja ti ṣe wọgile eto igbaniṣiṣẹ ti wọn fi gba wọn wọle ni 2019.

Igbimọ adajọ ẹlẹni mẹta to gbe idajọ kalẹ lori ọrọ yii ni, ọga ọlọpaa Mohammed Adamu ko laṣẹ tati ṣeto igbanisiṣẹ.

Wọn ni ajọ to n ri si ọrọ akosọ ileeṣẹ ọlọpaa, Police Service Commission, lo laṣẹ lati ṣeto igbaniwọle siṣẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Police Recruitment: Ìlé ẹjọ ti pasẹ pe ki ilé iṣẹ́ ọ̀lọ́pàá dá ìgbaniwolé

Fanfa lori ọrọ yii ko ṣẹṣẹ bẹrẹ nitori loṣu Kẹsan ọdun 2019 ni ajọ to n sakoso ileesẹ ọlọpaa (PSC) ti gba ileẹjọ lọ, lati le fidi agbara wọn mulẹ, nipa gbigba eeyan ṣiṣẹ ọlọpaa.

Ababọ ẹjọ ti wọn pe ni pe, ile ẹjọ giga Abuja dajọ are fun ọga ọlọpaa, Adamu ṣugbọn PSC faake kọri, ti wọn si gba ile ẹjọ kotẹmilọrun.

Àkọlé fídíò,

Goitre Patients: Àwọn èèyàn tó ní àrùn gẹ̀gẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìkórira àti ìdẹ́yẹsí ní àwọn ń kojú

Adajọ Olabisi Ige, to jẹ adajọ to lewaju ninu idajọ naa ni iwe akoso isẹ ọlọpaa lo fun ajọ PSC ni agbara, lati le gba eeyan ṣiṣẹ ọlọpaa.

Ile ẹjọ ni ilana iṣakoso to ni pe ọga ọlọpaa lo ni aṣẹ lati gba eeyan ṣiṣẹ ko fẹsẹmulẹ, nitori naa igbaniṣiṣẹ yii ko bofin mu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: