Independence Day Nigeria: Atinuke Oladeru ni kẹ yé ṣépè fún Nàíjíríà mọ́, ẹ pa ohùn dà

Independence Day Nigeria: Atinuke Oladeru ni kẹ yé ṣépè fún Nàíjíríà mọ́, ẹ pa ohùn dà

Yoruba ni ẹyin lo n di akukọ, bi ọmọde oni ko ba ku, o daju pe agba ni yoo da.

Bẹk ni ọrọ ri pẹlu Atinuke Oladeru Christiana toun naa pe ọgọta ọdun lonii ti orilẹede Naijiria n sami ajọdun ọgọta ọdun to gba ominira.

Asiko ti pọpọ sinsin ominira Naijiria n lọ lọwọ ni ọjọ Kinni osu Kẹwaa ọdun 1960, ni wọn bi arabinrin Oladeru sile aye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n sọrọ lori awọn ohun to n fẹ atunse lorilẹede Naijiria, Oladeru wa ijọba nimọran lati mojuto eto aabo, ilera, eto ẹkọ, airisẹ se awọn ọdọ ati iwa isekupani laibikita.

Bakan naa lo gba awọn ọmọ Naijiria nimọran lati ye sepe fun orilẹede yii, amọ ki wsn pa ohun wọn da, ki wọn si maa se adura fun.

Oladeru ni epe la n sẹ fun Naijiria lati ọgọta ọdun to ti gba ominiria, to si n beere pe igba wo gan wa la fẹ maa gbadura fun?